Èèyàn 150 kú láàrin ọjọ́ méjì torí ìjà láàrin Hausa àtawọn ẹ̀yà míì

Ẹya Hausa n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, AFP

Eeyan aadọjọ lo ti jade laye laarin ọjọ meji tori ija nla to n waye laarin awọn Hausa atawọn ẹya miran to wa nipinlẹ Blue Nile lorilẹede Sudan.

Rogbodiyan naa si lo tii buru julọ ninu itan aawọ ẹlẹyamẹya to tii waye ri lorilẹede Sudan lati bii osu meji sẹyin.

Ọsẹ to kọja ni aawọ naa bẹrẹ eyi to da lori ọrọ ilẹ to n waye laarin awọn Hausa atawọn ẹya miran nibi ti eeyan mejila ti kọkọ ku.

Nibayi, ijọba ti kede pe ki awọn eeyan fidi mọle wọn, lọna ati bomi pa aawọ naa.

O seese ki rogbodiyan naa fẹju si, ti ko si le si alaafia ọlọjọ pipẹ lagbegbe naa - UN

Amọ ajọ isọkan orilẹede agbaye, United Nations ti kede pe “O seese ki rogbodiyan naa fẹju si ni agbegbe Lagawa atawọn agbegbe miran to wa nipinlẹ Blue Nile.

Ko le si alaafia ọlọjọ pipẹ lawọn agbegbe naa ti ijọba to duro re ko ba si eyi ti yoo mu ipese awọn tawọn eeyan n poungbẹ rẹ lọkunkundun.”

Atẹjade kan ti ajọ UN fisita lori laasigbo yii lati ọọfisi rẹ to wa fun idapada alaafia ni lara awọn ohun tawọn eeyan n fẹ naa ni eto aabo to peye, ki ijọba si mọ ohun to n fa ija naa.

Orilẹede Sudan lo ti n jiya nitori laasigbo oselu ati rogbodiyan lati igba ti iditẹ gbajọ ti waye lorilẹede naa lọdun 2021.

Ọ̀dá òjò ń ṣoro ní Somalia, wo bí ọmọ ọdún méjì, tí kò tobi ju ọmọ tuntun lọ, ṣe bá ebi kú

Awọn ọmọ to n saisan ati iya wọn

Ti ẹ ba wo ọmọ ọdun meji yii, Abdiwali Abdi, iwọn rẹ tii se kilo mẹrin ati aabọ ko ju iwọn ọmọ tuntun lọ, amọ o ni okun lati kerora ranpẹ.

Iya Abdiwali Abdi, Hawa gbe wa sile iwosan, to si joko ti ọmọ rẹ, bẹẹ lo tun n fun ọmọ osu meji miran ni ọmu, erongba rẹ si ni pe ko pada sinu agọ wọn ni abule wọn.

Nile iwosan naa, ọmọde mẹtadinlogun lo wa lori ibusun, ti gbogbo wọn si n ba airi ounjẹ asaraloore jẹ wọ ijakadi.

Bẹẹ ni ọpọ aisan to so mọ ebi lo n ba awọn ọmọ de naa finra eyi to wọpọ ni ẹkun guusu orilẹede Somalia, ti ọgbẹlẹ ogoji ọdun ti n ba finra.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Fatuma Mohammed, tii se olutọju alaisan ati alakoso ile iwosan naa to wa lati Kenya salaye pe itọju awọn ọmọde naa ti n mu iwuri wa.

Amọ Hawa, tii se iyalọmọ ni ko si ounjẹ ti awọn fẹ fun awọn ọmọde naa jẹ bi o tilẹ jẹ pe awọn aladugbo n seranwọ fun awọn.

Hawa lo ti n fo ọmọ rẹ lori ibusun to n joro si fun aimọye ọsẹ, ti arun iba ati igbẹ gbuuru si n ba finra, ko to di pe wọn gbe wa sile iwosan.

Amọ o se ni laanu pe wọn du ẹmi Abdiwali, ọmọ ọdun meji naa sugbọn nigba ti yoo fi di aago mẹwa aarọ, ọmọ naa gbe ẹmi mi lẹyin ọjọ keji to dele iwosan

Ile iwosan naa to wa ni abule Dollow, eyi to kun fun eruku lẹkun guusu Somalia nijọba ilẹ UK n se onigbọwọ rẹ lati seranwọ ipese ilera fawọn ọmọde.

Nibayi, ọdun karun ree ti ojo ko ni rọ nilẹ Somalia, ti iye awọn eeyan to n saisan si n pọ si lojoojumọ nile iwosan naa.

Abdiwali Abdi

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn mọlẹbi bii ti Hawa lo korajọ si abule naa lati wa abbo ati ounjẹ, ti ẹgbẹlẹgbẹ ẹran ọsin wọn si ti ku.

Abdulkadir Mohammed lati igbimọ alamojuto awọn to n se atipo lati Norwe sọ fun BBC pe “ẹmi aimọye ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun eeyan lo wa ninu ewu.

O ni ọpọ eeyan si n ku, ti a ko si ni ohunkohun lati seranwọ fun wọn.”