Ààrẹ Amẹrika rán aṣojú sí Ààrẹ Tinubu fún ìpàdé pàtàkì

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden ti kọwe ijiroro si Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu.
Ninu atẹjade kan ti agbẹsnusọ Tinubu, Ajuri Ngelale fi lede, o ni aṣoju ijọba Amẹrika to tun jẹ igbakeji minisita to n ri si ọrọ ilẹ Afrika nilẹ Amẹrika, Molly Phee, lo fi ọrọ naa lede lasiko to ṣabẹwo si Tinubu.
Iroyin ni Phee sọ fun Aarẹ Tinubu pe ipade oun ati Biden yoo waye nibi ipade ajọ agbaye, United Nations General Assembly, UNGA, niluu New York, ti ijiroro naa yoo si tẹsiwaju ninu oṣu Kẹsan an.
Awọn aṣoju ilẹ Amẹrika naa sọ pe Tinubu nikan ni Aarẹ ti Biden yoo fi irufẹ iwe bẹẹ pe nilẹ Afrika.
Wọn ni “a mọ pe ọpọ nnkan ni a le ṣe lati ṣe idokowo olowo nla ni Naijiria, a si ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ... eyii to jẹ ọkan lara awọn ọna lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje Naijiria ati ilẹ Afrika.”
“A mọ riri ipinnu rẹ lati pese aye ti yoo mu ko ṣeeṣe.”
“Aarẹ Joe Biden n bere lati ṣe ipade pẹlu rẹ lasiko ti ipade UNGA ba n lọ lọwọ, iwọ si ni olori kan ṣoṣo nilẹ Afrika ti Aarẹ tii sọ pe oun fẹ ṣe ipade ipẹlu.”
“Eyii jẹ ami pe Aarẹ ọhun mọ riri ijọba rẹ, o si bu iyi fun ọ.”
Ninu idahun rẹ, Aarẹ Tinubu sọ pe rogbodiyan to n waye ni orilẹ-ede Niger ko ni di oun lọwọ lati ṣe ohun ti yoo ṣe anfani fun awọn ọmọ Naijiria.
O sọ fun awọn aṣoju ilẹ Amẹrika naa pe ajọ ECOWAS yoo gbiyanju lati lo ọna alaafia lati yanju rogbodiyan to n waye ni Niger.
Awọn aṣoju Amẹrika naa si fesi pe digbi lawọn wa lẹyin ipinnu ati igbesẹ ECOWAS.












