PDP àti Labour jẹ gbèsè! Wo àpapọ̀ owó tílé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní kí wọn san lórí títako èsì ìbò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook
LP yoo san N47m, PDP N23m fún fifi àkókó ilé ẹjọ́ ṣòfò lóri ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀
Lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da ẹgbẹ oṣelu LP, PDP ati APM lẹbi tan lori ẹjọ ti wọn pe wi pe Bola Tinubu ko wọle ibo aarẹ, ile ẹjọ tun sọ fun wọn pe ki wọn lọ san obitti-biti miliọnu tori awọn ẹjọ ti wọn pe ko lẹsẹ nlẹ.
Ile ẹjọ ni wọn gbọdọ san owo yii nitori wọn fi akoko ile ẹjọ ṣofo lori ẹsun ti ko fẹsẹ mulẹ ti wọn gbe wa sile ẹjọ.
Ile ẹjọ ni ki ẹgbẹ oṣelu LP tii ṣe ẹgbẹ Peter Obi san owo to le ni miliọnu mẹtadinlaadọta(N47, 910, 431.87).
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni owo ti ile ẹjọ ni ki wọn san tun ṣikeji lẹyin ti wọn ni ki wọn lọ san owo to le miliọnu mẹtalelogun(N23, 391,001.45).
Owo to le ni miliọnu mẹtala naira ni ile ẹjọ ni ki ẹgbẹ oṣelu APM lọ san.
Awọn sọ fawọn ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta pe wọn gbọdọ san owo yii laarin ọjọ meji lẹyin idajọ si akaunti ileẹjọ kotẹmilọrun ni ile ifowọpamọ apapọ Naijiria, CBN.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni igbẹse yii wa ni ibamu pẹlu ẹka 87 labẹ ẹka 390 ti ọdun 1968 ninu iwe ofin Naijiria.
Obi wa lati fi owo ẹgbẹ to to miliọnu mẹẹdogun owo dọla ati biliọnu mejila naira(N12b) ṣofo lasan ni - Apapa
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu LP labẹ olori Alhaji Lamidi Apapa ti sọ pe awọn kilọ fun Obi lori ẹjọ to pe wi pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nlẹ.
Alukoro ẹgbẹ LP, Ọmọwe Abayomi Arabambi sọ ninu atẹjade to fi sita lẹyin idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun pe ojuti nla ni pe awọn agbẹjoro Obi ko fun ni imọran gidi ki o to mori le ile ẹjọ kotẹmilọrun.
O ṣalaye ninu atẹjade naa pe ijakulẹ Obi nile ẹjọ ti kin ohun tawọn sọ tẹlẹ lẹyin pe Obi wa lati fi owo ẹgbẹ to to miliọnu mẹẹdogun owo dọla ati biliọnu mejila naira(N12b) ṣofo lasan ni.
Ọmọwe Arabambi ni fifi akoko ṣofo lasan ni ẹjọ ti Obi pe.
O tun ṣalaye pe ọkan lara ẹsun ti awọn agbẹjọro Obi gbe lọ sile ẹjọ pe Tinubu ko ni iko mẹẹdọgbọn ibo niluu Abuja jẹ iyanlẹnu tori Abuja dabi ọkan lara awọn ipinlẹ ni Naijiria ni.
Ẹgbẹ oṣelu LP labẹ olori Apapa wa sọ pe awọn faramọ idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun gẹgẹ bi ọmọ Naijiria to bọwọ fun ofin.
Wọn ni iyan ti di atun gun bayii, bẹẹ ni ọbe ti di atunse lẹgbẹ oṣelu LP.















