"Pasitọ̀ tí ẹ̀ yàn ní Ṣọ̀ún kò bá wà lára mú àmọ́ tó bá ti ṣetán láti ṣétùtù, kò sí wàhálà"

Oríṣun àwòrán, TWITTER/THE INSIGHT
Awọn onisẹse ti n fi apa janu lori bi ijọba ipinlẹ Oyo se kede Pasitọ Afolabi Ghandi Olaye gẹgẹ bii Sọun tuntun fun tilẹ Ogbomoso.
Araba awo ilu Osogbo, Baba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ati Olori awọn onisẹṣe nipinlẹ Osun, Dokita Oluseyi Atanda ti sọrọ sita lori igbesẹ naa, eyi ti wọn lo ku diẹ kaato.
Ti a ko ba gbagbe, Pasitọ Ijọ Redeemed ni Ọmọọba Olaoye ni ọpọ ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ to kede rẹ bi Ọba tuntun, paapa awọn Oniṣẹṣe nitori gẹgẹ bi Pasitọ, o ṣeṣe ko ma tẹlẹ asa ati ise ilẹ Yoruba fun ilana ọba jijẹ.
"Ko ni si ija bi Sọun tuntun ko ba yan ẹsin kan nipọsin"
Elebuibon ni igbesẹ naa ko ba awọn Onisẹṣe lara mu sugbọn ti Ọba tuntun ba ti setan lati bọwọ fun Asa ati Ise ilẹ Yoruba, to si setan lati jẹ Ọba fun gbogbo ẹlẹsin, awọn onisẹṣe yoo ṣe atilẹyin to tọ.
“Ti ko ba ti ṣe ipọsin, ti ko si gbe ẹsin Kristẹni rẹ leri pe Ẹsin Kristẹni nikan ni oun yoo ma ṣe, ko ni si ija.
“Ti awọn Musulumi ba de, ko gbawọn, ti awọn ẹlẹsin Isẹṣe ba de ko gba wọn, iyẹn lo le lọrun fun gẹgẹ bi Ọba.”
"Ipo Ọba nilẹ Yoruba yatọ si ti ilẹ Israel tabi Bethlehem"
Baba Elẹbuibọn tẹsiwaju pe o ṣe koko ki Ọba to fẹ jẹ niluu Ogbomoso mọ pe ipo Ọba yii ki ṣe ti ilẹ Isirẹli tabi Bathleham sugbọn ti ilẹ Oduduwa, ilẹ Orisa
O fikun pe o ṣe koko fun Ọmọọba Olaoye lati mọ pe oun gbọdọ bọwọ fun awọn orisa ti wọn bọ niluu Ogbomoso.
“Ọba to ba ma jẹ nilẹ Yoruba gbọdọ ṣe gbogbo nnkan ti wọn ba ṣe niluu ilu naa.
“Ti eeyan ba wa lati idile Ọba, to ba ti mọ pe nnkan ti wọn n ṣe yii ko ba oun lara mu, lati ṣe oro, ko ma kulẹ sunmọ ibi ti wọn ti n jẹ Ọba
“Irufẹ eeyan gbọdọ fi Ọba silẹ fun awọn to le ṣe “
"Ọba ko le sọ pe orisa nikan ni ma sin, Ọba le se ẹsin pupọ"
Araba ni pẹlu bi ọlaju ṣe ti wọlu, yoo nira lati sọ fun ọba pe orisa nikan lọ gbọdọ maa sin sugbọn ṣe pataki pe Ọba mọ pe oun ko si ni ilẹ ajoji.
“Ọba to ba ti jẹ Ọba nilẹ Yoruba gbọdọ le ṣe nnkan ti awọn Yoruba n ṣe
“Bi Gomina ṣe yanb Ọba yii, awọn ilu gbọdọ da lẹkọ, ẹ kọ bi a ṣe n ṣe Ọba,
“O yẹ ko mọ itan, ko mọ oriki, ilu ebo lo ti gbe fun ọpọlọpọ ọdun, ti asa ilu ebo si wa lara rẹ
“Ko ti ṣe awọn nnkan wọnyi ko si wahala, sugbọn to ba kọ, ibi ti wahala yoo ti sẹlẹ niyẹn.”
To ba ni Ọba Kristẹni ni oun, ko ki n ṣe Ọba lọdọ awa Onisẹṣe - Dokita Atanda

Oríṣun àwòrán, RCCG JESUS HOUSE/YOUTUBE
Dokita Oluseyi Atanda to jẹ olori awọn ẹlẹsin nipinlẹ Osun ni ko ki ṣe pe awọn Oniṣeṣe faramọ ikede Ọmọọba Olaoye sugbọn o ṣe koko ki awọn bẹrẹ lọwọ Ọmọọba ko to jẹ Ọba pe Ọba jẹ olusakoso fun ohun to jẹ iṣe ati asa ilẹ Yoruba.
Atande ṣe apẹẹrẹ pẹ ẹlẹsin Kristẹni ni Ọọni ti ilu Ile Ifẹ ko to di pe o jẹ Ọba ilu Ile ifẹc sugbọn lẹyin ti wọn salaye ipo Ọba fun un, Ọọni ni oun ṣetan lari bọwọ fun asa ati ilana Ilẹ Yoruba.
“Ti Ọba tuntun yii ba ti gba, to si ti ṣe oro ipẹbi, awọn Oniṣẹṣe ko ni isoro pẹlu rẹ.
“Sugbọn to ba ti ni Ọba Kristẹni ni oun n ṣe, mo layọ lati sọ fun iyin pe ko ki ṣe Ọba lọdọ awọn Onisẹṣe.
“Arakunrin ni yoo ma jẹ, ọwọ ni a ma yọ si, ko si ẹni ti yoo dọbalẹ fun un rara ti ko ba ti le ṣe oro nitori Ade to wa lori Ọba ni a fi pe ni Ọba, ti ki si n ṣe pe Ade yẹpẹrẹ ni.
“Ọba ti ko ba ti le soro ni ipẹbi, ki n ṣe Ọba, osisẹ ijọba lasan ni.”















