Ọwọ Ọlọ́pàá tẹ 'IVD, ọkọ ìyàwó tó dáná sun ara rẹ̀, lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bí ìyàwó kígbe pé ó ti sálọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, IVD/Instagram

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe ọwọ ti tẹ Ikechukwu Ogbonna, ti ọpọ mọ si ‘IVD’ lori ikú iyawo rẹ, iyẹn Abimbola Martins.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti awọn mọlẹbi Abimbola sọ pe ọkọ rẹ lọwọ ninu iku rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin lo kede bẹẹ lori opo Twitter rẹ.

Hundeyin ni wọn ti gbe Ikechukwu Ogbonna, ẹni ọdun mẹtadinlogoji lọ si ẹka to ṣe iwadi iwa ọdaranto wa ni Panti, Yaba niluu Eko.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii ni wahala bẹ silẹ nile tọkọtaya ọhun to wa ni Megamound Estate, lagbegbe Lekki, niluu Eko.

Ọkan lara awọn aladugbo tọkọ-taya naa, ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ pe Bimbo lo koju ọkọ rẹ Ogbonna.

O ni ọkunrin naa ti maa n lu aya rẹ ni ilu bara fun ọjọ pipẹ lori awọn ariyanjiyan to maa n waye laarin tọkọtaya.

Ikede ileesẹ ọlọpaa naa lo waye lẹyin ti mọlẹbi Abimbola Martins pariwo sita pe ọkọ ọmọ wọn, iyẹn Ikechukwu Ogbonna, ti fi ẹsẹ fẹ kuro lorilẹede Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nigba ti wọn n salaye bi isẹlẹ to gbẹmi ọmọ wọn naa se waye ninu atẹjade kan ti mọlẹbi Abimbola fi sita, wọn ni awọn gbagbọ pe Ogbonna lo pa ọmọ awọn.

Wọn wa se apejuwe isẹlẹ naa bii ohun ibanujẹ fun awọn obi, mọlẹbi, papa julọ awọn ọmọ.

“Isẹlẹ yii jẹ ohun manigbagbe ti ko yẹ ki ẹnikẹni la kọja. Ọpọ igba ni a gbinyanju lati gba ọmọ wa kuro lọwọ ọkọ rẹ to wa pada gba ẹmi rẹ.

“Abimbola jẹ ẹni to ni ẹran ifẹ lara, to si bọwọ fun ọkọ, to tun wa jẹ iya rere fun awọn ọmọ, to si gbinyanju lati pe se igbesiaye rere fun wọn."

Mọlẹbi Martins wa mọ riri itara awọn araalu ati adura wọn lori isẹlẹ naa.

Wọn ni awọn nigbagbọ pe ọkọ ọmọ awọn, ti wọn ti fẹ ara wọn fun dun mẹrindinlogun lo gba ẹmi rẹ, to si na papa bora.

Awọn mọlẹbi naa ni awọn n fẹ idajọ ododo lori isẹlẹ yii, ti wọn si n bẹ awọn araalu pe ki wọn sugba awọn lati beere fun idajọ ododo lori isẹlẹ yii.

aworan atẹsita awọn mọlẹbi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí aya gbajúmọ̀ ṣe dáná sun ara rẹ̀ l‘Eko?

IVD

Oríṣun àwòrán, kanyidaily

Ẹnu lọọlọ yii ni iroyin gbode pe iyawo gbajugbaja oniṣowo ọkọ ayọkẹlẹ niluu Eko, Ikechukwu Ogbonna, ti ọpọ mọ si IVD Autos, iyẹn Bimbo, ti jade laye, ti wọn si sọ pe ọkọ rẹ lọwọ ninu iku rẹ.

Iroyin ni igbeyawo tọkọ-taya naa to ti le ni ogun ọdun ko toro, to si jẹ pe igbaju igbamu ni lojojumọ.

Amọ ṣe lootọ ni IVD dana sun iyawo rẹ Bimbo to si n wo niran bo se n jona, tabi iyawo gan lo dana sun ara rẹ gẹgẹ bii iroyin mii to n lọ nigboro?

Alaye ree nipa awọn akojọpọ iroyin ti ẹbi tọkọtaya naa gbe sita.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii ni wahala tuntun bẹ silẹ nile tọkọtaya ọhun to wa ni Megamound Estate, lagbegbe Lekki, niluu Eko.

Ọkan lara awọn aladugbo tọkọ-taya naa ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ pe Bimbo koju ọkọ rẹ Ogbonna, lẹyin ti ọkunrin naa ti maa n lu ni ilu bara fun ọjọ pipẹ lori awọn ariyanjiyan to maa n waye laarin lọkọlaya.

Aladugbo naa ni “Mo ji laarọ oni, mo si bẹrẹ si n gbọ ariwo lati inu ile wọn, mo ri IVD to n lu iyawo rẹ, ti obinrin naa si n ke gbajare si ara adugbo lati gba oun.”

“Lẹyin naa ni obinrin ọhun bu epo bẹntiro, to si sọ ina sile wọn.”

“Bimbo tete fo sinu omi ‘swimming pool’ ninu ọgba ile wọn amọ ina naa ran ile ọhun atawọn ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye to wa nibẹ.”

“Lẹyin naa ni mo pe awọn eeyan, ti a si gbe Bimbo ati IVD lọ sile iwosan fun itọju amọ ina ọhun ti jo Bimbo kọja sisọ.”

“Iṣelẹ yii lo waye lẹyin to ti maa n kọ awọn atẹjade kan soju opo WhatsApp rẹ nipa awọn ohun to n la kọja ninu igbeyawo rẹ.”

Ẹwẹ, lẹyinorẹyin, Bimbo jade laye lẹyin to ti gba itọju fun ọjọ diẹ nile iwosan.

Ki ni ohun ti awọn mọlẹbi Bimbo sọ nipa iṣẹlẹ naa ati iku rẹ?

Lẹyin iku Bimbo ni ibatan rẹ obinrin ti ọpọ mọ si Mama Jazz fẹsun kan ọkọ rẹ pe oun gan lo ṣeku pa aburo oun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Ogbonna yii lo dana sun oloogbe naa, to si tun ya fidio rẹ bi ina ṣe n jo lara ti ko si bikita.

Ninu fidio to fi lede loju opo Instagram rẹ, o ni “Bimbo ti ku o, aburo mi ti ku, ina n jo mi.”

“IVD, iwọ lo ti aburo mi sinu ina, o si n wo bi ina naa ṣe n jo, bẹẹ lo tun n ya fidio rẹ.”

Nibo ni IVD wa?

Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ oloogbe naa, IVD, ti wọn fẹsun kan ti na papa bora bayii.

Amọ ninu awọn atẹjade kan ti ọkunrin naa fi lede loju opo Instagram rẹ, o ni oun ko lọwọ ninu iku iyawo oun rara.

Koda, o tun ko awọn ẹri maa jẹ mi ninṣo kan jade lati fi han pe oloogbe naa gan ni onijọgbọn ninu igbeyawo wọn.

IVD tun ṣafihan ile rẹ to sọ pe obinrin naa sọ ina si, to fi mọ awọn ọkọ olowo iyebiye to bajẹ, to si fẹsun kan oloogbe naa pe ko fi oun lọkan balẹ ninu igbeyawo wọn.

Wayi o, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n ke si ileesẹ ọlọpaa lati ke si ọkunrin naa lati lọ sọ ohun ti oju rẹ to nipa iku iyawo rẹ.

Amọ titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti iṣẹlẹ naa ti waye, ko tii sọ ohunkohun nipa rẹ.