Wo kókó àwọn ètò tí Bola Tinubu fẹ́ ṣe tó bá di ààrẹ

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialasiwajubat

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Asiwaju Bola Tinubu, ti ṣàgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe ní orílẹ̀ èdè tó bá di Ààrẹ lọ́dún tó ń bọ̀.

Níwájú àpapọ̀ ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà Árèwá ni Tinubu ti ṣàgbékalẹ̀ èròńgbà rẹ̀ ọ̀hún.

Tinubu ṣèlérí pé tí òun bá di Ààrẹ Nàìjíríà, òun yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé ìṣọ̀kan Nàìjíríà dúró ṣinṣin.

Bákan náà ló ní àwọn ètò tí yóò mu Nàìjíríà gòkè àgbà ni ìjọba òun ma dágbálé.

Ó fi kun pé òun máa sọ ẹkùn àríwá Nàìjíríà di ibi tí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ yóò ti le máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ọ̀gbìn.

Àwọn ọmọdé tí kò lọ sílé ẹ̀kọ́ ni àwọn máa ṣètò láti fi wọ́n sẹ́nu ẹ̀kọ́ṣẹ́.

Ó fi kun pé ṣíṣe àmúlò àwọn ohun àlùmọ́nì àti ètò ọ̀gbìn ni èròńgbà àwọn láti fi mú kí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà bọ̀ sípò.

"A ma ṣàgbéyẹ̀wò ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti fi yanjú ìṣòro ààbò"

Bákan náà, Tinubu ní gbogbo àwọn iṣẹ́ takuntakun tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe kù, ní òun yóò tẹ̀síwájú pẹ̀lú wọn.

O sọ pe ni pàápàá ní ẹ̀ka pípèsè àwọn ohun amáyédẹrùn.

Ó ní ipa òun ní ìpínlẹ̀ Eko gẹ́gẹ́ bí gómìnà ti jẹ́ ẹ̀rí máa jẹ́ mi nìṣó pé òun yóò ṣàgbékalẹ̀ àwọn ètò tí yóò mú kí àìsí ètò ààbò ni àríwá àtàwọn ẹkùn mìíràn ní Nàìjíríà di ohun ìgbàgbé.

Ó ní gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àkọ́kọ́ fún ẹni tó bá jẹ́ Ààrẹ orílẹ̀ èdè, ètò ààbò ni ohun àkọ́kọ́ láti gbájúmọ́.

Asiwaju ní gbogbo ohun tó bá wà ní ìkáwọ́ ìjọba láti mú kí àwọn ènìyàn sun láìsí bẹ̀rù ni òun yóò ṣe.

Ó sọ wí pé ìpè fún ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ àti àtúntò Nàìjíríà ni òun mọ́ àti pé gbogbo àwọn nǹkan yìí ni òun yóò wá ọ̀nà láti wá ojútùú lọ́nà tí ó bá òfin mu.

Tinubu sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ tí Nàìjíríà ní àmọ́ tí àwọn olórí wa kò ì tíì ṣàmúlò pátá, ni òun yóò lò láti fi mú ìlọsíwájú bá Nàìjíríà.

Níṣe ló yẹ kí Atiku jan ìyànsípò mi lóǹtẹ̀, kò yẹ kó gbégbá ìbò

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ṣàtìlẹyìn fún olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar nígbà tó ń wápò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú ACN lọ́dún 2007, Tinubu kò yẹ kí Atiku ṣe iyèméjì kó tó gbárùkù ti òun lórí ìpinnu òun láti díje dupò Ààrẹ.

Ó ní ń ṣe ló yẹ kí Atiku jan ìyànsípò òun lóǹtẹ̀ nítorí àsìkò ẹ̀san ló dé yìí.

Ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn Àríwá tí Tinubu bá sọ̀rọ̀ ló jẹ́ àpapọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Arewa Consultative Forum, Northern Elders Forum, Sir Ahmadu Bello Memorial Foundation, Jamiyyar Màtá Arewa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Tinubu ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò rẹ̀ wọ̀nyí lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí Atiku náà ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ náà.

Ó wá kan sárá sí àwọn adarí Nàìjíríà láyé àtijọ́ tí wọ́n fi àyè gba ara wọn láìfi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe èyí tó ní ó hàn nínú orin orílẹ̀ èdè tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe àgbékalẹ̀ fún orílẹ̀ èdè yìí.

Tinubu ni Ààrẹ tí Nàìjíríà nílò láti gòkè àgbà - El-Rufai, Lalong

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ wí pé olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni àwọn ènìyàn àríwá máa dìbò fún láti di Ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún tó ń bọ̀.

El-Rufai ní gbogbo àwọn gómìnà APC ló fẹnukò pé kí ipò Ààrẹ lọ sí ẹkùn gúúsù kí ìṣọ̀kan àti dọ́gba-n-dọ́gba lè wáyé.

Ó ní tí àwọn àgbààgbà Àríwá bíi Sir Ahmadu Bello tí ń ṣe Sardauna ìlú Sokoto bá wà láyé, tapá titan rẹ̀ ni yóò fi ṣàtìlẹyìn pé kí ipò agbára padà sí ẹkùn gúúsù.

Adarí àpapọ̀ ìpolongo Tinubu tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau, Simon Lalong ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa gòkè àgbà lábẹ́ ìdarí Tinubu àti pé tẹrútọmọ ni yóò ni àǹfàní láti ṣe tirẹ̀.

Lalong fi kun pé ìṣọ̀kan Nàìjíríà dájú lábẹ́ ìdarí Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Máṣe jápa ní 2023, èmi ló máa borí, Tinubu rawọ́ ẹ̀bẹ̀

Tinubu pẹlu El-Rufai

Oríṣun àwòrán, nasir ahmad el-rufai

Oludije aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC feto idibo 2023, Aṣiwaju Ahmed Tinubu ti fi idaniloju han pe oun ni yoo bori ibo aarẹ lọdun to n bọ.

Aṣiwaju Bola Tinubu ninu ọrọ to sọ nibi ipade apero ati idokoowo ipinlẹ Kaduna, to waye nilu Kaduna, lo ti fọwọ gbaya bẹẹ.

O tun kan sara si gomina ipinlẹ naa, Mallam Nasir El-Rufai pẹlu afikun pe awọn alarojinlẹ bii rẹ loun yoo nilo ni iṣejọba oun.

Tinubu wa ke si El_Rufai lati ṣeleri niwaju gbogbo eeyan pe oun ko ni sa roke okun lati kẹkọ gboye kun oye.

O ni ohun ti yoo leke ilepa iṣejọba oun, bi oun ba wọle ni “idapada alaafia ati abo kaakiri ẹkun gbogbo.

"O da mi loju pe labẹ idari mi, ijọba yoo mu ọrọ gbigbogun ti igbesunmọmi lọkunkundun gẹgẹ bi ara eto ologun.

A o dijọ ja ija yi papọ ni.”

Oludije ipo aarẹ Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC naa wa rawọ ẹbẹ si El-Rufai lati duro si orilẹede Naijiria, lẹyin to ba pari saa iṣejọba rẹ lọdun 2023 lati ba oun ṣiṣẹ pọ.

Ninu esi rẹ, gomina Nasir El-Rufai ni oun “ṣeleri lati duro bi o tilẹ jẹ diẹ diẹ ni.”