Ọkọ̀ di pọ̀ńtọ̀ lọ́jà! Àwọn ọlọ́kọ̀ ń gbé ọkọ̀ kalẹ̀ fún títà torí ọ̀wọ́n epo
Yoruba ni ki laa jẹ ni agba ki la se.
Bi ọrọ se ri ree pẹlu ọpọ ọmọ Naijiria lasiko yii nitori ilu to le, ti ati jẹun si ti isoro nla.
Ọpọ ọmọ Naijiria to n fi mọto ayọkẹlẹ se ẹsẹ rin lo ti gbe awọn ọkọ naa ju silẹ, ti wn si n fi ẹsẹ rin kiri igboro.
Eyi tun peleke si nigba ti ọwọn ba owo lita epo pẹtirollu kan, to si di ẹgbẹta Naira tabi ko le diẹ.
Nigba igba to jẹ pe Orisa bii ọfun ko si, ojoojumọ lo n gba ẹbọ lọwọ ẹni, ohun tawn ọmọ Naijiria yoo jẹ, lo se koko si wọn lasiko yii ju yii ju owo ti wọn yoo fi ra epo sọkọ wọn lọ.
Nigba ti BBC Yoruba si bọ sigboro lati mọ bi ọpọ onimọto se n fara da ọwọn epo yii si, ẹnu ko gba iroyin nipa ohun ti oju wa ri.

Ọ̀pọ̀ ọlọ́kọ̀ ń ta ọkọ̀ tó ní Pílọ́gìì mẹ́fà láti ra onípílọ́gìí mẹ́rin
Ni ọpọ ibudo ti wọn ti n ta ọkọ ayọkẹlẹ nilu Eko ati Abeokuta, a gbọ pe esinsin lo n yọ owo imi, ni ọrọ wọn lasiko yii tori wọn ko ri taje se rara.
Koda, a gbọ pe dipo ki awọn eeyan wa maa ra mọto, se ni wọn n gbe aloku mọto wọn wa lati ta tori ọwọn epo pẹntiroolu.
Ridwan Raheem, tii se ontaja ọkọ nilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun sọ fun BBC Yoruba pe ọpọ awọn onimọto to ni ọkọ to n lo Pilọọgi mẹfa lo wa gbe awọn ọkọ naa silẹ.
“Se ẹ ri awọn mọto to n lo pilọgi mẹfa yii, maa n jẹ epo pupọ ju awọn ọkọ to n lo pilọọgi mẹrin lọ.
Eyi si lo mu kawọn onimọto to n lo awọn ọkọ onipilọgi mẹfa yii se fẹ ta wọn, paapaa awọn ọkọ nla Jeep, ti wọn si fẹ ra ọkọ kekere onipilọgi mẹrin ti ko ni jẹ epo.
Ọpọ awọn to ni mọto kansoso gan ko ni owo lati ra epo sinu mọto naa lojoojumọ
Rasheed Badru ti oun naa n fi ọkọ onipilọgi mẹfa se okoowo lati gbe ero lati ilu kan si omiran sọ fun BBC Yoruba pe oun fẹ ta mọto naa lati lọ ra ọkọ kekere onipilọgi mẹrin ti ko ni jẹ epo.
Iwadi wa tun sisọ loju rẹ pe ọpọ idile ti wọn ni mọto mẹta si mẹrin, ni wọn n ta awọn mọto wọnyi tori ọwọ epo.
Koda, a ri daju pe ọpọ awọn to ni mọto kansoso gan ko ni owo lati ra epo sinu mọto naa lojoojumọ, ti wọn si n gbe awọn ọkọ naa sile lọpọ igba lati lọ wọ mọto ero nigboro.






