A kò mọ báwọn ọmọ ìgbìmọ̀ olùdarí CAN kan ṣe wọnú ìgbìmọ̀ ìpolongo ìbò Tinubu - CAN

Oríṣun àwòrán, @officialBAT
Ẹgbẹ ọmọlẹ́yìn Kristi ni Naijiria, CAN, ti sọ pe oun ko mọ nipa awọn pasitọ kan ti orukọ wọn jáde ninu igbimọ ipolongo ibo fun oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress, Bola Tinubu.
Ọjọru ni igbimọ ìpolongo naa gbe awọn orukọ mìíràn jade, pẹlu afikun awọn orukọ tuntun si eyi to ti kọkọ fi sita ni oṣu to kọja.
Aarẹ ẹgbẹ́ CAN, Archbishop Daniel Okoh sọ pe iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn pe akiyesi oun si àwọn orukọ naa.
Okoh sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita pe o ya oun lẹ́nu pupọ lati ri orúkọ àwọn oloye ẹgbẹ́ CAN kan, ti ṣáá wọn yoo tán laipẹ, ninu orúkọ igbimọ ìpolongo ibo Tinubu/Shettima 2023.
"A ti bẹrẹ iwadii lori bawọn ọmọ igbimọ alaṣẹ CAN, ṣe di oloselu ọsan gangan."
Alufa Okoh sọ pe iru iwa bẹẹ jẹ eyi to kọ ni lominu nitori pe "o tako ilana ajọ CAN, eyi ti kii ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ́ oṣelu kankan".
O ni oun ko lọwọ si iru igbeṣẹ awọn eeyan naa lasiko yii tabi ni ọjọ iwaju.
"Mo fi n da gbogbo Kristẹni to wa ni Naijiria ati aráàlú loju pe lati igba ti iroyin naa ti tẹ mi lọwọ ni mo ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ CAN ṣe di oloselu ọsan gangan."
Aarẹ CAN sọ pe ẹgbẹ́ naa yoo gbe igbeṣẹ to yẹ, lati daabo bo awọn ilana ẹgbẹ́ naa ti oun n dari.
Ṣáájú ni awuyewuye ti n waye lori bi oludije sipo aarẹ ni APC, Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima ṣe jẹ ẹlẹ́sìn Musulumi.
Ẹgbẹ CAN paapaa koro oju si igbesẹ naa.
Awọn ọmọ igbimọ CAN to wa ninu igbimọ ipolongo ibo Tinubu ree:
Gẹ́gẹ́ bi iwe iroyin Punch ṣe sọ, àwọn ọmọ igbimọ oludari CAN to wa ninu igbimọ ipolongo Tinubu/Shettima ni:
Igbakeji Akọwe Agba fun CAN, Apostle Biodun Sanyaolu (oludari ẹka akanṣe isẹ ninu ìpolongo ibo)
Alaga CAN nipinlẹ Eko, Stephen Adegbite; Oludari ẹka ofin ninu CAN, Comfort Chigbue ; ati Testimony Onifade, oluranlọwọ pataki fun aarẹ CAN tẹlẹ, Supo Ayokunle.
Àwọn yooku ni Kwankur Samuel, Ọjọgbọn Para Mallam ati Victor Ivoke.
Sugbọn ṣa, orukọ Apostle Biodun Sanyaolu nikan ni BBC Yoruba ṣi fidi rẹ múlẹ̀.









