Irú iṣẹ wo gan ni àjọ NBS n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ tó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ní lọ́wọ́? - Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Iwadii ajọ to n mojuto onka lorilẹede Naijiria, National Bureau of Statistics lori igbanisisẹ ni awọn ṣe ifilọlẹ ilana tuntun to ba ajọ agbaye mu lori igbanisisẹ eyi to ri ida mẹrin to ja walẹ ninu ida iye ainiṣẹ lọdun 2023.
Ajọ onka, ajọ banki agbaye ati ajọ osisẹ lagbaye lo gbe iwadi naa kalẹ eyi ti wọn gbe sori ayelujara lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 2023.
Iwadi ajọ onka jẹ ko di mimọ pe ilana tuntun yii ṣàlàyé pe awọn eeyan to ni iṣẹ lọwọ ni awọn to n ṣiṣẹ́ fun owo tabi ere ati awọn to n sisẹ fun wakati kan laarin ọjọ meje.
Pẹlu ilana yii, awọn onimọ ṣe akọsilẹ awọn isẹ ti Ajọ NBS n sọrọ nipa rẹ ati bi awọn ọmọ Naijiria yoo ṣe gbajumọ bi wọn yoo se ri iṣẹ.
Akintunde Babatunde, ẹni to jẹ olori eto ni ẹka Centre for Journalism Innovation and Development ni ajọ NBS n sọrọ nipa awọn isẹ igbalode, to si ṣe akọsilẹ wọn.
Awọn isẹ ti Akintunde Babatunde darukọ ree;
- Coding
- Data analysis
- Data Science
- Social media management
- Cloud computing
- Artificial intelligence
- Cyber security
- Graphic design
- Photography
- Videography
- Copywriting
- Proofreading
- Creative writing
- Project management
- Visual assistant

Oríṣun àwòrán, Akintunde Babatunde
Babatunde ni ti orilẹede Naijiria ba fẹ gbogun ti airiṣẹṣe lorilẹede yii, o ṣe koko ti Ajọ NBS ṣe nnkan to yẹ nitori wọn yoo nilo ọpọlọpọ iwadi lati ṣe atunto ọrọ Aje lati le yanju ogun airiṣẹṣe ati iṣẹ.
Bakan naa lo ṣalaye pe ti eeyan ba ṣiṣẹ fun wakati kan lọsẹ, ko tumọ si pe o ni iṣẹ lọwọ nitori igba Naira lo rí gba laarin wakati kan, eyi ti ko tiẹ gbe pẹli pẹlu owo oṣu awọn oṣiṣẹ.
"Owo yii ko to lati san owo ọkọ lati ile lọ si ibi iṣẹ."
Ajọ NBS ni ilana ti wọn lo lo da le lori awọn oniṣowo ati agbẹ to jẹ pe owo kekere ni wọn mu wọle ti ọjọ ori wọn ko ju ọmọ ọdún mẹẹdogun soke lọ.
Ajọ ọhun ni awọn ti awọn ṣapejuwe gẹgẹ bii awọn to ni iṣẹ lọwọ ni awọn to jẹ pe wọn ko ṣiṣẹ fun ogoji iṣẹju lọsẹ, ti wọn si tun fẹ ṣiṣẹ si, ti awọn ti ko si ni iṣẹ lọwọ ṣugbọn ti wọn n wa iṣẹ lati fi ri owo tabi ere.
Babatunde ni ida ọgọrun ninu awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria lo jẹ oniṣẹ ọwọ, to si jẹ pe awọn ni ajọ NBS ṣapejuwe gẹgẹ bii awọn to ni iṣẹ lọwọ, awọn ni, oniṣowo, olounjẹ, ẹṣọ alaabo, teelọ, awakọ, abanikọle ati awọn miiran tí wọn n gba owo ojumọ.












