Ọmọlúàbí ni Tinubu jẹ́ sí mi àmọ́ ń kò fẹ́ kó dépò ààrẹ lọ́nà èrú- Adebanjo
Ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn Gúúsù Nàíjíríà ti ṣe ààrẹ, ìlà oòrùn ló kàn - Ayo Adebanjo:

Oríṣun àwòrán, Adebanjo
Nibayi ti eto ipolongo ibo aarẹ ti bẹrẹ nigbaradi feto idibo gbogbo gboo to n bọ ni Naijiria, oniruru awuyewuye lo n lọ kaakiri.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni asaaju ẹgbẹ Afenifere, Alagba Ayo Adebanjo kede pe ẹyin oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi ni oun to si.
Bakan naa lo ni oun ko ni se atilẹyin fawọn oludije aarẹ fun ẹgbẹ oselu PDP ati APC, eyiun Atiku Abubakar ati Bola Tinubu.
Idi ree ti BBC Yoruba se kan si asaaju ẹgbẹ Afenifere, Alagba Ayo Adebanjo lati se afọmọ ohun to ri, to fi yan oludije aarẹ kan nipọsin.
Uncle ni Tinubu n pe mi, o maa n fi nnkan ransẹ si mi amọ oselu ti gbe le Tinubu lọwọ lo n se – Adebanjo
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alagba Ayo Adebanjo ni kii se pe oun ko fẹran oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Amọ o ni kii se ilan aoselu ti oun gbe le Tinubu lọwọ lo n se.
“Tinubu ko duro ki mi ri, o maa n tẹ ki mi ni, bẹẹ ni Uncle lo n pe mi.
Amọ kii se ilana oselu ti mo gbe le lọwọ lo n se, emi ati Tinubu gan sun mọra ju awọn alatilẹyin rẹ to n bu mi lọ.
Bi Tinubu ba si di aarẹ lonii, maa jẹ anfaani rẹ ju awọn alatilẹyin rẹ gan lọ.
Amọ ọna eru ni n ko fẹ ko gba di aarẹ.”
Ofin Naijiria lo la a kalẹ pe ka maa pin ipo agbara ni dọgba-dọgba”
Alagba Adebanjo tẹsiwaju pe o ti wa ni akọsilẹ ninu ofin Naijiria pe gbogbo ipo to ba da awọn ẹya to wa ni Naijiria papọ, a gbọdọ maa pin dgba-dọgba ni.
O ni ofin Naijiria lo ni ipin ti ẹya kan ko gbọdọ ju ti ekeji l eyi to mu ka ni ofin ’Federal Character’, tii se ilana bu u re, la a re, ikan ko gbọdọ ju omii l.
Adebanjo tẹsiwaju pe idi ree ta se ni ilana ’Rotation’ eyiun pinpin nnkan kaakiri.
Eyi si lo ni o mu ki awọn ologun wa yan Yoruba lati di aarẹ lẹyin ti wọn da ibo aarẹ to gbe MKO Abiola wọle nu lọdun 1993.
“Ẹya Hausa, Yoruba ati South South ti se aarẹ, awọn ẹya Igbo lo kan”
Adebanjo ni ni awọn ẹya to wa lapa ariwa Naijiria lo ti dari orilẹede yii, bakan naa ni ẹya Yoruba ati awọn eeyan ẹkun aarin gbugbun lati guusu Naijiria ti se aarẹ saaju.
O ni kii se awọn ẹya to ti jẹ aarẹ saaju yii lo tun yẹ ka to si lẹyin, to si wa n beere pe ẹya Igbo n kọ?
“Ẹyin wọn ni awa Afenifere duro si, a dẹ n fẹ ominira ẹ̀tọ́ ati ètò fun Naijiria.
Ẹyin ki ipo aarẹ lọ sọdọ ẹya Igbo ni awa duro si, se ibo ko wa lati South East ni?
“Sunday Igboho ati IPOB yoo dakẹ, bijọba ba se atunto Naijiria, eyiun ‘Restructuring’
Nigba to n woye lori ijijagbara fun orilẹede Yoruba ta mọ si Yoruba Nation, Adebanjọ ni ko si ẹnikẹni to le jade pe awọn n ja fun ilẹ Yoruba ju Afenifere lọ.
Bakan naa lo ni ko si ẹni kankan to wa ni aye yii, to le ni oun n ja fun ifẹ Yoruba ju oun Ayo Adebanjo lọ.
O wa fi ọwọ sọya pe oun ko se ounkohun tako ipe fun Yoruba Nation nitori awọn ọmọ oun lo n lewaju ipe naa.
“Awọn ti oju n kan pe ti wọn ko ba se Naijiria ni ẹtọ ati ofin, yoo dara ka kuku yapa lo n pe fun Yoruba Nation.
Awọn ologun lo gbe iwe ofin irẹjẹ le wa lọwọ, kii se ofin ti Awolowo, Azikiwe ati Balewa fọwọsi la n lo lasiko yii.
Idi ree ta se duro lori sise agbeyẹwo ofin ilẹ wa nibi ta ti se agbekalẹ ilana atunto tun orilẹede yii.
Mo si ti sọ fun Buhari pe to ba jẹ pe lootọ lo nif orilẹede Naijiria, yoo gba ka se atunto orilẹede yii.
Sunday Igboho ati IPOB yoo dakẹ, bijọba ba se atunto Naijiria’
O dara ki Naijiria wa papọ bi orilẹede kan amọ a ko le wa papọ lori irẹjẹ - Adebanjo
Alagba Adebanjo tẹsiwaju pe ẹya to wa lapa ariwa nikan lo n gba awọn ipo nla nla to wa ni Naijiria.
Bakan naa lo tun koro oju si bi ijọba apapọ se n pariwo pe abẹ akoso awọn gomina ni ipese eto aabo nipinlẹ koowa wọn wa.
Amọ o ni o se ni laanu pe awọn ohun ija ti wọn yoo lo lati pese aabo naa wa lọdọ ijọba apapọ, ti ko si fun awọn ipinlẹ lati lo wọn.
O ni yoo dara ki Naijiria si wa papọ gẹgẹ bi orilẹede kan amọ ko seese ka wa papọ lori irẹjẹ.
Nigba to n sọrọ lori ominira Naijiria, Adebanjo ni kaka ko san lara iya ajẹ ni ọrọ wa, se la kan n fi ọmọ wa bi obinrin, ti ẹyẹ wa n yi lu ẹyẹ.
O ni se ni ohun gbogbo kan n buru si ni Naijiria, to si buru jai pupọ labẹ isejọba aarẹ Muhammadu Buhari.






