Wo èrèdí tí àwọn Mùsùlùmí Cape Town ṣe gbé Quran yìí sínú àpótí ‘bullet proof’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Quran ti imaamu ọmọ orilẹ-ede Indonesia kan fi ọwọ kọ ni nnkan bii igba ọdun sẹyin ti di ohun manigbagbe fun awọn Musulumi agbegbe Cape Town, ni South Africa bayii.
Awọn to n ṣe atunṣe si mọṣalaṣi Auwal lo ṣawari rẹ lasiko ti wọn n wo apakan mọṣalaṣi naa ni nnkan bii ọdun 1980.
Awọn oniwadii ijinlẹ gbagbọ pe imaamu kan ti orukẹ rẹ n jẹ Abdullah ibn Qadi Abdus Salaam, ti apẹle rẹ n jẹ Tuan Guru lo kọ Quran naa lẹyin to ha gbogbo rẹ sori lẹyin ti wọn gbe lọ si Cape Town gẹgẹ bii ẹlẹwọn lati erekusu Tidore, ni Indonesia, lọdun 1780.
Cassiem Abdulla, ọkan lara awọn igbimọ to n ṣatunṣe mọṣalaṣi naa sọ fun BBC pe “O ti dọti nigba ti a ṣawari rẹ, ni ṣe lo da bii pe ẹnikẹni ko tii de ibi ti Quran naa wa lati ọgọrun-un ọdun sẹyin bo ṣe dọti to.”
“Awọn to n kọ ile naa tun ṣawari akọsilẹ kan nipa ẹsin Islam, eyi ti Tuan Guru kọ ṣaaju.”
Quran naa ti apakan oju ewe rẹ ti ja sọnu lo ṣi wa digbi, yatọ si awọn oju ewe kọọkan to ti faya lẹgbẹẹ.
Bakan naa ni inki dudu ati pupa ti wọn fi kọ Quran ọhun ni ede Arabic ko parẹ rara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipenija kan ṣoṣo to wa niwaju awọn Musulumi agbegbe naa lasiko ti wọn ṣawari rẹ ni bi wọn yo ṣe ri gbogbo oju ewe Quraan ọhun to ku ki gbogbo oju ewe rẹ le pe perepere.
Amọ ṣa, oloogbe kan, Maulana Taha Karaan, ko awọn eeyan kan sodi lati ṣawari awọn oju ewe Quaran naa to ku, wọn si ṣe aṣeyọri lati so gbogbo rẹ pọ lẹyin ọdun mẹta gbako.
Ni bayii, wọn ti gbe Quran naa si gbagede mọṣalaṣi Auwal, eyi ti Tuan Guru da silẹ lọdun 1794, to si jẹ mọṣalaṣi akọkọ ni orilẹ-ede South Afrika.
Igba mẹta ọtọọtọ ni awọn kọlọrọsi kan ti gbiyanju lati ji Quran naa gbe, eyi to mu ki awọn alaṣẹ mọṣalaṣi ọhun lọ gbe sinu apoti kan ti ina ko le jo, ti ọta ko si le wọ inu rẹ.












