DSS Stabs Agent in Osun: 'Ọpẹ́lọpẹ́ Ọlọ́run, ikùn ni òṣìṣẹ́ DSS kò bá ti gún mi lọ́bẹ'
Saaju ni ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba mu iroyin bi osisẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS kan ṣe gun abaniwale kan, Omoshola Oludele lọbẹ lasiko to lọ bere owo ina lọwọ rẹ.
Iṣẹlẹ yii lo waye ni nnkan bii aago meje alẹ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ Kejilelogun oṣù Kẹjọ nipinlẹ Osun.
Omoshola Oludele to jẹ Abaniwale gba Tifase Abiodun sile gẹgẹ bi ayalegbe, to si ṣe bere owo ina ti wọn ma san lososu tí Tifase Abiodun jẹ lọwọ rẹ, ni ọrọ ba ba ibo miiran yọ,.
Nígbà tí ikọ BBC Yoruba kan si Omoshola Oludele nile iwosan to ti n gba itọju ṣàlàyé pé owo iná ni oun lọ beere lọ́wọ́ Tifase Abiodun tó fi da a sí ìjà.
O ṣalaye pe lati nnkan bii oṣu mẹrin si marun-un ni awọn ti wọn jọ n gbele ti n fi ẹjọ rẹ sun oun pe kii fẹ san owo ina.
O ni eyi lo mu oun gẹgẹ bi ẹni ti wọn gba ile lọwọ rẹ lọ si ile naa lati lọ beere lọwọ rẹ idi to fi n ṣe bẹẹ ati pe ki oun bawọn pana aawọ to n maa n waye lori ọrọ ina naa.
O fi kun pe bi awọn ṣe n sọrọ lo fa ibinu yọ to si binu wọ inu yara rẹ lọ.
Omoshola ni oun lọ ba ninu yara lati lọ tu u ninu ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba to fa ọbẹ yọ si fi gun oun.
O ni eyi mu ki gbogbo awọn ara ile yooku sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si sare gbe ohun digbadigba lọ si ile iwosan.
O tẹsiwaju pe ni kete ti Tifase gun oun ni ọbẹ tan ni ọrọ naa da jo oun naa lọwọ to si sa kuro nile amọ niṣe lo pada wa pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ miiran lati dunkoko mọ awọn to jọ n gbele.
"Gbogbo awọn to n gbe ni ile naa lo ti sa kuro nile, to fi mọ awọn to gba ṣọbu si ita nitori wọn o mọ nnkan to le tun ṣẹlẹ lẹyin ọrọ naa."