Wo arẹwà mẹ́jọ tó ti jẹ́ Ayaba fún Ooni Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Facebook
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
Igbeyawo Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji pẹlu Ọmọọbabinrin Ronkẹ Ademiluyi lọjọbọ.
Olori Ronkẹ ni Olori kẹfa ti yoo wọ Aafin Oodua laarin oṣu meji sira wọn lẹyin ti Ọba Ogunwusi pada si ipo apọn fun oṣu mẹsan an lẹyin ti Naomi Silẹkunọla pinya pẹlu rẹ loṣu kejila ọdun 2021.
Ta ni awọn obinrin to ti ba kabiyesi Ọọniriṣa pin iyẹwu wọ, yala ki o to de ori itẹ ni o tabi lẹyin to gun ori itẹ?
Eyi ni alaye lori awọn obinrin naa:
Adebukọla Bombata

Oríṣun àwòrán, other
Kabiyesi Ọọni Ogunwusi ti kọkọ fẹ Adebukola Bombata ki o to de ori oye ṣugbọn ituka waye lẹyin iwuye rẹ.
Adebukola Bombata ni obinrin imii to jade ninu aye Oba Ogunwusi ṣaaju ki o to jẹ Oba Ile Ife.
Lọdun 2008 ni wọn ṣe igbeyawo ni won jọ gbe papọ ki onikaluku to pin gaari.
Bi awọn kan ṣe sọ pe Adebukola fi Ooni Ogunwusi silẹ lọdun 2015 nitori pe ipo Oba naa ko wu u ni àwọn mii ni pe nkan miran lo jẹ ki wọn fi ara wọn silẹ.
Olori Wuraola

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Lọdun 2015 lẹyin ti Ooni gori aleefa itẹ awọn baba nla rẹ ni o gbiyanju iyawo miran.
Ooni ko duro nile Yoruba rara lati lọ mu arẹwa to wu Kabiesi.
Benin ni ipinlẹ Edo to jẹ ọmọ iya Oodua ni Oba Ogunwusi ti lọ gbe Olori Zainab Otiti Obanor Wuraola.
Igbeyawo Ọọni Ogunwusi ati Olori Wuraọla foriṣanpọn loṣu keje ọdun 2017.
Naomi Silekunola
Apọn ni Ọoniriṣa pada si lẹyin ti Olori rẹ ana, Ṣilẹkunnọla Naomi fi silẹ ni oṣu kejila ọdun 2021.
Lọdun 2018 ni Oba Adeyeye Ogunwusi gbe Ajihinrere obinrin Naomi Silekunola lati ipinlẹ Ondo ni iyawo.
Oba Oke fi omokunrin lantilanti, Tadenikawo Ogunwusi ta wọn lọrẹ lọdun to kọja.
Olori Naomi wọ aafin Oodua gẹgẹbi Olori tuntun lẹyin Wuraọla Otiti lọdun 2018 ṣugbọn ori ayelujara Instagram lo ti kede ituka igbeyawo oun ati ọbalaye naa.
Silekunola Moronke ni iyawo alarede ikeji ti Alayeluwa Ọba nla nla ni ilẹ̀ Yoruba, Ooni Ile Ife yóò fẹ niṣu lọka.

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Iyawo Ooni Ogunwusi ti Ile Ife, Silekunola Moronke Naomi dédé ya awọn eniyan lẹ́nu ni oṣu kejila nigba to jade sori ayelujara lati kede pe oun ti fi àkọlé Olori ti ilu Ile Ife silẹ.
O ni oun ti ń da ṣe iya ọmọ oun, Tadenikawo, to si ni Olori awọn eniyan lo ku ti oun n jẹ bayii.
Bakan naa lo ṣàlàyé pe ọmọ tí oun bi fun Ooni ni ọmọ àkọ́kọ́ ti oun yoo bí laye oun, lodi si iroyin ti awọn kan n gbe kiri.
Ko si ẹni ti ko bọ̀wọ̀ fun ipo Ooni tori igbagbọ awọn Yoruba ni pe iran Oduduwa to jẹ Orisa ilẹ̀ Yoruba ni Ooni ti ṣẹ wa.
Eyi lo mu ki iyi pọ gidi fun Ooni ati iyawo rẹ.
Ẹwẹ, Olori Silekunola tun sọ ninu atẹjade rẹ pe ọ̀tọ̀ ni oju ti Ooni n fihan fun araye ọ̀tọ̀ to n fihan ninu ile.
Mariam Anako

Oríṣun àwòrán, Mariam Anako
Ni ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2022 ni Ọọni Ile Ifẹ gbe Mariam Anako wọle gẹgẹ bi olori rẹ.
Igbeyawo naa waye lẹyin oṣu mẹsan ti Naomi Ṣilẹkunọla, fi aafin silẹ to si kede lori ayelujara pe oun ko ṣe mọ. Ki ẹnikẹni masi ṣe pe oun ni Olori laafin Ọọni ile ifẹ mọ.
Anako ni iyawo kẹrin ti Kabiyesi Ọọni Adeyẹye Ogunwusi yoo fẹ laye rẹ.
Ki o to di olori ni aafin, gbajumọ oniṣowo epo ni arabinrin Mariam Anako, ọmọ ẹya Ebira ni ipinlẹ Kogi si ni.
Ilu Ilorin ni a gbọ pe awọn obi rẹ wa.
Bakan naa la gbọ pe Mariam padanu baba rẹ lati igba ewe rẹ, ile ọga ọlọpaa patapata ri lorilẹede Naijiria, Mohammed Dikko Abubakar ni wọn si ti tọọ dagba.
Iya rẹ pẹlu jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti.
Olori Elizabeth Ọpẹoluwa

