Ọ̀rọ̀ di hùn, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fi ẹgba lé àwọn òṣìṣẹ́ jáde l'ọ́fíìsì l'Ondo

Aworan awọn oṣiṣẹ l'Ondo

Agbarijọ awọn oṣiṣẹ labẹ ajọ NLC lọ fi ẹgba le awọn oṣiṣẹ ijọba kuro lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Ondo lonii ọjọ Iṣẹgun.

Awọn oṣiṣẹ ọun ti wọn kọ lati tẹle aṣẹ ajọ NLC pe ki oṣiṣẹ joko sile loni ojọ Iṣẹgun ati ọla Ọjọru ni wọn wa lẹnu iṣẹ lakoko ti ajọ NLC de awọn ileeṣẹ ijọba ọhun.

Lara awọn ọfiisi ti wọn de ni ile iṣẹ to n mojuto eto iroyin, ijọba ibilẹ ati ọrọ oye, eto inawo ati ileeṣẹ to n moju to eto ilera.

Bo tilẹ jẹ pe pupọ lara awọn oṣiṣẹ naa ni wọn yara lati jade ti wọn si ti ilẹkun ọfiisi wọn, awọn diẹ lara wọn gbena woju awọn adari ajọ NLC to jade lati moju to iyanṣẹlodi naa.

Alaga NLC nipinlẹ Ondo, Victor Amoko, to dari igbimọ to n moju to imuṣẹ iyanṣẹlodi naa wipe ẹtọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ni awọn n ja fun, ti ko si yẹ ki oṣiṣẹ kankan o tako igbesẹ yii.

Amoko to koro oju si bi awọn oṣiṣẹ kan ko ṣe tẹle aṣẹ NLC lori ifidimọle naa wi pe “ẹtọ awa adari ajọ NLC kọ la n ja fun, ẹtọ gbogbo wa ni.

To ba jẹ pe ẹtọ temi nikan ni, o rọrun fun mi lati gba owo lọwọ ijọba ki n si dakẹ. Amọ, ti mo ba gba owo, bawo ni ọjọ ọla awọn ọmọ mi yoo ṣe ri?

Idi ni yii ti gbogbo wa fi gbọdọ jẹ ki ijọba mọ ibi ti bata ti n tawa lẹsẹ, ki wọn si bu ororo itura sii ni kiakia ki aye o le rọrun fun t'olori t'ẹlẹmu.”

Ẹwẹ, gbogbo awọn ile ifowopamọ ni ilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ti akọroyin BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ni wọn wa ni ṣiṣi ti awọn onibara si n wọle jade.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ile ifowopamọ ko tete ṣi ilẹkun laarọ, awọn onibara wi pe wọn duro lẹnu ọna pẹlu ireti pe awọn banki naa yoo ṣiṣẹ leyi to si pada wa si imuṣẹ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ iná mọ́nàmọ́ná bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní Kwara, wọ́n ní kí ìjọba ṣe ohun tó tọ́

Aworan awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Kwara
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ meji ti bẹrẹ ni ipinlẹ Kwara lonii ọjọ kaarun un, osu kẹsan an ọdun 2023.

Awọn ileeṣẹ aladani ati ti ijọba ni o wa ni titi pa, awọn oṣiṣẹ ko si ni anfaani lati wo ibi isẹ wọn.

Ni olu Ile iṣẹ ajọ to n ri si ina mọnamọna ni ipinlẹ ọhun ni a ti ri egbe National Union of Electric Employee (NUEE) ti wọn si n ṣe ifẹhonuhan wọn.

Alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Kwara, Kọmureedi Ologun Felix Oluwatosin ṣalaye wi pe, ẹgbẹ NUEE jẹ ẹka ajọ NLC awọn si gba idari lati NLC pe ki awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi latari pe ijọba ko mu ileri rẹ ṣẹ.

O tẹsiwaju pe, "ebi n pa awon eniyan, awon eniyan ko ri owo na, wọn ko si tun le gbe ọkọ lọ si ibi iṣẹ latari yiyọ owo iranwọ ori epo, nitori eyi no a ṣe n fi ẹhonu wa han si ijọba ki wọn ṣe ohun to yẹ lati le jẹki ara dẹ awọn oṣiṣẹ ati ara ilu.

"Ọlọjọ meji pere ni eleyii, ikilọ si lo jẹ fun ijọba, ti ijọba ko ba ṣe ohun ti o yẹ ki wọn ṣe, a a tun n pada bọ."

Ẹwẹ, akọwe ẹka naa, Kọmureedi Ayodele Peters sọ wi pe, imunilẹru ni o jẹ fun awọn, nitori awọn n sisẹ bi erin ti awọn si n jẹ ijẹ ẹliri.

