Igbó orò ni wọ́n sin òkú pásítọ̀ tó pa ara rẹ̀ torí olólùfẹ́ rẹ̀ sí

Pasitọ Igbokwe

Oríṣun àwòrán, others

Awọn eeyan ilu Nnewi ti ṣalaye pe inu igbo oro ni wọn sin oku pasitọ Prosper Igbokwe to gbẹmi ara rẹ nitori ọrẹbinrin rẹ to nifẹsi lati fi ṣaye kọ lati fẹẹ.

Ìròyìn ní pásítọ̀ náà fò láti orí ilé alájà méjì tó sì kú lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn ti olólùfẹ́ rẹ̀ sọ fun un pe oun ko ṣe mọ. àdédé jà kulẹ̀.

Ohun ti a gbọ ni pe inu igbo ni wọn sin pasitọ naa sii gẹgẹ bi aṣa ilu Leru to jẹ ilu abinibi rẹ fun ẹnikẹni to ba gba ẹmi ara rẹ.

Ohun ti awọn to sunmọ oloogbe naa sọ ni pe oun funra rẹ lo ran arabinrin naa lọ sile ẹkọ giga titi to fi jade ile ẹkọ giga fasiti ki o to sọ pe oun ko le fẹ pasitọ naa.

Wọn ni igbo oro ni wọn sin in si ni ilana pẹlu aṣa ilu naa fun ẹnikẹni to ba ṣe ohun ‘eewọ’

Bawo ni Pásítọ̀ Igbokwe ṣe gbẹ̀mí ara rẹ̀ nítorí ọ̀rẹbinrin to kọọ silẹ

Pásítọ̀ ìjọ kan ní ìlú Nnewi, ìpínlẹ̀ Anambra tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pásítọ̀ Proper Igbokwe ti gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀.

Ìròyìn ní pásítọ̀ náà fò láti orí ilé alájà méjì tó sì kú lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣàdédé jà kulẹ̀, tó sì kọ̀ láti gbà láti jẹ́ aya rẹ̀.

Ẹbí pásítọ̀ náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ́rọ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ṣàlàyé pé pásítọ̀ tó dolóògbé náà ló jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún ló rán ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ náà ní ilé ẹ̀kọ́ tó fi jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga.

Ó ní pásítọ̀ náà ló jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Leru ní ìjọba ìbílẹ̀ Umumeochi, ìpínlẹ̀ Abia gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ ní oṣù tó kọjá nítorí tí ọ̀rẹ́bìnrin tí wọ́n jọ ń ṣe wọléwọ̀de kọ̀ láti gbà láti jẹ́ aya rẹ̀.

Pásítọ̀ Prosper Igbokwe

Oríṣun àwòrán, Others

Ó ṣàlàyé pé ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé ẹni tó jẹ́ pásítọ̀ pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀ le hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ó fi kun pé gẹ́gẹ́ bí àṣà ìlú àwọn inú igbó ni wọ́n máa ń sin ẹnikẹ́ni tó bá pa ara rẹ̀ sí nítorí ohun èèwọ̀ ni onítọ̀hún ṣe.

“Ní ọjọ́ Ẹtì ni a sín sínú igbó ní ìlú rẹ̀.”

Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kàn sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra, Tochukwu Ikenga ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò gbọ́ sí ìròyìn náà.