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gẹgẹbi ọpọ iroyin ṣe sọ, ti awọn agba oye nilu Ifẹ naa si tun fidi rẹ mulẹ, ọjọ diẹ lẹyin ti Ọọni ṣe igbeyawo pẹlu olori Mariam ni awọn agbagba ilu Ifẹ kan lọ si agbegbe Magodo nipinlẹ Eko lati tọrọ Dokita Elizabeth Ọpẹoluwa Akinmuda gẹgẹ bi olori laafin Adimula nilu ileIfẹ.
Onimọ nipa imọ ẹrọ Data Processor ni.
Ọmọ ilu Ondo nipinlẹ Ondo ni Olori Ọpẹoluwa, orilẹede Scotland lo si fi ṣe ibujoko ṣaaju igbeyawo rẹ pẹlu Ọọni ile ifẹ.
Olori Tobi Phillips

Oríṣun àwòrán, Tobi Phillips/ instagram
Lẹyin to pinya pẹlu olori Wuraola Zainab Otiti, ni iroyin ti n kan nigba naa lọdun 2018 pe Ọọni n gbero lati fẹ Tobi Phillips ẹni to ti figba kan ri gba ade omidan arẹwa.
Ọmọ bíbí ìlú Erinje-Ikale ní Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Tobi Phillips. Ile ẹkọ giga fasiti ilu Eko lo si ti kẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu imọ ninu ohun alumọni inu omi.
Òun ló ni iléeṣẹ́ gbajúgbajà aránsọ QTP Luxury Fashion tó sì ti ń ránṣọ ìgbàlódé láti ọdún 2018.
Yàtọ̀ sí aṣọ rírán Tobi jẹ́ arìnrìn oge láti ìgbà tó ti wà ní ilé ẹ̀kọ́.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Tobi ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Blueprint lọ́dún 2014, ó ní ọdún 2009 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rin ìrìn oge nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ilé ẹ̀kọ́.
Ó ní gbígbégbá orókè níbi ìdijé omidan Madam Tinubu Hall ní ọdún 2009 ló ṣí ojú òun sí ohun tí òun ti ń gbèrò láti ṣe láti kékeré òun wá.
Ìrìn oge ti gbé Tobi dé orílẹ̀ èdè South Korea nígbà tó lọ ṣojú àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀ níbi tó ti gba oyè omidan ilé ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ adúláwọ̀ àgbáyé (World Miss University Africa).
Ọjọ kẹsan an oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Ọọni gbe e niyawo.
Olori Ashley Fọlaṣade

Oríṣun àwòrán, Ashley Adegoke
Ni Ọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Kabiyesi Ọọniriṣa gbe Ọmọbabinrin Ashley niyawo gẹgẹ bi iyawo kẹrin.
Gẹgẹ bi ọpọ iroyin ti ṣe sọ, irinajo awọn mejeeji yii ti pẹ ki o to di pe Ashley wọle gẹgẹ bi iyawo niṣulọka.
Ọmọ ilu ile ifẹ ni Olori Ashley, idile ọba loun naa ti wa.
Ni ile baba rẹ, Ọmọọba Adegoke to wa ni adugbo Olubuse lopopona Ẹdẹ nilu Ile ifẹ si ni igbeyawo rẹ ti waye.
O wa lati ile ọla ti wọn ti n jọba ti wọn pe ni Lafogido ni agboole Adeagba ni Ile Ife
Iwe ẹri imọ ijinlẹ mẹta ọtọọtọ ni imọ iṣiro owo lati fasiti ilu Greenwhich.
Oun si ni oludasilẹ ajọ ẹlẹyinjuanu Ashley Adegoke Foundation eyi to fi n sọri iranti baba rẹ Ọmọọba Jacob Adebiyi Adegoke.
Ilu Oba United Kingdom lo gbe fun ọpọlọpọ ọdun.
Ta ni Olori Ronke Ademuluyi?

Oríṣun àwòrán, queen moremi ajasoro international
- Idile ọba ni wọn bi Ronke Ademiluyi si ni Ile Ife
- Oun ni arọmọdọmọ Ooni Ajagun Ademiluyi to ti rewalẹ aṣa
- O lo ibẹrẹ aye rẹ ni Naijiria ko to tẹkọ leti lọ silẹ Gẹẹsi
- Ademiluyi kẹkọ gboye nipa imọ ofin ni fasiti Thames Valley niluu London
- Oun ni oludasilẹ ati olootu eto Africa Fashion Week to maa n waye lọdọdun niluu London, nibi ti wọn ti maa n ṣe igbelarugẹ aṣọ ati aṣa ilẹ adulawọ
- Ademiluyi lo wa nidi eto ‘Queen Moremi,’ oun naa tun ni oludasilẹ ileesẹ Adire Oodua
Ti ẹ ko ba gbabe, ọsẹ to kọja yii ni Ooni gbe Ashley Adegoke niyawo, iyẹn lẹyin to ti kọkọ fẹ Tobi Philips ati Mariam Anako ṣaaju.















