Ilé ẹjọ́ fi òǹtẹ̀ lù àṣeyọrí Bola Tinubu ní ìdìbò ààrẹ

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency

Gbogbo awọn adajọ maraarun to dari ẹjọ nibi igbẹjọ awuyewuye eto idibo aarẹ ti pa ẹnu pọ dajọ pe aarẹ Bola Tinubu gangan ni ojulowo ajaweolubori nibi eto idibo aarẹ to waye ninu oṣu keji ọdun yii.

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto idibo ni Naijiria tun kede wipe ilana to tọ ni wọn fi yan aarẹ Bola Ahmed Tinubu ninu idibo aarẹ to waye ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun 2023.

Ninu idajọ to waye ni Ọjọru ọsẹ ni ilu Abuja, igbimọ adajọ agba ẹlẹni marun to dari igbẹjọ naa sọ pe gbogbo ẹsun ti olupẹjọ iyẹn oludije ẹgbẹ oṣelu alatako Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi gbe wa kuna lati fihan pe magomago wa ninu eto idibo naa.

Awọn adajọ ile ẹjọ naa fidi rẹ mulẹ pe olupẹjọ ko lee fẹsẹ awọn ẹsun rẹ mulẹ lori ẹsun pe ibo pọ ju iye awọn to forukọ silẹ lọ. Bakan naa ni wọn dajọ pe Ọgbẹni Peter Obi kuna lati jẹ ki ile ẹjọ gba pe ajọ eleto idibo mọọmọ ma tete ko awọn esi idibo sori ẹrọ ayarabiaṣa fun awọn araalu lati ri nitori ki wọn le yi esi idibo pada lati gbe Ọgbẹni Tinubu.

Awọn adajọ jẹ ko di mimọ pe gẹgẹ bi akọsilẹ awọn abala kan ninu iwe ofin Naijiria, niwọn igba ti olupẹjọ ko ti le fi aridaju bi o ṣe ni ajọ naa ko tẹle ofin ati bo ṣe ṣakoba fun esi idibo han ile ẹjọ. “Bi awọn naa ko ba le fi aridaju kan naa han, ipẹjọ yii kuna,” ile ẹjọ kede.

Ilé ẹjọ ti wọ́gílé gbogbo ẹ̀sùn Peter Obi tako ààrẹ́ Tinubu!

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto idibo ti da ẹjọ lori ẹsun ti oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi pe lori abajade esi idibo aarẹ Naijiria.

Ẹsun Peter Obi pin si ọna mẹrin ṣugbọn ṣe ni igbimọ adajọ ẹlẹni marun to wa nikalẹ tu awọn ẹsun rẹ mẹrẹẹrin ka tako oludije Labour Party naa.

Adari ikọ adajọ naa, Haruna Tsammani ṣapejuwe awọn ẹsun Ọgbẹni Peter Obi gẹgẹ bi "ẹsun ti ko mulẹ" ati “Ibere alailesi lasan”.

Lori ọrọ ida ibo marunlelogun (25% votes) ni ilu Abuja

Tinubu ati Obi

Oríṣun àwòrán, APC/LP

Bakan naa, ile ẹjọ ti yanju ọrọ ida marunlelogun ti ariwo gun ori rẹ pe o yẹ ki ẹni to ba jawe olubori ni ni olu ilu orilẹede yii tii ṣe Abuja.

Wọn ni ọrọ “ati” (and) ti awọn eeyan n tẹnu mọ pe o wa ninu iwe ofin eto idibo kan jẹ atamọ atamọ lasan.

Ile ẹjọ wa fi kun un pe ki wọn ma kan maa wo ofin lai wo o tan toripe ofin wa nibẹ lati tọ koda iran to n bọ wa sọna ni.

“Gbogbo ofin lo ni ayé ati ẹ̀mí to n ṣiṣẹ. Aye ati ẹmi ofin orilẹede Naijiria wa ninu ifaara rẹ.”

Ori keji iwe ofin ọdun 1999 doju kọ ibadọgba ẹtọ oludibo ati pataki ibo wọn.

Ko sohun mii to ṣafihan bikoṣe erongba fun bo ba jẹ bẹẹ, ko maa jẹ bẹẹ lọ.

Apa ibi to sọpe “ati olu ilu orilẹede yii (FCT) ko ni itumọ ti awọn olupẹjọ n fun un rara,” Adajọ Haruna Tsamani sọ bẹẹ.

