Bí Sanwo-Olu bá fún Super Eagles lówó ń kọ̀; Ṣebí kìí ṣ'owó ìjọba

Oríṣun àwòrán, @:Sanwo-olu
Iye tó ba wu Sanwo Olu ló lè fún ẹnikẹni - Akoṣile
Laipẹ yii ni awọn iwe iroyin kan gbe e pe Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ni miliọnu mọkanlelogoji o le diẹ lasiko to lọ fun idije AFCON 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt.
Ọpọ lo ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi eyi ti ko ba oju mu, eyi to da bi iwa àpà.
Awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu PDP tilẹ̀ ni Sanwo-Olu n fi owo awọn araalu ṣofo ni pẹlu igbesẹ naa.
Eyi mu ki BBC Yoruba o kàn si igbakeji akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Gboyega Akosile.
Akoṣile sọ fun akọroyin BBC to ba a sọrọ lọjọ kẹjọ, oṣu Keje, pe irọ patapata ni iroyin naa.
Amọ ṣa, lọjọ kẹsan an, to jẹ ọjọ̀ keji, ni akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, to jẹ ẹgbẹ gomina, Joe Igbokwe fi ikede kan sita pe ko si n to buru ti gomina ba ṣe bẹẹ.
O ni ti gomina ba ṣe e, o ṣe e lati mu ori awọn agbabọọlu naa wu ni fun bi wọn ṣe na ẹgbẹ agbabọọlu Camreoon.
Ọrọ̀ ti Igbokwe sọ yii mu ki BBC Yoruba o tun pada kàn sí Gboyega Akosile to ti kọkọ sọ̀ pe Gomina Sanwo-Olu ko fun Super Eagles ni owo kankan.
Ninu ọrọ to sọ lasiko yii, Akosile sọ pe bi igba ti awọn to n bu gomina lori igbesẹ naa kan n fi oju keere gomina ni.
O ni ''eelo ni gbogbo owo naa (41.4m) ti gomina ko le fun Super Eagles lati apo ara a rẹ, lai mu owo ijọba?''
Akosile sọ pe bi gomina ba ti ẹ ṣe bẹẹ, o ṣe e gẹgẹ bi baba to fẹ ki ọmọ rẹ o ṣe daadaa ni.
Ṣugbọn Akọṣile yi tẹnumọọ fun BBC pé oun duro lori ọrọ àkọ́sọ oun pé Sanwo Olu kò fún ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lowo.















