Nyesom Wike yan olùbádámọ̀ràn, olùrànlọ́wọ́ 42,000 torí ètò ìdìbò ọdún 2023

Oríṣun àwòrán, Twitter
Gómínà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti yan àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ibùdó ìdìbò ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n (28,000).
Ìyànsípò ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kan tí gómìnà Wike yan olùbádámọ̀ràn pàtàkì ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá, (14,000) àwọn aṣojú wọ́ọ̀dú 319 àti àwọn aṣojú ìjọba ìbílẹ̀ ogójì (40).
Àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àtí olùbádámọ̀ràn yìí ni Wike yàn lórí ètò ìdìbò ọdún 2023 tó ń súnmọ́ etílé.
Agbẹnusọ Wike, Kelvin Ebiri tó fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan lọ́jọ́rú ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ fún àwọn tí gómìnà yàn sípò òṣèlú náà.
Gómìnà Wike fún àwọn tó lùgbàdì ẹ̀kúnwọ́ omi ní Bílíọ̀nù kan náírà
Ebiri nínú àtẹ̀jáde náà tún ṣàlàyé pé gómìnà Wike tún ti buwọ́lu bílíọ̀nù kan náírà láti fi tu àwọn tí wọ́n lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ní ìpínlẹ̀ Rivers lójú.
Ó ní owó náà ló wà láti fi pèsè ohun ìtùnú fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀kúnwọ́ omi ṣọṣẹ́ fún ní ìjọba ìbílẹ̀ Ahoada àti Ogba/Egbema/Ndoni.
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́fà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ ni yóò mójútó pínpín àwọn ohun ìdẹ̀kùn tí fún àwọn ènìyàn náà.
Akọ̀wé àgbà iléeṣẹ́ tó ń rí sí àkànṣe iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers, George Nwaeke ni alága ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́fà náà ti Inime Aguma sì jẹ́ akọ̀wé.
Lónìí ni ìrètí wà pé gbogbo àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà yóò ṣèpàdé pẹ̀lú Wike láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní kíákíá.