Kikede esi idibo lori ẹrọ kọmputa

Awọn adajọ agba naa ni ikede esi idibo lori ẹrọ ayarabiaṣa ko ni akọsilẹ ninu iwe ofin eto idibo.

Lori ọrọ gbigbe esi idibo jade lori ẹrọ ayarabiaṣa, ile ẹjọ ni ko si ninu ofin eto idibo ọdun 2022 taara.

Ile ẹjọ tun fi kun un pe ajọ INEC lo gbe e wọle lati fi kun agbekalẹ amojuto wọn fun eto idibo.

Peter Obi kùnà níléẹjọ́ kò ríbi yẹ àga ààrẹ mọ́ Tinubu nídìí!

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja, ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti oludije ẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi pe tako esi ibo aarẹ eyi to gbe Aarẹ Bola Tinubu wọle.

Ninu idajọ rẹ, adajọ Abba Muhammed ni iwe akọsilẹ esi ibo ati abọ igbimọ oluyẹwo ti olupẹjọ gbe kalẹ ko to lati tako esi ibo naa.

Bakan naa lo ni olupẹjọ naa, to ni ayederu esi ibo ni ajọ INEC kede fun esi ibo aarẹ, kuna lati tọkasi awọn ẹkun idibo ati awọn agọ idibo ti magomago ibo ti waye nipinlẹ Kọọkan.

“A ko tiẹ lero rara pe olupẹjọ kan yoo fi ẹsun kan pe magomago nla waye lawọn agọ idibo to to 176,000, wọọdu 8000 , ijọba ibilẹ 774 ati ipinlẹ mẹrindinlogoji lai tọkasi awọn ibi ti magomago yii ti waye gan”

Ileẹj naa wa wọgile ẹri eeyan mẹwa ninu ẹlẹri mẹtala ti Peter Obi pe lori awọn ẹsun yii.

Bakan naa ni ileẹjọ kotẹmilọrun naa ni Peter Obi ko ni asẹ labẹ ofin lati pe ẹjọ lori iyansipo Bola Tinubu ati igbakeji rẹ nibi ibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC.

O ni ohun to ba n sẹlẹ ninu ẹgbẹ oselu kan ko kan ekeji rara, ayọnusọ ni.

Adajọ Muhammed ni gbogbo awọn oludije to ba ja kulẹ ninu ibo ni ẹtọ lati pe ẹni to jawe olubori nikan lẹjọ, kii se ajọ to gbe esi ibo naa silẹ.

Ileẹjọ wọgile awijare Tinubu pe Peter Obi kii se ọmọ ẹgbẹ oselu Labour lasiko idibo abẹnu fun ipo aarẹ

O si to ẹsẹ mẹtadinlogun ninu iwe ẹsun Peter Obi ati ẹgbẹ oselu Labour tileẹjọ Kotẹmilọrun naa wọgile.

Ileẹjọ ni awọn ẹsun to wa ninu awọn iwe ẹsun ti wọn wọgile naa lo jẹ ofege ati agbelẹrọ lasan.

O fikun pe awọn ẹsun naa to da lori sise magomago ati segesege to waye lasiko eto idibo naa ni olupẹjọ ko fi idi ẹri to daju mulẹ lati gbe ẹsun wọn lẹsẹ.

Amọ ileẹjọ wa wọgile awijare ikọ olujẹjọ eyi to ni Peter Obi kii se ọmọ ẹgbẹ oselu Labour lasiko eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu Labour amọ to pada wa di oludije aarẹ fẹgbẹ oselu naa.

Ile ẹjọ ni eyi ko kan awọn olujẹjọ rara nitori ọrọ abẹnu ẹgbẹ oselu kan ni lati sọ awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ rẹ, ko si kan ẹgbẹ oselu miran.

"Peter Obi kuna lati sọ iye ibo to ro pe oun gba ninu ibo aarẹ ko to di pe ajọ Inec yọ kuro ninu esi ibo naa gẹgẹ bo se sọ"

Nigba to n wọgile awijare Peter Obi ati ẹgbẹ oselu Labour pe oun lo bori ibo aarẹ, adajọ naa ni wọn ko se atupalẹ awọn akọsilẹ esi aarẹ naa lẹsẹẹsẹ eyi ti yoo fihan pe o bori ibo ọhun.

