Kí ló fa rògbòdìyàn ní Mile 2 l‘Eko, tí ẹ̀mí èèyàn kan fi bọ́?

Iroyin kan to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti fidi rẹ mulẹ pe rogbodiyan ti n lọ lọwọ ni agbegbe Mile 2 nilu Eko.
Awọn aworan ati fidio to gba ori ayelujara fihan pe se ni awọn eeyan kan da ina soju popo ti eefin dudu si n ru lọ soke.
Bakan naa ni awọn ina yii n se idiwọ fun lilọ bibọ ọkọ, ti oju ọna naa si da paro paro.
Bi o tilẹ jẹ pe awn eeyan kan n sọda lopopona marosẹ onibeji naa amọ awọn eeyan kan ti irisi wọn dabi ọmọ isọta duro sẹba ina naa.
Bakan naa ni iroyin ọhun ni wọn ti yinbọn pa eeyan kan lagbegbe naa.
Ki lo fa rogbodiyan yiii?
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko tii ri aridaju ohun to se okunfa isẹlẹ naa.
Sugbọn ileesẹ iroyin kan loju opo ayelujara lo gbe fidio kan sita pe awọn ọlọpaa amusẹya kan ti yinbọn pa eeyan kan ni agbegbe Mile 2.
Iroyin naa wa n kesi awọn araalu lati ta kete si agbegbe naa.
Amọ nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin se ayalo fidio yii
Amọ o ni oun ko tii le fidi iroyin mulẹ boya lootọ ni pe awọn igbimọ amusẹya ileesẹ ọlọpaa pa ẹnikankan ni agbegbe Mile 2.
Amọ o wa fidi rẹ mulẹ pe ikọ awọn ọlọpaa ti de sagbegbe ti rogbodiyan naa ti n waye.
O fikun pe wọn ti ko awọn ohun idiwọ ti wọn fi di oju popo naa kuro, ti igbokegbodo ọkọ si n lọ bo se yẹ.
BBC Yoruba si n tẹsiwaju lati se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yii, a mu wa fun yin laipẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















