Ìgbé ayé Mufu Olóòṣà-oko, ọmọ ìta tó kú ikú ọlọ́ṣà

Oríṣun àwòrán, Screen shot
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
Yoruba ni arise ni arika, arika ni baba iregun, ohun ti a ba se lonii, o n bọ wa di itan lẹyinwa ọla.
Ọpọ ẹda to si ti wa saye ni orukọ wọn wa ninu iwe akọsilẹ manigbagbe, boya fun isẹ rere ti wọn se nile aye ni tabi ni idakeji rẹ.
Iru rẹ ni ti ọkunrin kan to gbajumọ nilu Ibadan laarin ọdun 1970 si1976, ti iwa to hu lasiko naa si jẹ ki orukọ rẹ wọnu iwe manigbagbe lorilẹede Naijiria.
Gbajumọ nla ni orukọ Mufu Olooṣaoko ninu itan ilu Ibadan, ti ọpọ lode oni gbọ, ti wọn si mọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ohun ti wọn mọ ọ si ki i ṣe ohun to dara pupọ, sibẹ orukọ rẹ jẹ eyi to gbajumọ ninu iwe iranti ọpọ eeyan.
Ta ni Mufu Olooṣa-oko?
Tani Mufu Olooṣa oko? Bawo ni irinajo aye rẹ ṣe jẹ? Ẹ jẹ ka gbe eyi yẹwo.
Ni adugbo Abẹbi nitosi agbegbe kan ti wọn n pe ni Ṣọọṣi Ẹlẹja, ọna tooro kan wa to lọ si agbegbe Olooṣa-oko tabi ti agekuru rẹ n jẹ Olooṣa’oko.
Gbogbo wa la mọ bayi pe ọpọ orukọ adugbo lode oni lo ti yipada diẹ nitori asunki iṣẹnupe lo ti waye lori wọn laarin ọpọ akoko.
Oloriṣa oko ni agbegbe yii, asunki iṣẹnupe lo sọ pipe rẹ di olooṣ’oko.
Nibẹ ni Mufu n gbe, orukọ nla ti n da ẹru ba ẹgbẹ rẹ ni.
Alhaji Mufu Olooṣ’oko, ẹbọra nla; ijaya ti n ba tonile talejo lẹru.
"Olugbeja mẹkunnu ni Mufu, ẹnikẹni ti wọn ba yan jẹ ladugbo, lo maa n gbe wọn nija "
Gẹgẹ ba se gbọ lẹnu awọn onpitan, agbegbe Abebi, Idikan, Oloosa oko, Beere titi de Mokola, Oja Ọba nilu Ibadan ni Mufutau gbe dagba, to si ti ṣe ìpátá.
Ni ibẹrẹ aye rẹ, onirẹlẹ ẹda ni Mufutau, ti kii si gbe oju soke wo ẹnikẹni loju, koda, ko le sọrọ ẹnu rẹ tan.
Ẹda tẹẹrẹ ti ko ni omi lara ni Mufu amọ tori adugbo to gbe dagba, ko si ẹda ti wọn jọ ja, tí Mufu ko ni fi ẹyin rẹ balẹ.
Olugbeja mẹkunnu ni Mufu, ẹnikẹni ti wọn ba yan jẹ ladugbo, tabi ti wọn gba iyawo rẹ lo maa n gbe wọn nija pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ.
Awakọ ero ni Mufutau, ilu Portharcourt si lo maa n fi ọkọ pijo 504 rẹ na titi wọ ọdun 1976, ti wahala de ba.
"Mufu na eeyan wọ Mọsalasi, Lemọmu ba sepe fun pe ko ni ṣe ẹẹmi"
A gbọ pe lasiko ti Mufu wa laye, ko si ẹni to mọ ọ bii adigunjale, amọ ọmọ líle, tọ́ọ̀gì ati janduku to n da agbo ariya ru ni.
Ko si si olorin tí yoo fẹ ṣeré nilu Ibadan, ti ko ni kọkọ juba Mufu Oloosa Oko pẹlu owo nla.
Lọdun 1975, oun ati awọn ikọ rẹ na eeyan kan wọ inu mọsalasi, nibẹ ni Lemọmu ti ṣẹ epe fun pe ko ni si laarin awọn ni iwoyi ọdun to n bọ.
Nigba to di ọdun 1976, Mufu n dari bọ lati ilu Portharcourt to n na pẹlu awọn ikọ rẹ, wọn ya sile epo kan nilu Ondo.
Wọn ba owo tuulu lọwọ osisẹ ileepo naa to n ka lọwọ, ti wọn si fi ìbon gba owo naa lọwọ rẹ.
Ọwọ ọlọpaa papa tẹ Mufu, ti adajọ si ni ki wọn lọ yẹgi fun nilu Akure lọdun 1976.
Itan wo ni igbe aye Mufu Oloos‘oko kọ wa?
Lara awọn ẹkọ ta ri kọ ninu itan igbe aye Mufu Oloosa-oko ni pe ka yago fun iwa ipata tabi ọmọ isọta nitori igbẹyin rẹ kii dara.
Ẹkọ keji ta tun ri kọ ni pe ta ba fẹ gbeja eeyan, a ko nilo lati huwa jagidijagan.
A tun ri gbọ pe iwa rere ni ẹsọ eeyan, orukọ rere si san ju wura ati fadaka lọ, nitori naa, ka maa fi ẹ̀ṣọ̀ lo ile aye wa.
Itan Mufu Oloosa-oko tun kọ wa lati ni ibẹru pupọ fun Ọlọrun ọba, nitori kii se ẹgbẹ ẹnikẹni.
Bakan naa, a tun kọ ẹkọ pe o yẹ ka maa yago fun ohunkohun to le mu ki a gba epe lẹnu agbalagba tabi eeyan Ọlọrun.
Nipari, itan aye Mufu Oloos‘oko kọ wa lati mase maa mu ohunkohun ti kii ba se tipa boya lọna ẹrọ ni tabi pẹlu tipa tipa.

















