Owó tí APC ná sí ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Osun lá gbà padà – PDP

Ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Osun ti sọ pe eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ naa lopin ọṣe ko ba ofin mu, idi ree ti wọn fi kọ lati kopa ninu rẹ.
Alaga ẹgbẹ ọhun, Akindele Adekunle ṣalaye fun BBC Yoruba pe gbogbo owo ti ijọba ipinlẹ Osun na lori eto idibo naa ni ijọba PDP maa gba pada ti awọn ba de ori alefa.
O ni “Ẹgbẹ PDP ko lọwọ si eto idibo yẹn, a dẹ ti sọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wa ki wọn ma kopa ninu eto idibo ọhun, wọn si gbọ ohun ti a sọ, wọn ko jade.”
Adekunle sọ pe asiko ti ijọba Gboyega Oyetola kede eto dibo naa ati akoko ti eto idibo naa waye sunmọ ara wọn pupọ, eyii to lodi si ofin eto idibo ni Naijiria.
O ni igbagbọ ohun ni pe ijọba APC mọọmọ fẹ fi idibo naa da wahala silẹ fun ijọba to n bọ ni, ati pe wọn mọọ fẹ fi kowo ilu sapo ni.
Gbogbo nkan ti wọn ba ṣe to lodi si ofin ni a maa yipada - PDP

"APC fẹ da wahala silẹ fun ijba PDp to n bọ ni plu ibo ijọba ibilẹ to se"
Adekunle tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ṣe ayipada gbogbo ohun ti ijọba to wa lode yii ba ṣe, eyii ti ko ba ofin mu.
O ni “Nigba ti eeyan ba ṣe eto idibo to lodi si ofin, eyii ti ẹjọ rẹ ṣi wa nile ẹjọ, o fẹ mọọmọ fi da wahala silẹ fun ijọba to n bọ ni.”
“A dẹ ti sọ lọpọ igba pe, ti ijọba yii ba de ori alefa lagbara Ọlọrun lọjọ kẹtadinlọgbọn, gbogbo nnkan ti wọn ba ṣe to ba lodi si ofin ni a maa ṣayipada rẹ.”
“Gbogbo owo ti wọn na lọna to ba ofin mu fun eto idibo naa ni a maa gba pada lọwọ wọn, o pẹ ti a ti n sọ eleyii, mo dẹ tun n sọ bayii.”
“Ofin to rọ mọ eto idibo ti sọ pe ijọba gbọdọ kede eto idibo naa bii ọdun kan ṣaaju ọjọ idibo ọhun ki awọn ẹgbẹ to ku le murasilẹ, idi ree ti a ṣe lọ sile ẹjọ.”
O ni ko bojumu to bi ẹgbẹ APC nikan ṣe kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ naa nigba to jẹ pe nnkan bii ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun lo wa ni ipinlẹ Osun.

Ile ẹjọ sọ lo fun wa laṣẹ lati ṣe eto idibo naa – OSIEC
Ẹwẹ, ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun, OSIEC ti fesi pe eto idibo naa to waye kii ṣe ẹbi APC, amọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ku ti wọn kọ lati lọwọ ninu rẹ ni.
Alaga ajọ naa, Oladunjoye Oladitan ni ti ijọba ko ba dara, ẹbi awọn to lẹtọ lati yan ijọba amọ ti wọn kọ ni kiiṣe ẹbi ijọba ti wọ ni ko dara.
Gẹgẹ bi ohun to sọ, ajọ eleto idibo OSIEC ke si gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ Osun ki wọn to ṣe eto idibo naa, amọ awọn kan lo mọọmọ sọ pe awọn ko ni lọwọ ninu rẹ.
O ni OSIEC ko lẹbi kankan ninu bi ọrọ naa ṣe jẹ nitori ile ẹjọ fun awọn laṣẹ lati tẹsiwaju ninu eto idibo naa bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu kan ko faramọ.






