Ìròyìn òfégè ni àtẹ̀jáde tí wọ́n ń gbé kiri nípa mi - Hannatu Musawa

Hannatu Musawa

Oríṣun àwòrán, HANNATU MUSAWA

Mínísítà fétò àṣà, iṣẹ́ ọnà àti ètò ọrọ̀ ajé àtinúdá, Hannatu Musawa ti ní ìròyìn tó gba ìgbòro pé òun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ń sin ìjọba lọ́wọ́ kò wá láti ọwọ́ òun.

Hannatu sọ èyí nígbà tó ń bá ikọ̀ ìròyìn BBC Pidgin sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àìkú.

Ṣáájú ni ìròyìn kan ti gbòde pé Hannatu fi àtẹ̀jáde kan síta wípé lóòtọ́ ni òun ń sin ìjọba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ ṣùgbọ́n òun kò tàpá sófin orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àmọ́ Hannatu ti ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn ọ̀hún, tí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ kan sì ní mínísítà náà kọ́ ló fi àtẹ̀jáde ọ̀hún síta.

Láti bí ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni ẹnu ti ń kun mínísítà náà pé ó ṣì ń sin ìjọba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ ìyẹn NYSC, nítorí náà kò yẹ kí wọ́n yàn-án mínísítà lásìkò yìí.

Gẹ́gẹ́ bí òfin tó de NYSC, gbígba ipò ìjọba lásìkò tí ènìyàn bá ń sin ilẹ̀ baba rẹ̀ lọ́wọ́ lòdì sí òfin NYSC.

Láti ìgbà tí awuyewuye yìí ti ń lọ, mínísítà náà kò sọ ohunkóhun àyàfi ìgbà tí àtẹ̀jáde náà tó jáde lọ́jọ́ Àìkú níbi tí wọ́n ti ní ó sọ wí pé òun kò lòdì sí òfin tí ó bá tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún ní “lóòótọ́ ni mò ń sin ìjọba gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ lọ́wọ́ ní èyí tí mo ti bẹ̀rẹ̀ láti bí oṣù mẹ́jọ sẹ́yìn nítorí mi ò parí rẹ̀ ní ọdún 2001 tó yẹ kí n kọ́kọ́ ṣe é.

“Ní Akwa Ibom ni mo ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ètò àgùnbánirọ̀ ní ọdún 2001 lẹ́yìn tí mo parí ètò ẹ̀kọ́ gíga fásitì ṣùgbọ́n mi ò le parí rẹ̀ nítorí pé mo kó lọ sí ìpínlẹ̀ Kaduna.

“Láti ìgbà náà ló ti wà ní ẹ̀mí mi pé mà á sin orílẹ̀ èdè bàbá mi nígbà tí mo bá ní ààyè àti àǹfàní láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Mo kọ̀wé sí NYSC pé mo ti ṣetán láti sin Nàìjíríà ní ọdún tó kọjá, tí wọ́n sì gbémi sí Abuja gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ ní èyí tí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ láti bí oṣù mẹ́jọ sẹ́yìn.”

Pẹ̀lú èsì tuntun tí Husawa fọ̀ fún ikọ̀ ìròyìn BBC Pidgin yìí, ó túmọ̀ sí pé Husawa kò ì tíì fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án.

Ǹjẹ́ àgùnbánirọ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti di ipò mínísítà mú ní Naijiria?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Njẹ ẹni to n se agunbanirọ lọwọ lee di ipo minisita mu ni Naijiria abi bẹẹ kọ?

Eyi ni awọn ibeere ti awọn eniyan n beere lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu yan arabinrin Hannatu Musawa gẹgẹ bi minisita fun ọrọ igbafẹ ati aṣa.

Ajọ ajefẹtọ ọmọniyan kan, Human Rights Writers Association of Nigeria ni arabinrin naa ko lee di ipo minisita mu ni Naijiria nitori agunbanirọ ni.

Bi a ko tilẹ le fidi rẹ mulẹ pe boya agunbanirọ ni arabinrin naa abi bẹẹ kọ.

Iṣẹlẹ yii ti fa ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Naijiria.

Kini ofin sọ nipa rẹ?

Onimọ nipa ofin lorilẹede Niajiria, aghbẹjọrọ agba Femi Falana ti ni agunbanirọ ko ni aṣẹ labẹ ofin lati di ipo minisita mu ni Naijiria.

O ni ẹka ofin to de ṣiṣe agunbanirọ ni awọn ọmọ ti ko ba tii pe ẹni ọgbọn ọdun gbọdọ sin orilẹede Naijiria.

Amọ ofin naa ni ẹnikẹni to ba ti kọja ọgbọn ọdun ko ni anfaani lati sin orilẹede Naijiria.

Ohun ti awọn eniyan wa n beere ni pe se arabinrin naa ti pe ẹni ọdun ọgbọn ọdun, abi ju bẹẹ lọ.

Femi Falana ni ofin Naijiria fi idi rẹ mulẹ pe ẹni ti ko ba le di ipo aṣofin mu ni Naijiria naa ko lee di ipo minisita mu.

Ofin naa tun sọ pe ẹnikẹni ti ko ba le di ipo aṣofin mu ko lee di ipo minisita mu.

Ofin ọhun si fi idi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni to n sin ilu rẹ lọwọ, to jẹ bii agunbanirọ ko lee di ipo aṣofin mu ni Naijiria.

Minisita ọhun to jẹ ọdọ ni iroyin ti ko dara ti n tẹlee lati igba ti to ti gba ipo.

Iroyin ni lara ohun akọkọ to ṣe ni bi o ṣe n ṣe owo Naijiria baṣubaṣu, eyii ti wọn ni o lodi si ofin, ti o si lee lọ si ọgba ẹwọn fun.

Amọ ijọba ko tii gbe igbesẹ kankan lori bi o ṣe se owo naa ti wọn fẹsun rẹ kan an.