Ẹni tó wu Aláàfin pé kó jẹ ààrẹ Nàíjíríà rèé - Akeem Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Screenshot
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Aláàfin ìlú Oyo tó dolóògbé, Oba Lamidi Adeyemi Kẹta, Akeem Adeyemi ti ní ohun tó wu bàbá òun kó tó dágbére fáyé ni pe kí Asiwaju Bola Tinubu di Ààrẹ Nàìjíríà.
Adeyemi tó ń ṣojú ẹkùn idibo Afijio/Atiba, ìlà oòrùn Oyo ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ló sọ èyí níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí wọ́n ṣe ní ìrántí olóògbé naa lópin ọ̀sẹ̀.
Ní gbọ̀ngàn ayẹyẹ tuntun tí wọ́n kọ́ sí Ode Aremo ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ìlú Oyo ni ayẹyẹ náà ti wáyé.
Tinubu ti ṣe ohun mèremère sí ìdàgbàsókè Nàìjíríà - Akeem Adeyemi
Adeyemi wá rọ àwọn ọ̀dọ́ láti ṣàtìlẹyìn fún Tinubu tó jẹ́ olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.
Ó fi kun pé Tinubu ti ṣe ohun mèremère sí ìdàgbàsókè Nàìjíríà, tó sì pàrọwà sáwọn ọ̀dọ́ láti ní àfojúsùn kí wọ́n dì ò fún ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wọn dọ́kan.
Bákan náà ló dúpẹ́ fún Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima fún àtìlẹyìn wọn tó sì ní ríri pé wọ́n dé ipò Ààrẹ jẹ àwọn lógún.
Adeyemi tẹ̀síwájú pé láti ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà ni àwọn ṣe kó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ọ̀dọ́ jọ, tí wọ́n sì ṣe ìkúnpá owó fún wọn láti máa fi polongo Tinubu.
Kò dín ní 1,500 ènìyàn tí Adeyemi ṣe ìkúnpá owó fún, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé gbọ̀ngán ẹ̀rọ Kọ̀ḿpútà, kọ̀ǹgadẹ̀rọ, ẹ̀rọ amúnáwá àti ètò ìlera ọ̀fẹ́ fún àwọn ènìyàn.
"Awọn ohun eelo ta pin la fẹ fi se ọjọ ibi Alaafin ka lo wa laye"
Akeem Adeyemi ní gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni òun ṣe láti fi ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí bàbá òun tí kò bá pé ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lókè èèpẹ̀ ká ní pé ó wà láyé.
Bákan náà ló ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rẹ́ẹ̀rin tí òun ń ṣojú ni àwọn pín gbogbo àwọn nǹkan náà sí.
Ó sọ síwájú pé ibi gbọ̀ngán tí àwọn ti ń ṣayẹyẹ náà ní Òde Aremo jẹ́ ibi tí àwọn ènìyàn máa ń dá ilẹ̀ sí kí òun tó sọ ibẹ̀ di gbọ̀ngán èyí tí yóò wúlò fún onírúurú ayẹyẹ.
Lára àwọn tó péjú síbi ayẹyẹ náà ni alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Oyo, Isaac Omodewu, olùdíje sípò gómìnà Oyo lẹ́gbẹ́ APC, Sẹ́nétọ̀ Teslin Folarin, àwọn lọ́balọ́ba àti àwọn olorì Ọba Lamidi tó di olóògbé.
Alaafin Adeyemi ṣe ọjọ́ ìbí àkọ́kọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn olorì mú ìdárò bọnu
"Alaafin ní ká wọ aṣọ funfun lọ́jọ́ ìbí rẹ̀ tó kọjá, à ṣé ó ti mọ̀ pé óun kò ní pẹ́ lọ ni"

Oríṣun àwòrán, alaafin oba adeyemi iii
Kii ṣe iroyin mọ pe nigba aye rẹ, alaafin to gbesẹ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta fẹ ọpọlọpọ obinrin nigba aye rẹ.
Ọkọọkan awọn olori alaafin Adeyẹmi wọnyii ni wọn kanlu ori ayelujara lati ki ọkọ wọn ku ayẹyẹ ọjọ ibi, bi o tilẹ jẹ wi pe Ọba alaye naa ti di ara ilẹ.
