Àwọn nkán mẹ́fà rèé nípa adelé adájọ́ àgbà Nàìjíríà tuntun Olukayode Ariwoola

Aworan adele adajọ agba tuntun

Oríṣun àwòrán, NGRPresident

Aarẹ Muhammadu Buhari ti bura wọle sipo fun adele adajọ agba orileede Naijiria tuntun adajọ Olukayode Ariwoola.

Ni ile ijọba ni Abuja ni ayẹyẹ iburasipo naa ti waye.

Iroyin ikọwefiposilẹ adajọ agba Naijiria adajọ Tanko Muhammada lo sọ di dandan pe ki aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari yan adele adajọ tuntun si ipo rẹ.

Tori naa ko jẹ iyalẹnu wi pe aarẹ Muhammadu Buhari yan adajọ Olukayode Ariwoola, ẹni to jẹ adajọ to nipo julọ, gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ adele adajọ agba tuntun.

Lọjọ Aiku to kọja yi ni a gbọ pe adajọ Tanko Muhammad kọwe fipo silẹ ṣugbọn a ko gbọ nipa rẹ titi di owurọ ọjọ Aje.

Ako ribi fidi rẹ mulẹ ni pato idi ti adajọ yi fi kọwe fiposilẹ ṣugbọn awọn iroyin kan n sọ pe o ṣebẹ nitori ailera rẹ.

Awọn miran ni eleyi ni ṣe pẹlu ẹsun ajẹbanu tawọn adajọ agba kan nile ẹjọ to gaju lọ ni Naijiria fi kan laipẹ yi nipa ẹtọ awọn ton ṣiṣẹ labẹ rẹ.

Adajọ Muhammad ti sọ pe oun ko mọ si awọn ẹsun wọnyi.

Ni bayi ti o ti wa fihan gbangba pe aaye adajọ ṣi silẹ ati pe ẹlomiran ni yoo di ipo yi mu, ki lohun tawọn ọmọ Naijiria mọ nipa adele adajọ tuntun yi.

Koko diẹ nipa adele adajọ agba tuntun

Aworan adele adajọ agba tuntun

Oríṣun àwòrán, NGRPresident

  • Ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 1958 ni wọn bi adele adajọ Ariwoola.Ọmọ bibi ilu Iseyin nipinlẹ Oyo nii ṣe.
  • Ṣaaju asiko yi, oun ni adajọ ti ipo rẹ gajulọ ni ile ẹjọ to gajulọ ni Naijiria.
  • Adajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun lo jẹ tẹlẹ ki wọn to ṣe agbega rẹ si ile ẹjọ to gajulọ
  • Adajọ Ariwoola ti fi igba kan ṣiṣẹ ni ile ẹjọ giga to wa ni ipinlẹ Oyo.
  • Ariwoola bẹrẹ eto ẹkọ rẹ ni Iseyin ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Local Authority Demonstration School, Oluwole, ni ijọba ibilẹ Iseyin, laarin ọdun 1959-1967.
  • Yatọ si pe o ṣiṣẹ ni Oyo, o ti ṣiṣẹ nigba kan ri ni ile ẹjọ kotẹmilọrun apapọ ni Kaduna, Kaduna, Enugu, ati ẹka ile ẹjọ naa ni Eko.
Aworan adele adajọ agba tuntun

Oríṣun àwòrán, NGRPresident

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ibura wọle sipo rẹ,adajọ Ariwoola jẹjẹ lati daabo bo iwe ofin Naijiria ati pe oun yoo tẹle aṣẹ rẹ.

Ireti ni pe yoo di ipo yi mu titi di igba ti aarẹ yoo fi yan adajọ tuntun miran eleyi to gba ki ile aṣofin agba Naijiria buwọle.

Adajọ agba Naijiria oṣiṣẹ ẹka aṣofin to gajulọ lorileede Naijiria.