O rọ awọn akẹgbẹ rẹ pe ki wọn jade sita ki wọn si sọrọ soke nitori ẹni to ba dakẹ, ti ara rẹ yoo baa dakẹ.

O leri wi pe ko si ẹnikan to le yọ awọn niṣẹ nitori pe wọn ja fun ẹtọ wọn bẹẹ si ni ẹnikẹni ko lee dunkoko mọ awọn.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì l'Oyo

Aworan awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo

Awọn oṣiṣẹ ile iṣe ijọba apapọ ati awọn ile ifowopamọ nipinlẹ Oyo ti gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ meji.

Ṣaaju ni apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ orilẹ-ede yii, NLC kede wiwo iṣẹ niran fun ọjọ meji lati fa ijọba apapọ leti.

Akọroyin ile iṣe BBC Yoruba ṣe abẹwo si awọn ile ifowopamọ kọọkan to wa ni ilu Ibadan papaa julọ ni agbegbe ọjoo, Agbowo, Bodija, Mokola, Sango ti a ṣi fidi rẹ mulẹ wi pe gbogbo wọn lọ wa ni titi pa.

Awọn oṣiṣẹ ile iṣe ti ijọba apapọ to wa nipinlẹ Oyo naa ko ṣai gun le iyanselodi, bii awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ati NLC ti ile iṣe naa ti ilẹkun ile iṣe ọhun paa.

Andrew Emelieze ẹni ti o siwaju awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to ba ileeṣẹ BBC sọrọ, ṣalaye wi pe, iyanṣẹlodi ti awọn gun le ko ṣẹyin aṣẹ lati ọdọ awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ latari bii awọn oṣiṣẹ jakejado orilẹ-ede yii tí ń jẹ iya.

Andrew rọ Aarẹ Bola Tinubu lati ṣaanu awọn oṣiṣẹ ki awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to gun le iyanselodi ti yoo lọ jakejado orilẹ-ede yii.

Paul Ayo ọkan to jẹ lara awọn to ṣe ifẹhonuhan ṣalaye wi pe awọn ounjẹ iranwo ati owo ti Aarẹ Tinubu fun awọn Gomina jakejado orilẹ-ede yii ni ko sọ eso rere.

Ayo ni iya ti awọn ọmọ orilẹede yii n jẹ lakooko yii ko ṣe fẹnu so, nitori gbogbo nkan ọja lo ti gbowo lori.

NLC bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, àmọ òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Eko, Osun àti Abuja kọ̀ láti kópa

Awọn osisẹ to n wosẹ niran

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meji lati kilọ fun ijọba apapọ lori bi ilu ko ti fara rọ lẹyin ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu yọ iranwọ owo epo kuro.

Ẹgbẹ NLC kọ eti ikun si ikilọ minisita ọrọ awọn oṣiṣẹ ati ipese iṣẹ, Simon Lalong ti kilọ pe iyanṣẹlodi yoo tunọ dakun iṣoro tawọn ọmọ Naijiria n doju kọ ni.

Lọjọ Ẹti to kọja lọ ni ẹgbẹ NLC kede pe oun yoo gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ meji lati kilọ fun ijọba.

NLC ni oun yoo gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹrinla tabi mọkanlelogun kaakiri orilẹede Naijiria ti ijọba ba kọ eti ikun si ohun tawọn n beere fun.

Aarẹ NLC, Joe Ajaero sọ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo tesiwaju pẹlu iyanṣẹlodi wọn titi ti ijọba apapọ yoo fi wa nkan ṣe si inira ti iyọkuro iranwọ owo ori epo ko bawọn ọmọ Naijiria.

Aworan awọn oṣiṣẹ

Awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ naa kede lati gbe ileẹjọ tipa kaakiri Naijira

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ lorilẹede Naijiria, JUSUN naa ti kede pe awọn yoo gbe gbogbo ileẹjọ tipa lọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru.

Ẹgbẹ naa ni igbesẹ yi wa ni ibamu pẹlu iyanṣẹlodi ọlọjọ meji lati kilọ fun ijọba apapọ ko le wa ojutuu si iṣoro tawọn ọmọ Naijiria n doju kọ.

Ninu atẹjade ti o fi sita, akọwe ẹgbẹ JUSUN, L.M. Adetola kepe gbogbo awọn olori ẹka ẹgbẹ naa lati ri pe gbogbo ileẹjọ kaakiri Naijiria di titi pa.

Bakan naa ni Ọgbẹni Adetola rọ gbogbo awọn olori ẹka lati ri pe awọn ọmọ ẹgbẹ tẹle idari wọn.

