AFCON 2019: Cameroun yọ Seedorf nípò gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ni Indomitable Lions

Seedorf ati Kluivert

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ ere bọọlu ni Cameroun ṣalaye pe Seedorf ko lee mu ẹjẹ to wa ninu iwe adehun igbanisiṣẹ rẹ ṣẹ ni wọn fi yọọ nipo

Ajọ ere bọọlu lorilẹede Cameroun ti rọ olukọni ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede naa, Clarence Seedorf loye lẹyin to kuna lati gba ife ẹyẹ AFCON lọdun yii.

Ọdun kan pere ni Seedorf ṣi lo nipo gẹgẹ bii oluksni ẹgbẹ agbabọọlu Indomitable lions.

Oun pẹlu igbakeji rẹ, Patrick Kluivert ni wọn jijọ n fi ipo silẹ bayii.

Ikọ Super Eagles ti Naijiria lo yọ ọwọ kilanko Cameroun kuro lawo idije AFCON 2019 to n lọ lọwọ ni orilẹede Egypt eleyi lo si mu ki minisita fere idaraya ni orilẹede Cameroun o ni ko wa maa lọ.

Seedorf ati agbabọọlu Cameroun kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oun pẹlu igbakeji rẹ, Patrick Kluivert ni wọn jijọ n fi ipo silẹ bayii.

Bi o tilẹ jẹ pe Seedorf ni inu oun yoo dun lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ naa lẹyin ti wọn ja bọ kuro ninu idije naa, ajọ ere bọọlu ilẹ Cameroun ni ko si ọna mọ fun wọn.

Won ni afi ki wọn fi ipo silẹ nitori awọn eto ti wọn fi kalẹ sinu iwe adehun ti wọn fi gba iṣẹ.

Ninu iwe adehun igbanisiṣẹ ti Seedorf ati Kluivert tọwọ bọ, ara ohun ti yoo mu iṣẹ wọn duro ni ki wọn gba ife ẹyẹ naa eleyii ti wọn gba ni ọdun 2017.

Àkọlé fídíò, Awọn ọdọ Ondo fẹ̀họ́nù hàn lórí ìṣekúpani Funke Olakunrin