Ọjọ karundinlogun oṣu kẹwaa ọdun 1930 ni wọn bi Alaafia Adeyẹmi kẹta ki o to waja gẹgẹbi Alaafin Ọyọ ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun 2022.
Gbogbo awọn iyawo rẹ ni wọn bọ soju opo Instagram wọn lati ki kabiyesi naa, to yẹ ko ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹrinlelọgọrin rẹ, ka ni ko tii jade laye ni.
Idaro olori ọkọọkan nipa Alaafin loju opo Instagram wọn niyi:
Ọkọ mi, ṣe o ti mọ tẹlẹ pe akara oyinbo ikẹyin to o ba wa ge niyẹn ni - Olori Moji
Olori Moji ki ọkọ rẹ bẹẹ ni o kọ akọsilẹ bi oun ayun rẹ ṣe n yun oun.
“O sọ fun gbogbo wa pe aṣọ funfun ni ka wọ lọjọ ibi rẹ to kọja, ṣe o ti mọ pe ọjọ rẹ nibi ko pẹ mọ ni?
Ọkọ mi, ṣe o ti mọ tẹlẹ pe akara oyinbo ikẹyin to o ba wa ge niyẹn ni?
Ayun rẹ n yun mi ọba mi. Ẹ ku ọdun ọjọ ibi kẹrinlelọgọrin, Kabiyesi iku baba yeye, ọmọ Ibironkẹ.
Sun re o.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Iranṣẹ nla ti ko lafiwe ni ọrun tẹwọ gba nigba to ti Alaafin papoda - Olori Mẹmunat Omowunmi
Ninu ọrọ ikini tirẹ, olori Memunat kọ soju opo instagram tirẹ naa pe:
Mẹmunat ki ọkọ rẹ, ọmọ iya rẹ Ibironkẹ, to si sọ pe ẹbun nla ni Alaafin Adeyẹmi kẹta jẹ fun gbogbo agbaye lati ọjọ ti wọn ti bi i.
O fi kun un pe iranṣẹ nla ti ko lafiwe ni ọrun tẹwọ gba nigba to fi papoda.
“Titi lae ni n o maa ṣafẹri rẹ lọkan mi. (ATANDA ỌMỌ IBIRONKẸ).
Mo fi anfaani yii gbadura pe ki Allah gbe ọ ka apa ọtun rẹ, ko si fi ọ si ipa awọn ti a fi mọna.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Mo n ṣafẹri rẹ aye mi, ṣugbọn mo mọ pe o ko ni fẹran lati ri omije loju mi - Olori Ọmọbọlanle
Ninu ọrọ ikini ku ọdun tirẹ, olori Ọmọbọlanle ṣe afihan bi Alaafin kii ṣe fẹ ri omije loju rẹ ninu ọrọ to kọ.
“Ku ọjọ ibi ọkọ mi. O lee ma si lẹgbẹ mi nibi lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Amọ jọwọ mọ wi pe gbogbo igba lo n wa ninu ọkan mi.
Mo n ṣafẹri rẹ aye mi, ṣugbọn mo mọ pe o ko ni fẹran lati ri omije loju mi.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Bi igba ti wọn ba ju biriki lu eeyan, ni iku alaafin ri fun mi - Current Alhaja
Ninu ọrọ tirẹ, olori Afolashade iya mẹta, ti awọn eeyan mọ si Current Alhaja lori ayelujara kọ loju opo tirẹ pe ọjọ ibi akọkọ ti kabiyesi naa yoo ṣe ,ti awọn ko ni rii soju ri bakan lara oun.
Current Alhaja sọ pe bi igba ti wọn ba ju biriki lu eeyan ni iku alaafin ri fun oun ṣugbọn oun ti tẹwọ gba a gẹgẹ bi ifẹ Eleduwa.
“Ayẹyẹ ọjọ ibi akọkọ lai si ẹ nibi, ọkọ mi. Ẹ ku ọdun.
Gbogbo ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa lọjọ rẹ, Atanda...ọmọ Ibironkẹ Morondiya.
Ọmọ Adeniran, iku rẹ da bi igba ti wọn ba ju ẹru biriki lu mi ni ṣugbọn ki ni mo le ṣe.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3















