“Mo ní ìpèníjà ojú àmọ́ àlàyé rèé lórí bí mo ṣe tọ́ ọmọ mi méjì táwọn náà kò ríran”
Yoruba ni ko si ohun ti ko sẹlẹ ri, ko si si ohun ti oju ko ri ri nitori bi eeyan ba rin, rin, rin, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Ko wọpọ lati ri ki iyan ni ipenija oju amọ ki awọn ọmọ toi bi tun ma riran.
Sugbọn BBC Yoruba rin, rin, rin, a se alabapade obinrin kan, Alabi Opeyemi, to ni ipenija oju, ti awọn ọmọkunrin mejeeji to tun bi naa ko riran rara.
Ibeere ti yoo si maa gba ọkan ọpọ eeyan ni pe bawo ni obinrin ti ko riran se tọ ọmọ meji tawọn naa ni ipenija oju, Kayeefi gbaa ni.

"Alaye ree lori bi mo se wo ọmọ meji ti ko riran dagba lẹyin ti ọkọ mi fi mi silẹ"
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Opeyemi salaye ọna to gba tọ awọn ọmọ rẹ dagba gẹgẹ bi ẹni ti ko riran lati inu iya rẹ amọ to bi ọmọ mẹta gbankọ-gbankọ.
Opeyemi salaye pe mama oun lo ni kata lasiko to loyun oun, to si lọ sile iwosan fun iwosan lai mọ pe arun ẹyi eyiun Measels lo ni eyi ti ko jade sita.
Igba ti mama oun si bi oun saye ni oun ko le fi oju oun riran daadaa rara.
O ni oun n riran diẹdiẹ amọ ko dabi, ti oun si lọ sile ẹkọ olukọni.
O ni oun ni ọkọ, ti oun si lọ si fasiti lati kẹkọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ lẹyin ọmọ meji.
Opeyemi ni awọn ọmọ mejeeji akọkọ yii ni ko mu ẹyinju waye rara, ti wọn ko si riran.
O ni fasiti ni oun wa, ti oun fi bimọ kẹta amọ ti ọmọ naa tun se afihan pe oun ko riran.
“Ni kete ti ọkọ mi mọ pe ọmọ kẹta yii tun ti fẹ fọ loju, lo wa gbe, to si palẹ ẹru rẹ mọ, to si salọ.”

"Alaanu kan lo kọ ile ti mo n gbe fun mi amọ mo nilo kanga ati ẹrọ amunawa Solar"
Opeyemi ni oun n gbiyanju lati ri ọwọ mu l sẹnu bi o tilẹ jẹ pe ko rọrun rara, ti oun si pa eto ẹkọ fasiti ti nigba ti ọkọ oun ti kọ oun.
Obinrin to ni ipenija oju naa, tii se olukọ nile ẹkọ awọn akanda ẹda nilu Ilorin ni ẹlẹyinju aanu kan lo kọ ile ti oun n gbe fun oun amọ oun si nilo ẹni ti yoo gbẹ kanga fun oun.
Bakan naa lo n fẹ iranlọwọ lori ipese ẹrọ amunawa to n lo itansan oorun, eyiun Solar ati owo lati fi kun ọja to n pese lati ta, eyiun ọsẹ ifabọ ati lọfinda oloorun didun.
Opeyemi, ẹni to n dupẹ ipo to wa tun wa n gba awọn obi to ni awọn ọmọ to ni ipenija oju lati mase pa wn ti tabi maa fi wọn se agbe kiri igboro.







