CJN: Ilé aṣòfin ti buwọ́lu Tanko Muhammad gẹ́gẹ́ bi adájọ́ àgbà Nàìjíríà

Aare Buhari

Oríṣun àwòrán, AsoRockVilla

Àkọlé àwòrán, Aare Buhari yan Tanko Ibrahim lati dele de adajọ Onnoghen

Ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ti buwọlu iyansipo Tanko Muhammad gẹgẹ bi Adajọ Agba Naijiria.

Wọn buwọlu u lọjọru lẹyin eto ayẹwo ti awọn aṣofin kan ṣe fun un.

Ṣaaju ni Ajọ to n mojuto eto idajọ ni Naijiria, NJC, rọ Aarẹ Buhari lati sọ Onidajọ Muhammad di Adajọ Agba Naijiria.

Ọjọbọ to kọja ni Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ rẹ ranṣẹ si awọn aṣofin fun ontẹ lati le mu u ko kuro ni ipo Adele Adajọ Agba.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2019 ni Muhammad bọ si ipo Adele lẹyin ti wọn da Adajọ Agba nigba kan, Walter Onnoghen duro, nitori ẹsun ṣiṣe magomago lasiko to kede dukia rẹ.

Lẹyin naa ni Aarẹ Buhari fi oṣu mẹta mi i kun ọjọ rẹ ni ipo naa.

Àkọlé fídíò, Fulani Heardsmen: Afenifere ní àṣẹ tó bá wu àwọn àgbàgbà agbègbè àríwá Nàìjíríà ni