Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 116 ní ìpínlẹ̀ Ogun

Ọwọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wn jẹ mẹrindinlọgọfa ni iye.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun 'Aye' lawọn ti ọwọ ba naa.
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita sọ pe ni ibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa lagbegbe Ifọ nilu Abẹokuta nibi ti wọn ti n ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun kẹdọgbọn idasilẹ ẹgbẹ okunkun naa lọwọ ti ba wọn.
"Bi a se de ibi, ni wọn tuka sugbọn ọwọ awọn ẹrindinlọgọfa , ọkunrin adọrin ati obinrin mẹrindinlaadọta.
"Awọn ohun ija bi ake, to jẹ asia ẹgbẹ naa ati egbodi oloro ni a lọwọ awọn afurasi ẹgbẹ okunkun naa.
"A ti ko awọn afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Eleweran niluu Abeokuta ni bi ti a ti n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo."
Kọminsọna ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abiodun Alamutu wa se ni ikilọ fun awọn ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ogun pe ko si aye fun ara ni gbogbo ayika ipinlẹ naa.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Ogun ti gimọ pọ lati ri pe awọn ẹgbẹ okunkun ko ri imu mi nipinlẹ naa.












