Ìdẹ̀rùn dé báwọn òṣìṣẹ́ l‘Ogun, wọn yóò gba ìsinmi ọjọ́ kan láàrín ọ̀sẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó ọkọ̀ lóṣù

Ọpọ awọn osisẹ nipinlẹ Ogun n na ọwọ soke, fo fayọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu ọjọ marun-un ti awọn oṣiṣẹ ijọba fi n ṣiṣẹ, wọn yoo maa isinmi ọjọ kan ninu rẹ bayii nipinlẹ Ogun, gẹgẹ bi Ọmọọba Dapo Abiodun, gomina Ogun, ṣe kede.

Yatọ si isinmi ọjọ kan yii, Abiodun tun ṣeleri pe oun yoo maa fun awọn oṣiṣẹ ijọba naa ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu, gẹgẹ bii owo ọkọ̀.

Olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun, Kehinde Onasanya, lo kede eyi l'Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlogun,oṣu Kẹrin ọdun 2026.

Onasanya ṣalaye pe igbesẹ naa n waye lati bu ororo itura si bawọn oṣiṣẹ ṣe n fi owo nla wọ ọkọ wa sibi iṣẹ, pẹlu bi owo epo ṣe ti gbowo lori kaakiri.

O fi kun un pe anfaani owo ati isinmi yii yoo wa fun oṣu mẹta, yoo si bẹrẹ loṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.

Gomina Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/Facebook

''Awọn oṣiṣẹ ijọba kan ko ni gba isinmi laarin ọsẹ ninu eto yii''

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Olori oṣiṣẹ ijọba Ogun sọ pe ki I ṣe gbogbo oṣiṣẹ ni yoo ni anfaani isinmi ọjọ kan laarin ọsẹ naa.

O ni awon ti iṣẹ wọn ko ṣe e ma ṣe ko ni anfaani isinmi ọjọ kan yii, sugbọn wọn lẹtọọ si ẹgbẹrun mẹwaa owo ọkọ.

Awọn oṣiṣẹ ti ko ni i kopa ninu isinmi ọjọ kan naa bi ijọba Ogun ṣe kede ni:

Awọn oṣiṣẹ ẹka ilera

Oṣiṣẹ eto idajọ.

Awọn olukọ.

Awọn oṣiṣẹ eto aabo

Awọn olori ẹka ileeṣẹ.

Onasanya gboriyin fun Gomina Dapo Abiodun fun eto to gbe kalẹ yii, o ni o bọ si asiko to yẹ fun awọn oṣiṣẹ, yoo si ran ijafafa wọn lọwọ .

O wa rọ awọn oṣiṣẹ ijọba naa lati mura siṣẹ, nitori bi awo ba kì fun ni, a n kì fawo pada ni, o ni ki wọn jẹ ki iṣẹ lọ bo ṣe yẹ.