Sọ fún wa bí o ṣe gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀yẹ Fásitì láì lọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti Girama - Atiku sí Tinubu

Oríṣun àwòrán, OfficialBAT
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar ti pe fun alaye to pe lọwọ Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu lori ọrọ ile ẹkọ akọbẹrẹ ati girama to sọ pe oun lọ.
Atiku pe fun alaye yii ninu ọrọ kan to gbe sori opo ayelujara rẹ lọjọ Aiku.
Igbakeji Aarẹ tẹlẹri ni Aarẹ Tinubu sọ pe oun lọ ile ẹkọ akọbẹrẹ St. John's ni agbegbe Aroloya nipinlẹ Eko, ko to lọ Children's Home niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.
O fikun un pe Aarẹ tun ni oun lọ Government College Ibadan ati Richard Daley ko to morile fasiti Chicago lorilẹede Amẹrika.
"Mo ji laarọ yii pẹlu ironu bí a ṣe de ibi tí a wa yii. Lọdun 1999, Tinubu sọ pe oun lọ ile ẹkọ akọbẹrẹ St. John's ni Aroloya nipinlẹ Eko, ko to lọ Children's Home niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.
"Gẹgẹ bii o se sọ, un ni oun lọ Government College Ibadan ati Richard Daley ko to morile fasiti Chicago lorilẹede Amẹrika.
"Ṣugbọn o ya mi lẹnu lọdun 2023, fasiti Chicago lorilẹede Amẹrika nìkan ni Aarẹ Tinubu ni oun lọ."
Atiku wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati bere lọwọ Aarẹ Tinubu bawo lo ṣe lọ fasiti lia lọ ile ẹkọ akọbẹrẹ ati girama.
"Mo ha orí mi, bawo lo ṣe ṣe? Mo rọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati bere lọwọ Aarẹ gẹgẹ bii emi naa se n bere.
Saaju ni Atiku tí wọ Aarẹ Tinubu lọ ileẹjọ, to si tako esi idibo to gbe Aarẹ wọle lọjọ kẹdọgbọn oṣu kejì ọdun 2023.














