Abiodun Oyebanji di gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Oríṣun àwòrán, OTHERS
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
Arakunrin Abiodun Oyebanji ni wọn ti bura fun gẹgẹ bi gomina tuntun ti ipinlẹ Ekiti.
Olotu eto idajo nipinle Ekiti, Adajo Oyewole Adeyeye lo bura wọle fun ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹrindinlogun, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Oyebanji ni o gba ipo ni ọwọ gomina tẹlẹ, Kayode Fayemi to jẹ Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorilẹede Naijiria.
Fayose, Gomina Akeredolu, Oyetola wa nibi iburawọle gomina tuntun nipinlẹ Ekiti
Lasiko ti wọn n bura wọle fun lo ṣeleri lati sin awọn araalu de ibi ti ẹru ko fi ni ba wọn.
Bakan naa lo ṣeleri lati di ipo gomina naa mu lai wẹyin, ti oun yoo si se ohun to tọ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ekiti.
Lara awọn to pejọ si ibi iburawọle naa ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ati awọn eekan lawujọ.
Bí eré, ọdún mẹ́rin pé, Kayode Fayemi fipò gómìnà Ekiti sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, ekiti state government
Gomina to n fipo silẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti sọ pe imuṣẹ awọn ileri ti oun ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Ekiti ni oun fi ọdun mẹrin toun pada wa lo ni iṣejọba ipinlẹ naa ṣe.
O ni awọn ohun ti oun dojule laarin ọdun mẹrin naa ni dida ipinlẹ Ekiti pada si oju ọna tootọ ati dida iyi ati ọla rẹ pada.
O ni awọn igbesẹ naa ni yoo mu oun duro gẹgẹ bi awokọṣe laarin awọn ipinlẹ yoku lorilẹede Naijiria.
"Mo fi ẹmi mi ati isuna perete sin awọn eeyan Ekiti laiyẹsẹ"
Ọmọwe Kayọde Fayẹmi sọ eyi di mimọ nibi ayẹyẹ idagbere ti wọn ṣe fun un gẹgẹ bi ara awọn ayẹyẹ to n sami ọjọ to gbẹyin fun un gẹgẹ bi gomina ni ipinlẹ naa.
Ọmọwe Fayẹmi tun sọ pe gbogbo ẹmi oun loun fi sin ipinlẹ naa laiyẹsẹ pẹlu iwọnba perete iṣuna ati ọrọ aje to dagun.
Fayemi ni bi o tilẹ jẹ pe, asiko iṣejọba oun tun ṣe kongẹ akoko ti ajakalẹ arun COVID-19 kọlu agbaye, ninu eyi ti orilẹede Naijiria ati ipinlẹ Ekiti ko gbẹyin.
Nibi Ayẹyẹ idagbere naa, eyi to sọkutu wọwọ nilu Ado Ekiti, ni wọn ti fi ọkọ ologun gbe Gomina Fayẹmi ati iyawo rẹ Bisi Fayẹmi jade.
Bakan naa ni igbakeji gomina, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi naa ba wọn jade kuro pẹlu ọkọ naa niwaju ọfiisi gomina ipinlẹ Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
"Ekiti ti gbe igbesẹ alọye bi igi eti odo labẹ akoso gbogbo awọn to ti ṣiṣẹ sin ipinlẹ naa"
Orin, ilu ati ijo latọdọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, ni wọn fi sin Fayemi sọna.
Awọn ọmọ igbimọ iṣejọba rẹ atawọn akọwe agba nileeṣẹ ijọba pẹlu awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC ati Kayọde Fayẹmi, si ni wn n fi idunnu han lati dagbere fun Fayemi.
Fayẹmi wa dupẹ lọwọ awọn aṣiwaju ipinlẹ Ekiti, awọn lọbalọba, atawọn to di ipo naa mu ṣaaju rẹ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn to ba a ṣiṣẹ lasiko iṣejọba rẹ.
O ni ipinlẹ Ekiti ti gbe igbesẹ alọye bi igi eti odo labẹ akoso gbogbo awọn to ti ṣiṣẹ sin ipinlẹ naa.
O ni bẹrẹ lati ijọba ologun akọkọ to kọkọ dari rẹ titi kan iṣejọba oun.

Oríṣun àwòrán, ekiti state government
Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti fun ore ọfẹ to ni wọn fun oun lati sin wọn to fi di pe oun naa wa goke di alaga igbimọ awọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria.
Lara awọn iṣẹ ilu to ṣe gbẹyin ni ṣiṣi papakọ ofurufu tuntun nilu Ado Ekiti ati bibu ọwọ lu iwe idasilẹ awọn ẹlẹwọn kan ni ọgba ẹwọn to wa nilu Ado Ekiti.















