Ní Bayelsa, aráàlú ya wọ ilé tí wọ́n kó oúnjẹ ìrànwọ́ ‘Palliative’ sí wọ́n jí ọ̀pọ̀ oúnjẹ kó lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olugbe ipinlẹ Bayelsa ti yawọ ileesẹ aladani kan ti ijọba ipinlẹ naa n lo lati tọju ounjẹ ati awọn nnkan miiran pamọ si lagbegbe Kpansia ni Yenoga, ti wọn si ko ọpọlọpọ ounjẹ lo.
Awọn ẹru ounjẹ bi apo irẹsi, garri, pali indomie ati ọpọlọpọ omi ninu ike ti wọn jẹ ohun iranwọ fun awọn agbegbe kan ti wọn ni ijamba omiyale nipinlẹ Bayelsa lọdun 2020.
Isẹlẹ yii waye ni asalẹ ọjọ Aiku ni bi nnkan ago meje abọ alẹ, ti pupọ awọn olugbe agbegbe naa si tu sita lọ si ile iko ounjẹ si naa to wa ni opopona Isaac Boro pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkọ akero lati ko awọn ounjẹ.
Pupọ awọn ounjẹ naa lo ti bajẹ, ti wọn si se jẹ rara.
Lasiko ti awọn eeyan n ko ounjẹ ni awọn ẹsọ alabi de, ti wọn si le pupọ awọn eeyan kuro ni ayika agbegbe naa.
Awọn ounjẹ yii ko da fun jijẹ- Ijọba Bayelsa
Ijọba ipinlẹ Bayelsa, ninu atẹjade ti ajọ to n ei si isẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa fi ransẹ si awọn akọroyin ni ohun iyalẹnu ni isẹlẹ naa jẹ ati pe pupọi awọn ounjẹ ti awọn eeyan ji gbe ni ko da fun jijẹ awọn eeyan.
Ọga agba fun BYSEMA, Walamam Igrubia ni isẹlẹ naa waye ni bi nnkan bi ao mẹjọ ku isẹju mẹdogun lẹyin ti awọn osisẹ ti kuro ni agbegbe naa.
"Lọdun 2022 lasiko omiyale ni gbe awọn oujẹ iranwọ ile yii. ati laipẹ yii ni ọga agba wa lasiko ti n gbaradi lati wa bi a se tako ẹkun omi lọdun yii, to si ni pupọ awọn ounjẹ yii ni ko da fun jijẹ,
"Ohun to ṣe koko ni pe pupọ awọn ounjẹ yii ni ko da fun jijẹ , ti irufẹ ijọba to wa lode nipinlẹ Bayelsa kop si ni fun awọn eeyan ni ounjẹ ti ko dara lati jẹ."
"Ko si ounjẹ kankan lati ji gbe , awọn ti wọn gbe nnkan lọ, a rọ lati ma jẹ ounjẹ naa."












