Ìjọba fòfin dè wíwọ aṣọ "Abaya" nílé ẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn akẹkọọ ni wọn ti fofin de lati maa wọ Abaya ati awọn asọ miiran ti awọn obinrin Musulumi kan maa n lo ni awọn ile ẹkọ ijọba.
Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede France, Gabriel Attal lo kede igbesẹ yii, to si ni ijọba ti pinnu lati bẹrẹ fifi ofin naa mulẹ lati ọjọ kẹrin oṣu kẹsan an.
Ṣaaju ni Orilẹede France ti fofin de lilo asia ẹsin kankan ni ile ẹkọ ijọba, ti wọn si ni o lodi si ofin orilẹede naa.
Fifi asọ bori ni wọn tun ti fofin de lati ọdun 2004.
"Ti a ba wọ inu yara awọn akẹkọọ, ko yẹ ki a mọ irufẹ ẹsin ti akẹkọọ kankan n ṣe ti a ba ti foju gaani wọn".
"Mo ti pinnu pe lilo Abaya ko ni jẹ itẹwọ gba ni ile ẹkọ wa mọ."
Igbesẹ yii waye lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye ati ijiroro lori wiwọ Abaya ni ile ẹkọ lorilẹede France.
Wiwọ Abaya lo ti wọpọ ni ile ẹkọ, eyi to fi n fa iyapa laarin awọn oloṣelu, bi awọn kan ṣe gba lati fofin de Abaya ni awọn mii ni o lodi ẹtọ ọmọniyan paapa awọn obinrin Musulumi.
Minisita ni oun gbe ikilọ naa kaakiri awọn ile ẹkọ lorilẹede France ki saa tuntun to bẹrẹ loṣu to n bọ.
Lọdun 2010, Orilẹede France fofin de fifi asọ boju ni ita gbangba eyi to fa awuyewuye ati ibinu laarin awọn Musulumi to wa ni orilẹede naa.















