Ghana dá ọmọ Nàìjíria 16 tó jápa padà wálé

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Ọmọ orilẹede Naijiria mẹrindinlogun ni wọn ti le pada wale lori ẹsun pe wọn n ṣe gbajuẹ ori ayelujara eyi ti ọpọ mọ si “yahoo-yahoo”.
Ọfiisi Ileeṣẹ aṣọbode Naijiria ni ẹnubode Sẹmẹ lo sọ eyi di mimọ.
Ọga agba ileeṣẹ aṣọbode lẹkun Sẹmẹ, Ọgbẹni Chukwu Emeka ṣalaye nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin pe awọn ti wọn le pada wale naa jẹ awọn ọdọ ti wọn fi orilẹede Naijiria silẹ roke okun lati lọ wa iṣẹ aje wọn.
“Awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Ghana n fi ẹsun kan wọn pe wọn lu jibiti, ṣugbọn iwadi ti a ṣi ṣe fihan pe wọn fi ẹtan mu awọn kan ninu wọn wọ inu awọn okoowo kan nitori iwọnwọra ati ojukokoro awọn ọdọ wa lati di olowo ni kiakia.”
Ọgbẹni Chukwu Emeka sọ pe ẹtan ni wọn fi mu awọn ọdọ naa kuro lorilẹede Naijiria pẹlu afojusun pe bi wọn ba de ilẹ okeere warawara ni wọn yoo di ọlọla, amọṣa ohun to buru ju nipa rẹ nipe wọn ko ri ohun ti wọn ṣe ileri rẹ fun wọn ni Ghana.
Adari ileeṣẹ aṣọbode lẹkun Sẹmẹ naa wa gba awọn ọmọ Naijiriia to n gbero ati roke okun nimọran pe ki wọn maa rii daju pe gbogbo iwe to yẹ fun irinajo wọn pe ki le lanfani ati ṣe okoowo ti ọkan wọn ba fẹ lorilẹede ti wọn ba lọ.








