Aare Oloruntoba dog trainer: Àwọn òbí mi ò gbọ́ èdè Gẹ́ẹ̀sì, àwọn ajá òyìnbó yìí sì ń ṣọ́ ilé wọn
"Bí èèyàn míì ṣe wá tí wọn ò ní tètè mọ ohun tí olùkọ́ ń kọ wọn bẹ́ẹ̀ ló wà láàrín àwọn Ajá náà."
BBC Yoruba tọ Aare Oloruntoba lọ lati baa rin pẹlu awọn Aja rẹ to si jẹ iyalẹnu bi wọn ṣe n ṣe gbogbo nnkan ti o pa laṣẹ fun wọn lede Yoruba.
"Bi emi ati awọn Aja yii ba jọ n rin, o maa n ya ọpọlọpọ eeyan lẹnu pe wọn gbọ ede Yoruba ti mo n sọ fun wọn."

O ṣalaye pe lootọ pe awọn eeyan ni agbegbe ilẹ Yoruba maa n mu Aja lọ si oko ọdẹ ti wọn si maa n sọ fun wọn pe ki wọn le ẹran mu, amọ o ni ko wọpọ ki awọn eeyan maa kọ awọn Aja wọn lẹkọọ.
Idi ti awọn Aja kan ṣe maa n bu eeyan jẹ...

Aarẹ Oloruntoba jẹ ko di mimọ pe ara aikọ Aja lẹkọọ naa lo n fa a ti awọn Aja kan maa n bu eeyan jẹ.
O jẹ ko di mimọ pe ọpọ Aja ti wọn n ta fun awọn eeyan ko mọ wọn ri tẹlẹ, wọn o dẹ ki n mu wọn jade.
"Awọn mii ti wọn ba ra Aja, wọn kii ra Aja kekere, Aja to dagba ni wọn maa n ra torii pe wọn fẹ fi ṣọ ile.".
Eyi tumọ si pe Aja to ti dagba ti ẹ ra ti baba mọ oju ẹlomiran.
Aare ni o dara lati maa kọ awọn Aja lẹkọọ bi wọn ba ra wọn ki wọn si maa mu wọn jade lati mọ oju adugbo to fi mọ ki wọn maa gbọ ohun ọkọ ati awọn nnkan mii.


