COZA: A ti wọ́gilé ìwọ́de lórí COZA tí a fẹ́ ṣe tẹ́lẹ́ nítorí...

Oni ni àwọn ikọ #Church Too ti wọn n ṣe iwọde ṣe lodi si ifipabanilopọ nile ijọsin kede lati ṣe iwọde ni Abuja ati Eko tẹlẹ.
Ọpọlọpọ iwọde ni wọn ti ṣe sẹyin lati igba ti ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti ṣẹlẹ pe pasitọ Biodun Fatoyinbo fipa ba arabinrin Busola Dakolo lo pọ
Bukky Shonibare to jẹ ọkan pataki lara awọn to fẹ ṣe iwọde naa ni idi tawọn ṣe fẹ sẹ iwọde toni ni pe ko yẹ ki ẹgbẹ CAN dọwọ bo iṣẹlẹ naa.
Bukky Shonibare ni awọn agbofinro ti kọkọ ranṣe si oun lati wa ṣalaye nipa iwọde ti wọn fẹ ṣe naa tẹlẹ.
O ni pataki idi ti wọn ṣe kọkọ fẹ ṣe iwọde naa ni tori pe awọn gbọ pe awọn olori ajọ CAN ni wọn n ṣatileyin fun pasitọ Biodun Fatoyinbo ni eyi ti wọn gba pe ko yẹ ko ri bẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni inu wọn dun pe ajọ CAN ti ni iṣẹ ẹgbẹ kọ́ ni awọn to lọ ijọ COZA lọ jẹ bikoṣe iṣẹ ara wọn.

Ninu fọnran fidio kan to n tàn kalẹ ni wọn ti ri alaga CAN fun FCT ati alaga CAN fun aarin gbungbun Naijiria, ti wọn n kede atilẹyin wọn fun pasitọ COZA.
Alufaa Isreal Akanji ati Alufaa Jonah Samson ni wọn n kede atilẹyin wọn ninu fọnran naa.
Ṣaaju asiko yii ni ajọ PFN ti kede pe awọn ko ni fọwọ bo iwa ibajẹ kankan lainii fi ṣe ẹni ti ade naa ba ṣi mọ lori.
Alaga PFN, Alufaa Felix Omobude ni ọrọ ẹsun ifipabanilopọ naa ba ni ninujẹ pupọ.
Ajọ CAN ti kede pe awọn n reti abọ iwadii ajọ PFN ki awọn to mọ igbesẹ to kan lati gbe lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ naa.