O ni Obi ko tun fidi ẹri to daju mulẹ nipa agọ idibo, agbegbe kan tabi ibudo akojọpọ esi ibo ti ayederu ibo ti wajẹ amọ to duro lori ọrọ atẹnudẹnu.

Adajọ Muhammed, lasiko to n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun ti Obi gbe kalẹ pe ajọ Inec yọ lara ibo oun, to si ro pọ mọ ti oludije fẹgbẹ oselu APC.

O ni Peter Obi kuna lati sọ iye ibo to ro pe oun gba ninu ibo aarẹ naa ko to di pe ajọ Inec yọ kuro ninu rẹ gẹgẹ bo se sọ.

Bakan naa lo ni olupẹjọ naa ko tun tu asiri awọn ipinlẹ tabi agọ idibo to ti gba awọn esi ibo naa eyi to ni wn yọ kuro ninu rẹ.

Bola Ahmed Tinubu na iwe ẹri moyege ibo soke

Oríṣun àwòrán, @officialbolatinubu

"Peter Obi ko gbe akọsilẹ awọn ẹlẹri to fi agbara ofin pe wa jẹri kalẹ lasiko"

Peter Obi ko gbe akọsilẹ awọn ẹlẹri to fi agbara ofin pe wa jẹri kalẹ laarin ọjọ mọkanlelogun ti ofin ajọ eleto idibo ilẹ wa tọdun 2022 gbe kalẹ.

Adajọ naa wa kọ lati tẹwọgba awọn iwe to fi mọ abọ iwadi awọn onimọ eyi ti ikọ olujẹjọ naa gbe kalẹ lati ipasẹ awọn ẹlẹri mẹwẹẹwa naa.

Ileẹjọ ni ọpọ awọn ẹlẹri ti Obi fi ofin gbe wa sile ẹjọ naa kii se awọn eeyan to nifẹ nipa abọ igbẹjọ naa.

O fikun pe awọn ẹri ti wọn gbe kalẹ ni wn se lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ.

"Kii se dandan fun oludije aarẹ lati ni ida mẹẹdọgbọn esi ibo nilu Abuja"

Bakan naa ni adajọ sọrọ lori awijare Peter Obi pe ko yẹ ki ajọ Inec kede Bola Tinubu bii ẹni to jawe olubori ninu ibo aarẹ naa nitori pe ko ni ibo ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun ti wọn di lasiko ibo aarẹ ni olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Adajọ naa ni kii se dandan fun oludije aarẹ lati ni ida mẹẹdọgbọn esi ibo nilu Abuja, ki wọn to kede rẹ pe o jawe olubori.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun kọ abọ iwadi esi ibo ti ajọ European Union (EU) gbe kalẹ

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kede pe oun ti yọ awọn iwe abọ itọpinpin esi ibo tawọn asoju ajọ European Union, EU gbe kalẹ lori ibo aarẹ to kọja eyi ti Peter Obi gbe wa sile ẹjọ.

Ile ẹjọ ni ẹda abọ iwadii ibo EU naa ti olupẹjọ ọhun gba lọwọ osisẹ ile ẹjọ ni yara ikowepamọsi, kii se ojulowo akọsilẹ abọ iwadi EU gẹgẹ bi ajọ naa ti gbe kalẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ ọhun tun taku lati gba iwe esi ibo 18,088 ti awn olupẹjọ gbe kalẹ lori awijare pe ohun to wa ninu rẹ ko han daadaa.

O fikun pe awọn iwe akọsilẹ esi ibo naa ko ni nnkan se pẹlu agọ idibo kankan to ni nnkan se pẹlu esi idibo ti wọn n gbe yẹwo, eyi ti olupẹjọ tun kuna lati tọkasi ninu iwe ẹsun rẹ.

Adajọ ni olupẹjọ gan ko le tọka si agọ idibo to ni iwe esi ibo naa nitori awọn esi ibo to wa ninu rẹ ni ko han lati ri.

“Ẹsun pe Tinubu huwa ọdaran ni Amẹrika ko lẹsẹ nilẹ”

Ile ẹjọ kotẹmilọrun tun ti salaye pe ofuutu fẹẹt, aasa ti ko ni kaun ni awọn ẹsun ti ẹgb oselu Labour fi kan Bola Ahmed Tinubu pe o huwa ọdan lorilẹede Amẹrika.

Adajọ ni ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ rara, ti oun si wọgile.

O ni Tinubu ko huwa ọdaran kankan ni Amrika, ti wọn ko si ran lọ sẹwọn tori rẹ tabi pe ko san owo itanran.