Ileesẹ ijọba ti ẹgbẹ osisẹ ti pa

Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ati Osun kọ lati gunle iyanṣẹlodi pẹlu NLC

Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko kọ lati gunle iynaṣẹlodi ọlọjọ meji ti ẹgbẹ NLC bẹrẹ lonii ọjọ Iṣẹgun.

Awọn oṣiṣẹ ipinlẹ kọ lati darapọ mọ NLC lẹyin ti ajọ TUC eleyii ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ rẹ kede pe oun ko ni da iṣẹ silẹ pẹlu NLC.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ ipinlẹ Eko, ASCSN fi sita ni wọn ti sọ fun gbogbo oṣiṣẹ ni ipinlẹ Eko pe ki wọn ma da iṣẹ silẹ.

Ẹgbẹ naa sọ ninu atẹjade ọhun pe gbogbo ẹka ẹgbẹ TUC ko ni ko ni kopa ninu iyanṣẹlodi NLC to bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun.

Bakan naa, ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ni ipinlẹ Osun ko ni kopa ninu iyanṣẹlodi NLC

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC nipinlẹ Osun, Kọmureedi Bimbo Fasasi

Ti kepe awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Osun ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ TUC lati ma kopa ninu iynaṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC gunle.

Kọmureedi Fasasi sọ ninu atẹjade ti oun ati akọwe ẹgbẹ naa, Abdul-Lateef Adeyeni buwọlu pe NLC ko jiroro pẹlu TUC lori iyanṣẹlodi ti o fẹ gunle.

O ni kawọn ọmọ ẹgbẹ naa kọ eti ikun si aṣẹ ẹgbẹ NLC to ni kawọn oṣiṣẹ da iṣẹ lọjọ Iṣẹgun ati l’Ọjọru tori wọn o tawọn lolobo ohun ti wọn fẹ sẹ rara.

Alaga TUC l’Osun ṣalaye siwaju sii pe ijiroro si n lọ lọwọ pẹlu ijọba apapọ lori ati wa ojutuu si iṣoro ti iyọkuro iranwọ ori owo epo ko ba awọn ọmọ Naijiria.

O ni iṣẹ si nlọ lori atunṣe ile ifọpo to wa ni ilu Port Harcourt, bakan naa ni ijọba yoo mu ileri rẹ lati pin bọọsi akero kaakiri Naijiria ṣẹ.

Bakan naa ni Fasasi sọ fawọn oṣiṣẹ pe irọrun awọn oṣiṣẹ jẹ gomina Ademola Adeleke ipinlẹ logun.

Banki to gbe ilẹkun rẹ ti pa

Ẹgbẹ oṣiṣẹ banki darapọ mọ iyanṣẹlodi NLC

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ idojutofo naa kede pe awọn yoo kopa ninu iyanṣẹlodi ẹgbẹ NLC.

Ẹgbẹ naa sọ pe awọn pinu lati darapọ NLC nitori iyanṣẹlodi yii wa lati ri pe ijọba dahun ibeere awọn lori ati wa ọna abayọ si ilu ti ko fara rọ latari iranwọ owo ori epo ti ijọba Tinubu yọ kuro.

Akọwe agba ẹgbẹ naa, Mohammed Sheikh NLC ti kan si awọn lati gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ meji yi.

O ṣeeṣe ki igbesẹ yii ṣe ipalara fun awọn eeyan ti wọn ni ohun kan tabi omiiran ṣe pẹlu ile ifowopamọ yala lori ẹrọ foonu wọn tabi nile ifowopamọ gan an.

Ko wọ pọ ki banki da iṣẹ silẹ kaakiri orilẹede Naijiria tori ipalara to pọ ni yoo mu ba ọrọ aje. Damilare Balogun,to jẹ oṣiṣẹ banki ni Naijiria sọ pe gbogbo eeyan ni iyanṣẹlodi yii yoo ṣakoba fun.

Amọ, o ni iyanṣẹlodi yii tun jẹ ọna kan gboogi ti awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ fi le fi ẹhonu wọn han si ijọba.

Balogun ni ẹrọ igbowo ATM gan an le ma ṣiṣẹ nigba tawọn oṣisẹ ba da iṣẹ silẹ.

Amọ, ọna abayọ fawọn eeyan ni lilo ẹrọ POS lati gba owo tabi fi owo ranṣẹ lasiko ti banki ba wa ni titi pa.

Ẹrọ POS yii naa ni ọpọ eeyan lo lasiko ti owo naira di ọwọn gogo latari owo tuntun ti banki apapọ CBN ṣẹ tẹ jade ni ibẹrẹ ọdun 2023.