Ọwọ́ tẹ olóyún, ìyálọ́mọ àtàwọn afurasí míì tó gbé òògùn olóró

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun oloro ni Naijiria, NDLEA ti salaye bi ọwọ awọn ṣe tẹ awọn to n gbe oogun oloro kaakiri orilẹede yii.

Ninu ọrọ rẹ, awọn ti ọwọ tẹ ni alaboyun kan, obinrin to n tọ ọmọ jojolo lọwọ, to fi mọ ọmọ ileẹkọ fasiti to wa ni ipele keji.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ NDLEA, Femi Babafemi fi lede, ni wọn ti salaye bi ọwọ se tẹ eeyan mejidinlọgbọn pẹlu oogun oloro Cannabis to le ni ẹgbẹrun lọna mẹsan kilo ati oogun onihoro to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọjọ.

Ọwọ tẹ akẹkọọ fasiti to gbe oogun oloro pamọ sinu ikoko turari

Ajọ naa ni asiko ti awọn n ṣe ofintoto ni ipinlẹ Yobe, Ondo, Edo, Rivers, Akwa Ibom, Imo, Jigawa, Kogi, Adamawa, Kaduna, Kwara, Lagos ati Abuja ni wọn ri awọn afurasi oloogun oloro naa mu.

‘’Ni ilu Yobe ni a ti ri eroja igbo to le ni mejidinlaadọta ni Buni Yadi ni agbegbe Potiskum.’’

‘’Bakan naa ni wọn ri awọn afurasi meji mu, to fi mọ oloyun kan to n gbe oogun oloro.’’

‘’O kere tan, apo igbo to fẹrẹ to ọgọrun kilo ni wọn ri gba ni agbegbe Ogbẹṣẹ nipinlẹ Ondo.’’

Bakan naa lo fikun un pe ọmọ ileẹkọ fasiti to wa ni ipele keji ni ileẹkọ Open University ni ọwọ tẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed ni ilu Eko pẹlu oogun oloro.

Wọn ni akẹkọọ yii ni wọn ba oogun oloro Tramadol to le ni ẹẹdẹgbẹta giraamu to fi pamọ sinu turari ti wọn n gbe lọ si Dubai.