“Ile ẹjọ yii wa fara mọ, to si kede pe Bola Tinubu lẹtọ lati kopa tabi dije ninu ibo aarẹ tọdun 2023.”

Ileẹjọ naa ni ikọ olupẹjọ kuna lati fidi rẹ mulẹ pe ileẹjọ Amẹrika dajọ iwa ọdaran fun Tinubu nibamu pẹlu ilana ofin.

O ni ẹjọ araalu lasan ni wọn ni pẹlu Tinubu, kii se iwa ọdaran rara, eyi to si le ma mu ki ẹni to ba jẹbi kuna lati gbegba ibo laarin ọdun mẹwa to sẹ ẹsẹ tile ẹjọ dajọ rẹ naa.

Àkọlé fídíò, Cost of Living: Ọ̀pọ̀ ọlọ́kọ̀ ń ta ọkọ̀ tó ní Pílọ́gìì mẹ́fà láti ra onípílọ́gìí mẹ́rin

APM lulẹ̀ lórí ẹ̀sùn tó pè tako èsì ìbò ààrẹ Tinubu, ilé ẹjọ́ ní aláyọnusọ ni

Tinubu ati ChiChi Ojei

Adajọ Haruna Tsammani, to ko igbimọ ẹadajọ ẹlẹni marun sodi lati ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja, ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti oludije ẹgbẹ oselu APM, Chichi Ojei pe tako esi ibo aarẹ eyi to gbe Aarẹ Bola Tinubu wọle.

Ninu idajọ rẹ, adajọ naa ni olupẹjọ ko pe ẹlẹri kankan wa sile ẹjọ lati gbe awọn ẹsun rẹ lẹyin.

Olupẹjọ yii lo n tako idibo yan Tinubu gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, kede pe Tinubu ko yẹ lẹni to yẹ ko bonu ibo abẹnu APC lati di oludije.

Amọ Adajọ ni ayọnisọ lasan ni olupẹjọ naa se lori ẹjọ to pe yii nitori ofin ko fi aaye gbe ọmọ ẹgbẹ oselu miran lati wa tako ibo abẹnu ẹgbẹ oselu ti kii se tirẹ.

"Ọmọ ẹgbẹ oselu APC nikan, to si tun kopa ninu ipo abẹnu ẹgbẹ pẹlu Bola Tinubu, nikan lo lẹtọ lati pe ẹjọ tako ibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa kii se ara ita"

O fikun pe ọmọ ẹgbẹ oselu APC nikan, to si tun kopa ninu ipo abẹnu ẹgbẹ pẹlu Bola Tinubu nikan lo lẹtọ lati pe ẹjọ tako ibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa.

Adajọ naa ni gbogbo awọn koko ẹsun ti olupẹjọ naa gbe kalẹ lati tako ibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC to fa Tinubu kalẹ bii ọmọ oye ni ko lẹsẹ nilẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹsun pe Kazzem Shettima ko yẹ lati gba ipo igbakeji Tinubu, Adajọ Tsammani wọgile ẹsun yii pe Tinubu ko lu ofin pẹlu igbakeji rẹ to yan naa.

Adajọ naa, ẹni to wo awọn akoko ti Shettima kọ ipo oludije Sẹnetọ silẹ lati gba ipo oludije sipo igbakeji aarẹ, salaye pe ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti gbe idajọ kalẹ saaju lori ẹjọ naa ti ẹgbẹ oselu PDP pe.

O ni ẹjọ naa si lo gbe fun Shettimma ti ile ẹjọ to ga julọ si ni Shettima yẹ lati gba ipo igbakeji aarẹ naa.

Ki ni awọn koko ẹsun ti Chichi Ojei pe tako Bola Tinubu?

Chichi Ojei, tii se oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu APM yii lo ni ibo 25,961 ninu ibo aarẹ to waye lọjọ Kẹẹdọgbọn osu Keji ọdun 2023.

Lara awọn ẹsun ti Ojei pe tako Tinubu ni pe ẹgbẹ oselu APC fa Tinubu kalẹ lọna aitọ niwọn igba to ti yan Kazzem Shettima bii igbakeji rẹ

APM ni Shettima gba lati se igbakeji Tinubu lasiko to si jẹ oludije fun ipo Sẹnetọ lẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Borno.

