Herdsmen attack: Ọwọ́ mi ni mo ma ń lọ fi gbé òkú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n pa - Aráàlú Yewa North

Àkọlé fídíò, Ẹ gbà wá o, àwọn Daran-daran yìí ń pa ni lẹ́kún jayé, wọ́n tún jó wa mọ́lé! - Àwọn èèyàn Yewa North

Àwọn aráàlú ilu Asa ati Agbon-Ojodu ni agbegbe ijọba ibilẹ Yewa ni ipinlẹ Ogun ti kẹnu bọ ọ̀rọ̀ lori bi wọn ṣe padanu ọpọlọpọ eeyan sọwọ awọn Daran-daran ti wọn ni wọn fẹ sọ ilu di ahoro mọ awọn lọwọ.

Ọkan lara awọn araalu ti BBC Yoruba ba sọrọ ṣalaye pe awọn iṣẹlẹ ipaniyan yii ṣoju oun koda o ni oun loun maa n lọ gbe oku ọpọlọpọ wọn.

Ẹlomiran tun ṣalaye bi awọn obinrin wọn ṣe maa n salọ si orilẹede Benin Republic ti ko jina si ilu naa tori wọn jọ pa ala pọ.

Awọn agbẹ ati olugbe ilu naa ti kigbe sita lori aduru ọsẹ ti awọn ti wọn pe ni Fulani Daran-daran n ṣe si ilu wọn eyi to ti waye lati ọdun 2021.

Nigba ti a ba ọmọ ile agbimọ aṣoju-ṣofin fun Yewa North sọrọ, Wahab Abiodun naa ṣalaye bi iwa aburu ṣe ti n ṣẹlẹ tipẹ tipẹ to si n kọ awọn to jẹ ijọba lominu gidi.

“Awọn eeyan wa a ti r’oko ka’dun, asiko to wa yẹ ki wọn kere oko wọn ni awọn ara ibi a ko ẹran de wọn a si jẹ gbogbo oko wọn patapata.

Agbẹ kan sọ fun BBC Yoruba pe "mo gbin agbado to to bii Acre meji, o ku bii ọsẹ kan kan ge e lawọn maluu de, wọn jẹ ẹ, ẹ o le ri igi kan ninu ẹ, wọn pari ẹ pata pata!"

Wahab Abiodun ṣalaye pe awọn ti tiraka titi titi ti ko niyanju koda bi wọn ba gbe ẹjọ naa lọ si agọ ọlọpaa, "kii ye wa bi wọn ṣe maa n yi ẹjọ da to jẹ pe awọn eeyan wa naa ni wọn a tun timọle."