Àánú ìjọba tó ń bọ̀ ń ṣe mí, torí nǹkan yóò nira – Sanusi
À ń ṣe ayẹyẹ, à sì ń rẹ́rìn-ín, tá à bá yanjú wàhálà tó wà nílẹ̀, àwọn ọmọ wa yóò gbé wa ṣépè - Sanusi

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina tẹlẹ fun banki apapọ Naijiria, Sanusi Lamido Sanusi, ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria ati Aarẹ tuntun ti wọn yoo dibo yan lọdun to n bọ, gbọdọ gbe awọn igbesẹ to lagbara ki Naijiria le pada bọ sipo.
Sanusi lo sọ ọrọ naa nibi eto kan to waye niluu Kaduna.
Emir nigba kan ri naa sọ pe ijọba yoo nilo lati fi kun owo epo bẹntiro ati owo ina ijọba, eyii ti ko ni rọrun fun awọn araalu.
Amọ o ni ijọba gbọdọ kọkọ jẹ ki awọn araalu mọ ohun ti yoo lo awọn owo naa fun, ko to kede afikun owo epo pẹtiroolu.
O ni wọn gbọdọ wa firi idi koko iranwọ owo epo, ki awọn araalu le mọ ohun ti ijọba n fi owo naa ṣe.
108% owo ti ijọba n pa wọle, lo fi n san gbese
Sanusi ni “Ọrọ wa ti kọja oju ẹ, a si ni lati pa alafo to wa laarin iye ti a n ṣẹ owo wa si owo ilẹ okeere.”
“Lọwọ yii, ida mejidinlaadọfa (108%) owo ti a n pa wọle, ni a fi n san gbese.”
“Awọn orilẹ-ede kan ma n kerora ni ti wọn ba n fi ida ọgbọn ninu owo wọn san gbese, amọ awa ni tiwa, ida ọgọrun ni a fi n san gbese.”
“Bẹẹ, a si n rẹrin, a n ṣe ayẹyẹ. Ti a ko ba yanju ọrọ to wa nilẹ yii, awọn ọmọ wa yoo gbe wa ṣepe ti akoko ba to.”
Sanusi sọ pe ijọba gbọdọ mọ pe NNPC ti kuro ni ileeṣẹ ti wọn le maa fi pa owo wọle.
O ni o si yẹ ki wọn tu NNPC naa ka ki wọn le ṣe amulo ofin ‘Petroleum Industry Bill.’
O pari ọrọ rẹ pe awọn oloṣelu gbọdọ jẹ ki awọn araalu mọ pe nnkan ko ni rọgbọ, ti ijọba ba fẹ gbe igbesẹ ti yoo mu nnkan pada bọ sipo ni Naijiria.















