PasitoTunde Bakare: Aago Nàìjíríà ti kún àkúnwọ́sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @T_Bakare
Gbajugbaja Agbẹjọro ati Pasito Ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ni awọn adari orilẹ-ede Naijiria n se oselu pẹlu ẹmi awọn araalu ni Naijiria.
Bakare sọ eyi lasiko to n ba ebi ati ara Abileko Funke Olakunrin to jẹ ọmọ baba pa Reuben Fasọnranti, ti wọn ni awọn agbebọn pa ni ọna Ọrẹ si Benin ni opin ọsẹ.
Pẹlu omije loju ni Bakare fi sọ wi pe aago Naijiria ti kun akunwọsilẹ pẹlu bi ẹmi awọn eniyan ko ṣe jọ ijọba loju mọ, ti ipaniyan n waye lọtun losi.
Ninu ọrọ rẹ, o ni ijọba n se aito lori bi wọn se n koju ipaniyan ati ijinigbe nitori awọn eleto aabo maa n sa gbogbo agbara wọn lati ri wi pe ki wọn má gba ẹmi awọn olowo lawujọ, sugbọn ẹmi awọn araalu ko jọ wọn loju.
Amọ, adari ẹgbẹ oselu APC lorilẹ-ede Naijiria, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ni awọn Fulani darandaran nikan kọ lo n jinigbe tabi paniyan, amọ awọn ẹya miran naa n se ibi pẹlu.










