Èmi àti Ooni ti mọra l'óde ọ̀run ká tóò pàdé l'óde ayé - Olori Ashley

Olori Ashley ati Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Afolasade

Ọkan ninu awọn olori ni aafin Ooni Ile-Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Olori Afolashade Ashley Oggunwusi, ti ṣalaye pe lati ọdun marun-un sẹyin ni Ooni ti tọrọ oun gẹgẹ bi iyawo, ṣaaju ayẹyẹ ti gbogbo aye ri.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Olori Afolashade ṣe pẹlu iwe iroyin The Sun, lo ti sọ pe Ooni Ooni ti yọju si ẹbi oun lati fi erongba rẹ han, ṣugbọn oun ọmọ kan ṣoṣo ti oun bi ṣi kere pupọ.

Yatọ si eyi, Afolashade sọ pe Ooni ko le ṣe igbeyawo pẹlu oun tabi kede rẹ, nitori eewọ to rọ mọ itẹ ọba Ile-Ife pe Ooni ko le fẹ obinrin to ti bimọ ri gẹgẹ bi olori rẹ akọkọ.

“Mo ni lati duro fun ọpọ ọdun pẹlu suuru, lati le daabo bo ọmọ mi. Ohun to si da mi loju nigba naa ni pe mo mọ pe ko si bo ṣe pẹ to, emi ni mo ni ọkọ mi.

“Awa mejeeji mọ nnkan to wa laarin wa, a si tun mọ pe ipadabọ awọn alaalẹ ni awa mejeeji jẹ lori itẹ awọn baba wa.”

Olori Afolashade ni ṣaaju ki Ooni to gbe oun ni iyawo, ni oun ti n pe e ni ọkọ lai fi ṣe pe o ti fi oun han gbogbo aye.

Olori Ashley ati Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Afolasade

Emi ati Ooni ti mọ ara wa ni ode ọrun ka to o pade laye

Nigba to n tẹsiwaju ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Olori Afolashade ṣalaye pe ẹmi to wa ninu oun ati Ooni lo so wọn pọ nigba ti wọn kọkọ pade.

“Nigba ti mo pade ọkọ mi ni ọpọ ọdun sẹyin, iru eeyan ti a jẹ ninu ẹmi lo so wa pọ, nitori pe a ti mọ ara wa ni ode ọrun.

“Eyi lo mu ko rọrun fun wa lati tete di ọ̀kan ni ode aye.”

Olori tun ṣalaye pe Ooni Ogunwusi paapaa lo ran oun lọwọ lati ni òye kikun nipa iru ẹ́dá ti oun jẹ́ lode ọrun.

Lati kekere ni mo ti wa ninu iṣẹṣe

Olori Ashley kopa nibi ọdun iṣẹẹṣe

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Afolasade

Afolashade ṣalaye pe lootọ ni baba to bi oun jẹ Kristiẹni, ṣugbọn o tun jẹ oniṣẹẹṣe ninu ẹgbẹ Awo Funfun.

“Lati igba ti baba mi si ti wo akọsẹjaye mi, lo ti mọ pe ipasẹ rẹ ni ma a tọ ninu iṣẹẹṣe. Eyi si lo mu ki wọn o fi oju mi mọ ilana naa lati kekere ninu gbogbo awọn ọmọ to bi.

Botilẹ jẹ pe olori pọ ni aafin Ooni, Olori Afolashade sọ pe igba aye alaafia ni awọn n gbe, ati pe ilu London ni oun n gbe ju.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ti mọ bi eeyan ti n gbe pẹlu orogun, nitori pe ile olorogun ni wọn ti bi oun ti wọn si ti tọ oun dagba.

Taa ni Olori Afolashade Ogunwusi?

Olori Ashley

Oríṣun àwòrán, Olori Ashley Afolasade

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Afolashade Ashley Ogunwusi jẹ ọkan lara awọn olori ti Ooni Adeyey Ogunwusi fẹ ni ọdub 2022, lẹyin ti olori rẹ keji, Naomi Silekunola kọ ọ silẹ.

Ṣaaju igbeyawo wọn, Afolashade ti bi ọmọbinrin kan ti wọn jọ n gbe nilu London. Ọmọ naa ti to ọmọ ọdun mẹwaa bayii.

Oluṣiro owo ati oniṣowo ni niluu London.

Ni Ọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Kabiyesi Ọọniriṣa gbe Ọmọbabinrin Ashley niyawo gẹgẹ bi iyawo kẹrin.

Gẹgẹ bi ọpọ iroyin ti ṣe sọ, irinajo awọn mejeeji yii ti pẹ ki o to di pe Ashley wọle gẹgẹ bi iyawo niṣulọka.

Ọmọ ilu ile ifẹ ni Olori Ashley, idile ọba loun naa ti wa.

Ni ile baba rẹ, Ọmọọba Adegoke to wa ni adugbo Olubuse lopopona Ẹdẹ nilu Ile ifẹ si ni igbeyawo rẹ ti waye.

O wa lati ile ọla ti wọn ti n jọba ti wọn pe ni Lafogido ni agboole Adeagba ni Ile Ife

Iwe ẹri imọ ijinlẹ mẹta ọtọọtọ ni imọ iṣiro owo lati fasiti ilu Greenwhich.

Oun si ni oludasilẹ ajọ ẹlẹyinjuanu Ashley Adegoke Foundation eyi to fi n sọri iranti baba rẹ Ọmọọba Jacob Adebiyi Adegoke.