Àarẹ Buhari búra fún CJN adájọ́ àgbà Nàìjíríà tuntun Olukayode Ariwoola

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli
Aarẹ Orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti bura wọle fun adajọ agba tuntun Olukayode Ariwoola.
Ayẹyẹ iburasipo naa waye ni ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ṣaaju ki ipade igbimọ alaṣẹ Naijiria waye lỌjọru yii.
Ariwoola ti ṣaaju di ipo adele adajọ agba mu fun igba diẹ lẹyin ti adajọ agba tẹlẹ Tanko Muhammada to fẹyin ti nidi ipo naa.
Ibiburawọle yi si n waye lẹyin ọjọ kan ti aarẹ Buhari fi ami ẹyẹ da awọn ọmọ Naijiria kan lọla.
Adajọ agba Ariwoola naa ba wọn gba ninu ami ẹyẹ yi nigba ti aarẹ Buhari fun ni ami ẹyẹ,The Grand Commander of the Order of Niger,GCON.
Awọn to peju sibi ayẹyẹ naa
Ọmọ bibi ipinlẹ Oyo ni Ariwoola jẹ ko si jẹ iyalẹnu pe Gomina Seyi Makinde yọju sibi ibura wọle yi.
Yatọ si Makinde, igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo, Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu ati awọn mọlẹbi adajọ agba yi naa peju sibẹ.

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli
Ta ni adajọ agba tuntun Ariwoola?

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli
- Ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 1958 ni wọn bi adele adajọ Ariwoola.
- Ọmọ bibi ilu Iseyin nipinlẹ Oyo nii ṣe.Ṣaaju asiko yi, oun ni adajọ ti ipo rẹ gajulọ ni ile ẹjọ to gajulọ ni Naijiria.
- Adajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun lo jẹ tẹlẹ ki wọn to ṣe agbega rẹ si ile ẹjọ to gajulọ
- Adajọ Ariwoola ti fi igba kan ṣiṣẹ ni ile ẹjọ giga to wa ni ipinlẹ Oyo.
- Ariwoola bẹrẹ eto ẹkọ rẹ ni Iseyin ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Local Authority Demonstration School, Oluwole, ni ijọba ibilẹ Iseyin, laarin ọdun 1959-1967.
- Yatọ si pe o ṣiṣẹ ni Oyo, o ti ṣiṣẹ nigba kan ri ni ile ẹjọ kotẹmilọrun apapọ ni Kaduna, Kaduna, Enugu, ati ẹka ile ẹjọ naa ni Eko.








