Ikú bàbá mi lo sọ mí di fẹ́ndọ̀ láti ọdún 1974; mo ṣì ń ta "paper" d'òní àmọ́ ohun tójú mi ń rí ... - Nureni Adesegun

Àkọlé fídíò, Arakunrin Adesegun Nureni tó ti n ta iwe iroyin lati ọdun 1974 ba BBC sọrọ lori iriri rẹ̀
Ikú bàbá mi lo sọ mí di fẹ́ndọ̀ láti ọdún 1974; mo ṣì ń ta "paper" d'òní àmọ́ ohun tójú mi ń rí ... - Nureni Adesegun

Lati ọdun 1974 ni Baba Nureni Adesegun ti n ta iwe iroyin nigboro ilu Ibadan to dẹ ṣi n ta a titi di asiko yii.

inu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, ninu iṣẹ tita iwe iroyin yii naa lo ti n ko owo jọ diẹ diẹ to fi n tọju ẹbi rẹ koda to tun fi ran ọmọ lọ si ile ẹkọ.

Nureni ninu fidio yii mu wa rin irinajo ninu iranti bi eto rọ aje ṣe ri ni aye atijọ pẹlu òwò to yan laayo.

Laye igba naa, o fihan pe nipasẹ iwe iroyin nikan lawn ma fi n gbọ iroyin nipa ohun to ba n lọ nilu amọ o fi we ode oni to jẹ wipe imọ ẹrọ ati ayelujara ti yi gbogbo nnkan pada.

Bawo wa ni baba yii ṣe n jẹun, tọju ara rẹ laye ti awọn eeyan ti n ka iroyin lori intanẹẹti bayii?

Ọgbẹni Nureni

"Ṣílè kan àbọ̀ là ń ta ìwé ìròyìn ní 1974 a sì n jẹun; Mo ṣì ń ta "newspaper" àmọ́ ohun tójú mi ń rí ..."

"Ọpọ eeyan maa n bi wa pe ṣe wọn ṣi n ra "paper" bayii amọ a dupẹ a n ta a a si n ri ounjẹ jẹ"

Baba yii ni "iṣẹ to wu oun ṣe tẹlẹ. mo kọ ọ amọ ko yọri, lati igba ti mo ti n ta "paper", mo dupẹ lọwọ Ọlọrun".

Ọgbẹni Nureni ni laye ode oni, oun kan n tiraka lati gbe ile aye ni pẹlu iṣẹ iwe iroyin to n ta.

Ọgbẹni Nureni