Àkọlé fídíò, Blind woman raises two blind children: Ọkọ mi kọ̀ mí lẹ́yìn tí ọmọ kẹta náà kò ríran
Ta ni yóò rẹ́rìn-ín láàrin Tinubu, Atiku àti Obi bí iléẹjọ́ ṣe ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ìbò ààrẹ?
Tinubu, Atiku ati Obi

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ, oni ni ile ẹjọ kọtẹmilọrun to n gbẹjọ awuyewuye to suyọ ninu ibo aarẹ orilẹede Naijria eleyii ti Bola Tinubu ti jawe olubori yoo da ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu LP, PDP, APM, APP ati AA pe ajọ eleto idibo INEC pe Tinubu to jẹ oludije APC ko wọlẹ ibo naa ni Ọjọru.

Ibẹru bojo ti gbalẹ kan kaakiri tori ko si ẹni to mọ ti idajọ naa yoo fori sọ.

Ẹwẹ, awọn eeyan yoo lanfaani lati wo eto igbẹjọ ọhun lori ẹrọ amohunmaworan ki gbogbo ọmọ Naijiria tẹ le igbẹjọ naa ni ṣisẹ n tẹle.

Ọjọ kinni oṣu Kẹta ọdun 2023 yii ni ajọ INEC kede pe Tinubu lo jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Naijiria.

Ajọ INEC ni ibo 8,794,726 ni Tinubu ri nigba ti Atiku ẹgbẹ PDP to ṣe ipo keji ri ibo 6,984,520, bakan naa ni Obi ti LP lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 6,101,533.

Amọ, awọn ẹgbẹ oṣelu marun un tawọn naa dije ninu ibo aarẹ sọ pe Tinubu to jẹ oludije APC kọ lo wọle ibo naa.

Ẹjọ ti Peter Obi pe

Oludije fẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi pe ẹjọ wi pe ọpọlọpọ kudiẹkudiẹ lo waye lasiko ibo naa, ati pe igbakeji Tinubu, iyẹn Kashim Shettima ko tọ lati du ipo igbakeji Aarẹ nitori oun kan naa lo n du ipo Sẹnetọ.

O tun sọ pe Tinubu kuna lati bori ida to pọ ju ninu ibo naa, ati pe ko bori ida kan ninu ida mẹrin gbogbo igbo ti wọn di ni ilu Abuja.

Pupọ ninu awọn ‘Obidients’ ti wọn jẹ ololufẹ ati alatilẹyin Peter Obi lo gbagbọ pe iroyin ayọ ni idajọ igbimọ naa yoo jẹ fun awọn.

Ṣugbọn Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe oun ko mikan lori idajọ naa rara nitori ayọ ni yoo jẹ fun oun.

Ẹwẹ, igbimọ oludajọ naa ti sọ pe kedere ni gbogbo aye yoo wo idajọ naa lori ẹrọ amohunmaworan ati lori ayelujara lọla Ọjọbọ.

Ẹjọ ti Atiku pe

Atiku ni tiẹ ni ki ile ẹjọ wọgile esi ibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ, ki INEC si ṣeto idibo tuntun miran.

Atiku tun sọ pe ki ajọ INEC gba iwe ẹri moyege ọwọ Tinubu nitori o lodi si ofin eto idibo Naijiria bi wọn ṣe fun Tinubu ni iwe ẹri ọhun.

Nigba tii yoo fesi pada, agbẹjọro Tinubu, Oloye Wole Olanipekun, SAN, sọ fun ile ẹjọ naa pe ẹjọ Atiku ko lẹsẹ nilẹ, nitori gbogbo igba lo maa n lulẹ ninu ibo Aarẹ Naijiria.

Amọ ṣa, lẹyin ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni igbimọ to n gbọ ẹjọ ọhun wọgile ẹjọ ti ẹgbẹ AA ati APP pe, lẹyin ti wọn ni awọn ko ṣe ẹjọ mọ.

Ohun kan to daju ni pe anfaani si tun wa fawọn olupẹjọ lati lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti idajọ oni ko ba tẹ wọn lọrun.

Ẹwẹ, Ileeṣẹ aarẹ ti sọ pe Tinubu o mikan rara lori idajọ ti yoo waye niluu Abuja.

Oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale lo sọrọ yii lori ẹrọ amohunmaworan Channels Tv lọjọ Aje.

Ngelale ni Tinubu o foya nitori o wọle ibo aarẹ eleyii ti Atiku ati Obi pe e lẹjọ si pe ko wọle.