Goodluck: Ṣèbí ajagunfẹ̀yìntì ni Buhari, o yẹ kó mọ ohun tó yẹ láti kápá ìpèníjà ààbò

Aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan ti gba aarẹ Buhari ni imọran pe ko yi eto ati ilana ti o n lo lati gbogun ti ipenija aabo to mẹhẹ ni Naijiria.
Ọmọwe Jonathan fun aarẹ Buhari ni imọran yii lasiko to fi ṣe abẹwo si ile alagba Rueben Faṣọranti lori iku ọmọ rẹ ti wọn ni awọn agbebọn pa ni ọjọ Ẹti to kọja.
- Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo sọ nílé bàbá Fasoranti
- EFCC ń wádìí iléeṣẹ́ 'Bola Tinubu,' Alpha Beta Consulting Ltd'
- Aago Nàìjíríà ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ - Tunde Bakare
- Àṣìta ìbọn pa èèyàn kan lásìkò tí SARS ń kojú adigunjalè l'Eko
- A ó gbé'gbésẹ̀ lẹ́yìn ìwádìí fídíò tí Dino ti ń náwó lójú agbo- Ọlọ́pàá
Aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria naa ni ọjọ ti pẹ to ti yẹ ki aarẹ yi ọwọ pada lori eto igbogun ti iwa ọdaran niwọn igba ti o jẹ wi pe ajagun fẹyinti ni ko to darapọ mo oṣelu.

"Ibanijẹ lo jẹ fun wa nigba ti a gbọ iṣẹlẹ buruku yii, o si yẹ ki ijsba apapọ tete wa wọrọkọ fi ṣada ki irufẹ eyi ma baa tun waye mọ."
"Asiko to lati lo imọ ẹrọ tuntun ki alaafia lee jọba ki iwa ọdaran si lee wọlẹ."
Akọwe ijọba ipinlẹ Ondo, atawọn kọmiṣọna ni ipinlẹ Ondo ni wọn ba Aarẹ ana, Goodluck Jonathan kọwọrin.
Alagba Faṣọranti dupẹ lọwọ rẹ fun abẹwo ati ibanikẹdun rẹ.









