Wo kókó mọ́kànlá táwọn adájọ́ ló mú kí Tinubu borí ẹ̀sùn Obi àti Atiku

Oríṣun àwòrán, Facebook
- Author, By Chiagozie Nwonwu, Fauziyya Tukur, Olaronke Alo
- Role, BBC Global Disinformation Team
Gbogbo awọn adajọ maraarun to dari ẹjọ nibi igbẹjọ awuyewuye eto idibo aarẹ Naijiria lo pa ẹnu pọ dajọ pe aarẹ Bola Tinubu wọle ibo aarẹ to waye ninu oṣu keji ọdun yii.
Nibi idajọ naa to waye nile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Abuja ni awn eekan oloselu, awọn agba agbẹjọro ati awọn akọroyin peju si.
Wọnyii si ni awọn koko ti ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ eyi to mu ki ẹgbẹ oṣelu LP ati PDP atawọn ẹgbẹ mẹta mii to pe ẹjọ tako bi ajọ INEC ti kede Tinubu gẹgẹ oludije to jawe olubori ninu ibo aarẹ to kọja fidi rẹmi.
Koko mẹẹdogun to mu ki Obi ati Atiku lulẹ nile ẹjọ
- Ninu idajọ to waye ni Ọjọru ọsẹ yii ni ilu Abuja, igbimọ adajọ agba ẹlẹni marun to dari igbẹjọ naa sọ pe gbogbo ẹsun ti olupẹjọ iyẹn oludije ẹgbẹ oṣelu alatako Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi gbe wa kuna lati fihan pe magomago wa ninu eto idibo naa.
- Adari ikọ adajọ naa, Haruna Tsammani ṣapejuwe ẹsun Ọgbẹni Peter Obi gẹgẹ bi "ẹsun ti ko mulẹ" ati iIbeere alailesi lasan” lori ọrọ ida ibo marunlelogun (25% votes) ni ilu Abuja.Adajọ naa ni kii se dandan fun oludije aarẹ lati ni ida mẹẹdọgbọn esi ibo nilu Abuja.
- Bakan naa ni wọn dajọ pe Ọgbẹni Peter Obi kuna lati jẹ ki ile ẹjọ gba pe ajọ eleto idibo mọọmọ ma tete ko awọn esi idibo sori ẹrọ ayarabiaṣa fun awọn araalu lati ri nitori ki wọn le yi esi idibo pada lati gbe Ọgbẹni Tinubu.
- Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ikede esi idibo lori ẹrọ ayarabiaṣa(IREV) ko ni akọsilẹ ninu iwe ofin eto idibo.
- Ile ẹjọ tun fi kun un pe ajọ INEC lo gbe e wọle lati fi kun agbekalẹ amojuto wọn fun eto idibo.
- Ninu idajọ rẹ, adajọ Abba Muhammed ni iwe akọsilẹ esi ibo ati abọ igbimọ oluyẹwo ti olupẹjọ gbe kalẹ ko to lati tako esi ibo naa.
- Ile ẹjọ ni olupẹjọ to ni ayederu esi ibo ni ajọ INEC kede fun esi ibo aarẹ, kuna lati tọkasi awọn ẹkun idibo ati awọn agọ idibo ti magomago ibo ti waye nipinlẹ kọọkan.
- Ileẹjọ wọgile ẹri eeyan mẹwa ninu ẹlẹri mẹtala ti Peter Obi ẹgbẹ oṣelu LP pe.
- Bakan ni ileẹjọ kotẹmilọrun ni Peter Obi ko ni asẹ labẹ ofin lati pe ẹjọ lori iyansipo Bola Tinubu ati igbakeji rẹ nibi ibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC.
- Ileẹjọ wọgile awijare Tinubu pe Peter Obi kii se ọmọ ẹgbẹ oselu Labour lasiko idibo abẹnu fun ipo aarẹ.
- Ile ẹjọ ni eyi ko kan awọn olujẹjọ rara nitori ọrọ abẹnu ẹgbẹ oselu kan ni lati sọ awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ rẹ, ko si kan ẹgbẹ oselu miran.
- Ile ẹjọ ni Peter Obi kuna lati sọ iye ibo to ro pe oun gba ninu ibo aarẹ ko to di pe ajọ Inec yọ kuro ninu esi ibo naa gẹgẹ bo se sọ.
- Adajọ ni Obi ko tun fidi ẹri to daju mulẹ nipa agọ idibo, agbegbe kan tabi ibudo akojọpọ esi ibo ti ayederu ibo ti waye, amọ o duro lori ọrọ atẹnudẹnu.
- Ile ẹjọ ni ẹda abọ iwadii ibo EU ti olupẹjọ gba lọwọ osisẹ ile ẹjọ ni yara ikowepamọsi, kii se ojulowo akọsilẹ abọ iwadi EU gẹgẹ bi ajọ naa ti gbe kalẹ.
- Bakan naa ni ile ẹjọ ọhun tun taku lati gba iwe esi ibo 18,088 ti awọn olupẹjọ gbe kalẹ lori awijare pe ohun to wa ninu rẹ ko han daadaa.
Wo àwọn ìròyìn òfégè tó gbòde lórí ìdájọ́ Tribunal fún èsì ìbò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Yàtọ̀ sí àwọn ìròyìn òfégè tó gbòde lórí àwọn Adájọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú ló dúnkokò mọ́ àwọn ẹbí Adájọ́ náà lórí ayélujára.
Gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ sórí ayélujára yìí ni wọ́n ń fi #AllEyesOntheJudiciary parí rẹ̀.
Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni àwọn Adájọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
Ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́ta, Labour Party (LP), Peoples Democratic Party (PDP) àti Allied People Movement (APM) ló ń pe ìjáwé olúborí Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) lẹ́jọ́.
Ìdájọ́ náà yóò máa wáyé pẹ̀lú gbogbo àwọn ìròyìn òfégè tí àwọn kan ń gbé kiri lórí ayélujára nípa àwọn Adájọ́ tí yóò dá ẹjọ́ náà.
Ẹ̀ka tó ń rí sí ìròyìn òfégè ní BBC ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìròyìn òfégè yìí.
Adájọ́ kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀
Nínú oṣù Keje, iléeṣẹ́ ìròyìn kan, Igbo Times, gbé ìròyìn jáde pé ọ̀kan lára àwọn Adájọ́ márùn-ún tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ, Adájọ́ Boloukuoromo M. Ugo tí kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.
Iléeṣẹ́ ìròyìn náà ni Ugo gbé àtẹ̀jáde síta pé nítorí àwọn kan ń gbìyànjú láti dá ojú ìjọba àwaarawa bolẹ̀ ni òun ṣe fi ipò òun sílẹ̀.
Igbo Times ní Adájọ́ Ugo ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣèjọba lọ́wọ́ ní kí àwọn fi ẹjọ́ náà gbe ọmọ ẹgbẹ́ àwọn, tí òun sì kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí bí òun bá ṣe bẹ́ẹ̀ ó túmọ̀ sí pé ìjọba àwaarawa ní Nàìjíríà ti di òkú nìyẹn.
Ìwádìí BBC fi hàn pé Adájọ́ Ugo kò ì tíì fipò rẹ̀ sílẹ̀ àti pé kò sí ẹ̀rí kankan tó fìdí àwọn nǹkan tí Igbo Times kọ múlẹ̀.
Iléeṣẹ́ ìròyìn náà fi ìròyìn síta lórí àwọn ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ tí àwọn ènìyàn kan bíi Charles Oputa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Charly Boy sì pín ìròyìn náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn mìíràn ní ìròyìn ọ̀hún kìí ṣe òótọ́ síbẹ̀ Igbo Times, Charly Boy àtàwọn míì tó gbé ìròyìn náà kò paárẹ́ lórí ìtàkùn ayélujára wọn.
Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú Adájọ́ àgbà Nàìjíríà ní London
Nínú oṣù Kẹta, lẹ́yìn tí INEC Tinubu pé òun ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ààrẹ ni iléeṣẹ́ ìròyìn People Gazette gbé ìròyìn kan pé Adájọ́ àgbà Nàìjíríà múra bí ẹni tí kò dá pé láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu ní London.
Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ìpàdé wọn dá lórí àwọn awuyewuye tí yóò wáyé lẹ́yìn ìjáwé olúborí Tinubu.
Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ló gbé ìròyìn yìí tí wọ́n sì fi àwòrán kan si pé Adájọ́ àgbà, Ariwoola ló wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ tí wọ́n ń tì kọjá ní pápá kọ̀ òfurufú.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn Supreme Court ní lóòótọ́ ni Adájọ́ àgbà ṣe ìrìnàjò lọ sí London fún àyẹ̀wò ìlera rẹ̀ àmọ́ kò ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu.
Kò sí ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Tinubu àti Ariwoola pàdé ní London.
Kíkede ayédèrú ọjọ́ ìdájọ́

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó jẹ́ alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party bẹ̀rẹ̀ sí ní gbe kiri lórí ayélujára pé ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ààrẹ tí mú ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹsàn-án bí ọjọ́ tó máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀.
Ìròyìn ló gbòde kan kí ìgbìmọ̀ náà tó jáde lọ́jọ́ Kẹrin pé ọjọ́ Kẹfà ni ìdájọ́ máa wáyé.
Bákan náà ni wọ́n kéde pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa ọjọ́ Kẹrìndínlógún tí àwọn kan ń gbé kiri.
Fífòfin de ẹ̀ka ìdájọ́
Nínú oṣù Keje ni Igbo Times tún gbé ìròyìn kan jáde pé Ààrẹ Tinubu ti fòfin de gbogbo àwọn ilé ẹjọ́ ní orílẹ̀ èdè yìí nítorí ẹ̀rù pé òun máa fìdí rẹmi.
Igbo Times kò fí ẹ̀rí kankan láti fi gbe ìròyìn yìí lẹ́sẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe ìwádìí ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìròyìn òfégè ni.
Ìròyìn náà ṣì wà lórí ìtàkùn ayélujára wọn.
Àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ mìíràn
Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò kéde ọjọ́ tí yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ni àwọn kan tún ti ń po ìròyìn òfégè mìíràn pọ̀.
Ẹnìkan lórí ẹ̀rọ X rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ @MissPearls fẹ̀sùn kàn pé Ààrẹ Tinubu ti ń gbèrò láti sá kúrò ní Nàìjíríà pé wọ́n fẹ́ fi ètò kan bójú fún un.
Ẹ̀wẹ̀, láti inú oṣù Kẹrin ni iléeṣẹ́ Ààrẹ ti kéde pé Ààrẹ yóò ṣe ìrìnàjò lọ sí India láti lọ kópa níbi àpérò G20 èyí tí Olóòtú ìjọba India, Shri Narenda Modi pè é sí.
Ní ọjọ́ kẹsàn-án àti ìkẹwàá oṣù Kẹsàn-án ni àpérò náà yóò wáyé.
Olaronke Alo àti Fauziyyah Tukur náà kopa nínú kìkọ ìròyìn yìí













