Wo ẹkùn Tigray níbi tí ebi ti ń pa ọmọdé, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì di alágbe

Àkọlé fídíò, Africa Eye - Ethiopia
Wo ẹkùn Tigray níbi tí ebi ti ń pa ọmọdé, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì di alágbe
Ọmọde to ku ni ẹkun Tigray

Ẹka ikọ iwadii ọtẹlẹmuyẹ labẹ ileesẹ iroyin BBC, Africa Eye se akanse akojọpọ iroyin iwadi yii nipa bi ebi se n pa awọn ọmọde lẹkun Tigray lorilẹede Somalia.

Bakan naa ni ẹgbẹlẹgbẹ awọn agbaagba ti di alagbe to n tọrọ bara nitori ogun to n waye lẹkun naa.

Lati osu Kẹfa ọdun 2021 nijọba apapọ orilẹede Ethiopia ti gbegi dina ẹkun Tigray nibi tawọn ikọ ologun ọlọtẹ orilẹede naa, TPLF, tẹdo si.

Lati igba naa si ni igbe aye ti buru si fawọn eeyan agbegbe naa, ti ogun naa si ti mu ẹmi ẹgbẹlẹgbẹ eeyan lọ.

Ko si ibikibi ni agbaye nibi ti idunkooko ti n ba ilera awọn eeyan finra bii ti agbegbe Tigray yii - WHO

Igbesẹ bi ijọba se gbegi dina lẹkun Tigray yii lo mu ko nira pupọ fun awọn ohun eelo ojoojumọ, to fi mọ ounjẹ ati oogun, lati wọle si ẹkun naa.

Ojoojumọ si ni ebi n dunkooko iku mọ ọkẹ aimọye miliọnu eeyan to wa lẹkun naa.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus tii se onisegun oyinbo labẹ ajọ eleto ilera lagbaye, WHO, isẹlẹ to n waye lẹkun Tigray naa buru jai.

“Ko si ibikibi ni agbaye nibi ti idunkooko ti n ba ilera awọn eeyan bii ti agbegbe Tigray yii.”

"A ri bi awọn ọmọde se n ku nitori ebi lẹkun Tigray"

BBC Africa Eye wa se abẹwo si ẹkun Tigray lati tọpinpin ipo to buru jai tawọn eeyan agbegbe naa wa.

Ninu iroyin yii, a ri bi awọn ọmọde se n ku nitori ebi, ti ọpọ eeyan lẹkun naa si di alagbe loju popo.