Àṣìṣe ń lá ni Peter Obi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí oludije fún ẹgbẹ́ wa nínú ètò idibo Ààrẹ - Alukoro Labour Party nípinlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lẹ́yìn tí ile Ẹ̀jo Tribunal gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ lórí ẹjo tí Peter Obi ti Labour Party gbé síwájú rẹ láti fi tako ijawe olubori Ààrẹ Bọlá Tinubu, àwọn eekan ẹgbẹ oṣelu Labour Party, PDP ati APC nipinlẹ Ogun ti fesi.
Lẹyin ti Bola Tinubu la oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ati ti ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar mọlẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí àjọ eleto idibò apapo ilẹ̀ Naijiria, INEC kéde nínú ètò idibo sípò Ààrẹ lodun 2023, BBC news Yoruba kan sì àwọn ẹgbẹ́ oselu PDP, APC àti ẹgbẹ́ oselu Labour ni ìpínlè ogún láti mọ èrò ọkàn wọn lórí ìdájọ́ náà.

Nígbà tí ó sọ erongba rẹ, alukoro apapo fún ẹgbẹ́ oselu Labour, Comrade Abayomi Arabanbi ni ifasiko ṣòfò lásán ni Peter Obi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí adije fún ẹgbẹ́ oselu Labour nínú ètò idibo sípò Ààrẹ náà.
Arabanbi ni, ẹgbẹ́ oselu Labour yóò wà ẹni tí yóò kún ojú òṣùwọ̀n àti olopolo pípé láti díje sípò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ oselu Labour nínú ètò idibo lodun 2027.
Alukoro PDP ni Ogun

Nínú ọ̀rọ̀ tìrẹ, Alaga ẹgbẹ́ oselu PDP ni Ipinle Ogun, Sikirulahi Ogundele ni àwọn oludibo lo fà tí iná eto oselu orile-ede Naijiria fi ń jó iná ajoreyin.
Sikirulahi Ogundele ṣàpèjúwe ìdájọ́ ilé Ẹ̀jo tribunal náà gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ jìbìtì àti ayédèrú tí ẹgbẹ́ oselu PDP yóò ṣe atunyewo rẹ nílé Ẹ̀jo tí ó ga jù lọ nílé wá.
Alukoro APC ni Ogun

Nígbà tí ó ń fèsì sì ìdájọ́ ilé Ẹ̀jo tribunal náà, alukoro ẹgbẹ́ oselu Apc ni Ipinle Ogun, ambassador Tunde Oladunjoye ni, a fi kí àwọn ẹgbẹ́ oselu tooku fi ọwọ sowopo pẹ̀lú Ààrẹ Bọlá Tinubu láti mú orile-ede Naijiria dé ilẹ̀ ìlérí.
Oladunjoye ni, ìrètí wá pé Ààrẹ Bọlá Tinubu yóò mú adùn àti ògo orile-ede yii padà bo sípò.















