"Ọmọ mi, ọmọ oṣù márùn-ún tí mo lo Hijab fún dojú bolẹ̀ bíi pé ó fẹ́ kírun, ló fi jáde láyé"
Arábìnrin Nafisatu Muideen Oyegbade lo bi Ọmọ Oṣù Marun ti Ajá yọ lẹyin rẹ to sì pa a ni Ọgbọn ọjọ nínú osu Kẹjọ ọdún 2023.
Ọjọ́ naa jẹ ọjọ ibanuje àti ọjọ́ tí arabinrin yii kò lè gbàgbé lailai gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC Yoruba nigba taa de ile rẹ.
Ikọ BBC News Yoruba ṣabẹwo sì Arábìnrin Nafisatu Mudeen Oyegbade ẹni to n gbe ni agbegbe Unity ni Halleluyah Estate, Gaa Fulani nílùú Osogbo nipinlẹ Osun.
Ẹni tí Ajá yọ ọmọ Oṣù Marun lẹ́yìn rẹ yii lo sọ pe "Ogun kata àti ikọ ni mo fẹ́ lọ ra tí Ajá fi yọ ọmọ lẹ́yìn mi to sì pá ọmọ náà tí Ajá náà sì tún bu mi jẹ ní apá ọ̀tún ati ẹsẹ̀ òtún mi."
Bakan naa lo tún ṣàlàyé pe oun ko mọ ìgbà tí wọ́n gbé oun lọ sílè Ìwòsàn. Nígbà tí òun yaju loun bá ara òun nílé Ìwòsàn nibẹ tún ní Ibanuje òun ti pọ sii nígbà tí ko si ọmọ lọwọ oun mọ.

"Gomina, Ọlọpaa, ẹ gba mi, ẹ ba mi ṣe idajọ ododo fun ẹni to ni Aja yii o!"
Arábìnrin Nafisatu Mudeen Oyegbade tí rawọ ẹ̀bẹ̀ sì àwọn Ọlọpaa ati Gomina Ademola Adeleke láti ṣe idajọ odoodo fún ẹni tí ó ní Ajá naa.
Arákùnrin Dayo Adeyemi to jẹ Alabagbe pẹlu Arábìnrin Nafisatu Mudeen Oyegbade lo ṣàlàyé pe o ti to Ọdún meji ti àwọn tí ko de inu ile ati àdúgbò naa ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ bẹẹ ko sẹlẹ rí.
Bakan naa lo sọ wípe ara àdúgbò tí ń gbe igbesẹ lori ọ̀rọ̀ naa. Bẹẹ ni ó tun rawọ ẹ̀bẹ̀ sì awọn Ọlọpaa lati ṣe idajọ odoodo lori ọ̀rọ̀ náà.
Omolola Babalola ẹni tí o ri Arábìnrin Nafisatu Mudeen nigba ti o fẹ lọ ra ogun kata lo ṣàlàyé pé igbe Ajá bu enikan jẹ loun gbọ ninu ile ti oun si rán ọmọ kan lọ wo oun tó n ṣẹlẹ̀.
Nígbà naa loun gbọ pé Ajá tí yọ ọmọ lẹ́yìn Arábìnrin Nafisatu to jẹ́ Aladugbo òun. Oni o jẹ òun ìyàlẹ́nu gidigidi fún àwọn.

Ki ni Ọlọpaa sọ?

BBC News Yoruba kan sì Arábìnrin Yemisi Opalola Agbenuso fún àwọn Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Osun.
"Ní deede agogo mẹta kọjá isẹju mokandinlogoji ni a gbọ ìṣẹ̀lẹ̀ naa.
Lójú ẹsẹ ni àti gbe Arábìnrin naa lọ sílè ìwòsàn tí Ọlọpaa tó wà ní Àgbègbè Òkè-Fa nílùú Osogbo nipinle Osun si n fún un ni itọju, tí arábìnrin naa sì tí ń gba àlàáfíà bayii.
Yemisi Opalola sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé ọwọ tí tẹ ẹni tọ ni Ajá naa bẹẹ sì ni ó ti wa ni akátá àwọn bayi fún iwadi ati fún idajọ òtítọ́.
Bakan naa ni Arábìnrin Yemisi Opalola ṣe ikilọ fun gbogbo àwọn ènìyàn to ń sìn Ajá kí wọ́n kó ṣe itọju Ajá wọn ati awon ti wọn ń sin nnkan ọsin miran kí wọ́n kó bójú tó o daadaa kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bayii má baa ṣẹlẹ mọ láwùjọ.
Ó tún pàrọwà fun àwọn olùgbé agbegbe naa ki wọ́n fi ọkàn wọn balẹ pé idajọ ododo yóò fara hàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
















