Ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro ilẹ̀ Afrika wà lọ́wọ́ wa, kìí ṣe ní òkèrè - Ààrẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ni awọn orilẹede ni ilẹ Afrika gbọdọ wa ọna abayọ si iṣoro wọn ni abẹle kii ṣe ni ibomiran.
Tinubu sọ eleyii lasiko to ṣepade pẹlu awọn aṣoju orilẹede lati Ethiopia, Cuba ati asoju orilẹede United Arab Emirates.
O ni awọn adari gbọdọ ṣetan lati se gbogbo ohun ti wọn ni lọkan to dara lati ṣe fun awọn araalu, ki wọn si mu gbogbo ileri wọn se.
Lasiko to n ba aṣoju orilẹede Ethiopia sọrọ, Awall Wagris Mohammed lo ti ni orilẹede Naijiria yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pẹlu awọn orilẹede toku ni ilẹ Afrika ni ẹka idokowo, eto aabo ati ọrọ aje to gbooro.
Aarẹ Tinubu rọ UAE lati pada bẹrẹ si ni fun awọn Naijiria ni Visa pada
"Awọn adari ilẹ Afrika gbọdọ ṣisẹ fun ilọsiwaju ilẹ Afrika, ki wọn si gbogunti awọn iṣoro ti wọn ba n doju kọ ni abẹle nitori ọna abayọ wa ni abẹle, ti yoo si jasi ayọ fun awọn araalu."
Aṣoju ile Ethiopia naa dupẹ lọwọ aarẹ Tinubu pẹlu ileri pe awọn yoo ri pe imugbooro ba ibasepọ laarin orilẹede Ethiopia ati Naijiria.
Ninu ipade miran ti aarẹ se pẹlu aṣoju ilẹ Cuba lo ti gboriyin fun orilẹede naa fun bi wọn se jẹ moriya fun awọn orilẹede miiran nipa eto ilera ni abẹle.
Aarẹ Tinubu lasiko to n ba aṣoju orilẹede UAE sọrọ parọwa pe ki orilẹ ede naa gbegi kuro lori aṣẹ to mu ki wọn ma fun awọn ọmọ Naijiria ni Visa lọ si orilẹede naa, ti aarẹ si ni oun yoo jiroro lati wa ọna abayọ si iṣoro naa.
O ni oun ti ṣetan lati da si ọrọ naa funra oun ati pe gbogbo awọn kọlọrọsi to ṣokunfa ti UAE fi paṣẹ bẹẹ ni awọn maa mojuto.
Ninu ọrọ rẹ ni asoju orilẹde naa ti fi da aarẹ Tinubu loju pe ayipada yoo ba aṣẹ naa, ti awọn ọmọ Naijiria yoo si ni anfaani lati wọ orilẹede UAE bii ti atijọ laipẹ.












