'Owó iná ni mo lọ bèèrè lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ DSS kó tó gún mi ní ọ̀bẹ'

Niṣe ọrọ di boolọ o ya fun mi ni agbegbe Tinumola Estate nílùú Osogbo, ipinle Osun nigba ti ija bẹ silẹ laaarin oṣiẹ DSS kan, Tifase Abiodun ati ẹni to gba ile lọwọ rẹ, Omoshola Oludele.
Tifase gẹ́gẹ́ bí iroyin ṣe sọ gun Omoshola, ẹni ọdun mejilelọgọta lọbẹ nigba ti ija naa du wọn.
Iroyin ni iṣẹ̀lẹ̀ yii lo waye ni nnkan bii aago eje alẹ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ Kejilelogun oṣù Kẹjọ látàrí bí Omoshola Oludele tó jẹ́ Abaniwale tó gba Tifase Abiodun sile ṣe bere owó Iná tí Tifase Abiodun jẹ lọwọ rẹ.
Iwadii ni ọrọ naa lo di ifanfa laarin wọn ko to di wi pe Tifase Abiodun, fa ọbẹ yọ to si fi gun Omoshola.
Nígbà tí ikọ BBC Yoruba kan si Omoshola Oludele nile iwosan to ti n gba itọju ṣàlàyé pé owo iná ni oun lọ beare lọ́wọ́ Tifase Abiodun tó fi da a sí ìjà.
O ṣalaye pe lati nnkan bii oṣu mẹrin si marun-un ni awọn ti wọn jọ n gbele ti n fi ẹjọ rẹ sun oun pe kii fẹ san owo ina.
O ni eyi lo mu oun gẹgẹ bi ẹni ti wọn gba ile lọwọ rẹ lọ si ile naa lati lọ beere lọwọ rẹ idi to fi n ṣe bẹẹ ati pe ki oun bawọn pana aawọ to n maa n waye lori ọrọ ina naa.
O fi kun pe bi awọn ṣe n sọrọ lo fa ibinu yọ to si binu wọ inu yara rẹ lọ.
Omoshola ni oun lọ ba ninu yara lati lọ tu u ninu ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba to fa ọbẹ yọ si fi gun oun.
O ni eyi mu ki gbogbo awọn ara ile yooku sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si sare gbe ohun digbadigba lọ si ile iwosan.
O tẹsiwaju pe ni kete ti Tifase gun oun ni ọbẹ tan ni ọrọ naa da jo oun naa lọwọ to si sa kuro nile amọ niṣe lo pada wa pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ miiran lati dunkoko mọ awọn to jọ n gbele.
“Gbogbo awọn to n gbe ni ile naa lo ti sa kuro nile, to fi mọ awọn to gba ṣọbu si ita nitori wọn o mọ nnkan to le tun ṣẹlẹ lẹyin ọrọ naa.”

Lara awon ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣoju wọn, Moronkola Ayinde àti Farinloye Victor ṣàlàyé pé awon ko mọ pe oṣiṣẹ DSS ni Tifase Abiodun lati igba ti awọn ti jọ n gbe pọ.
Wọn ni ohun to sọ fun ẹni to gba a sile ni pé òṣìṣẹ́ ilé epo kan ni oun.
Wọn ṣalaye pe lẹ́yìn ti Tifase Abiodun gun Omoshola Oludele lọbẹ tán lo pe àwọn òṣìṣẹ́ DSS ẹgbẹ rẹ kan lati wa gbe oun kuro nile lalẹ ọjọ naa.
Wọ́n ní ìyàlẹ́nu lo jẹ fun àwọn ará àdúgbò àti olùgbé inú ilé náà nigba ti wọn dédé rí awọn òṣìṣẹ́ DSS tó wá sílè tí ọhun ni aarọ kùtùkùtù ọjọ keji tí wọ́n sì wá ko gbogbo ẹrù rẹ kúrò nínú ilé náà pátápátá.
Gbogbo igbiyanju oṣiṣẹ wa lati gbọ latẹnu ajọ DSS lo ja si pabo ti wọn ko si fesi si ibeere kankan.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Patrick Longe nigba to n sọrọ ni tirẹ ni awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa amọ Tifase ko si ni ọdọ awọn pe ahamọ DSS lo wa bayii.














